Máa Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́
Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ṣe tó fi hàn pé òun lẹni tó lawọ́ jù lọ?
Tá a bá tiẹ̀ ń fún àwọn èèyàn ní nǹkan, àwọn ìwà wo ló yẹ ká yẹra fún kínú Ọlọ́run lè máa dùn sí wa?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Jẹ 4:3-7; 1Jo 3:11, 12—Kí nìdí tí Ọlọ́run ò fi tẹ́wọ́ gba ẹbọ tí Kéènì rú?
-
Iṣe 5:1-11—Torí pé Ananáyà àti Sàfírà ò ní èrò tó tọ́ nípa ẹ̀bùn tí wọ́n mú wá, tí wọ́n sì parọ́, Jèhófà jẹ́ kí wọ́n jìyà ohun tí wọ́n ṣe
-
Kí ló máa jẹ́ kínú Ọlọ́run dùn sí wa tá a bá ń fún àwọn èèyàn ní nǹkan?
Mt 6:3, 4; Ro 12:8; 2Kọ 9:7; Heb 13:16
Tún wo Iṣe 20:35
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Lk 21:1-4—Ohun tí opó aláìní kan fi sílẹ̀ kéré gan-an, síbẹ̀ Jésù gbóríyìn fún un torí pé tọkàntọkàn ló fi mú un wá
-
Báwo làwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe ń ran ara wọn lọ́wọ́?
Iṣe 11:29, 30; Ro 15:25-27; 1Kọ 16:1-3; 2Kọ 9:5, 7
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Iṣe 4:34, 35—Àwọn ará nínú ìjọ Kristẹni fi tinútinú yọ̀ǹda àwọn nǹkan tí wọ́n ní, àwọn àpọ́sítélì sì pín in fáwọn aláìní
-
2Kọ 8:1, 4, 6, 14—Ìjọ Kristẹni ṣètò bí wọ́n ṣe máa ran àwọn ará tó jẹ́ aláìní lọ́wọ́
-
Àwọn nǹkan pàtàkì wo ló yẹ káwa Kristẹni máa ṣe fáwọn tó wà nínú ìdílé wa àtàwọn tá a jọ ń sin Jèhófà?
Kí ni Bíbélì sọ pé ó yẹ ká máa ṣe fáwọn aláìní?
Báwo la ṣe mọ̀ pé ohun tó dáa jù lọ tá a lè ṣe fáwọn èèyàn ni pé ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà?
Mt 5:3, 6; Jo 6:26, 27; 1Kọ 9:23
Tún wo Owe 2:1-5; 3:13; Onw 7:12; Mt 11:4, 5; 24:14
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Lk 10:39-42—Jésù jẹ́ kí Màtá mọ̀ pé ohun tó máa mú ká lájọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà ló yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí wa
-