Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀

Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀

Ìwé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́ máa jẹ́ kó o tètè rí àwọn ẹsẹ Bíbélì àtàwọn ìtàn inú Bíbélì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá níṣòro. Ó tún máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè rí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o lè fi fúnni níṣìírí àtèyí tó o lè fi fúnni nímọ̀ràn kẹ́ni náà lè ṣe àwọn ìpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn. Lọ sí àkòrí tó o fẹ́, wàá rí àwọn ìbéèrè tó ṣe tààràtà àti àlàyé ṣókí nípa àwọn ìtàn Bíbélì tá a tọ́ka sí níbẹ̀. (Wo àpótí tá a pè ní “ Bó O Ṣe Lè Lo Ìwé Yìí.”) Ìwé yìí máa jẹ́ kó o rí ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn àti ìsọfúnni tó wúlò, tó sì ń tuni nínú látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wàá tún rí àwọn ìlànà Bíbélì tó o lè fi fúnni níṣìírí àtèyí tó o lè fi gbani nímọ̀ràn.

Kì í ṣe gbogbo ẹsẹ Bíbélì tó bá àkòrí kọ̀ọ̀kan mu lo máa rí nínú ìwé yìí. Àmọ́, wàá rí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣe pàtàkì, èyí á sì mú kó rọrùn fún ẹ láti ṣèwádìí sí i. (Owe 2:1-6) Kó o lè ṣèwádìí sí i, lo àwọn atọ́ka ẹsẹ Bíbélì tó wà láàárín ojú ìwé Bíbélì àtàwọn àlàyé ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì. Bákan náà, o lè lo Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí Watch Tower Publications Index láti ṣèwádìí síwájú sí i nípa ohun tí ẹsẹ Bíbélì kan túmọ̀ sí àti bá a ṣe lè lò ó. Àwọn ìtẹ̀jáde tó dé kẹ́yìn ni kó o máa lò, kó o lè rí òye tá a ní báyìí nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì.

Àdúrà wa ni pé bó o ṣe ń lo ìwé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́, kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè rí ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Tó o bá ń lo ìwé yìí, ìwọ náà á jẹ́rìí sí i pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà láàyè, ó sì ní agbára.”—Heb 4:12.