Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìpinnu

Ìpinnu

Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ìpinnu tó dáa?

Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa kánjú tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì?

Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣe nǹkan tí ọkàn wa bá ṣáà ti sọ nígbà tá a bá fẹ́ ṣèpinnu?

Owe 28:26; Jer 17:9

Tún wo Nọ 15:39; Owe 14:12; Onw 11:9, 10

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Kr 35:20-24—Ọba rere ni Jòsáyà, àmọ́ kò gba ìmọ̀ràn tí Jèhófà fún un, ó sì lọ bá Fáráò Nékò jà

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà ká tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì?

Flp 4:6, 7; Jem 1:5, 6

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Lk 6:12-16—Gbogbo òru ni Jésù fi gbàdúrà kó tó yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá

    • 2Ọb 19:10-20, 35—Nígbà táwọn ọ̀tá tó lágbára dojú kọ Ọba Hẹsikáyà, ó gbàdúrà sí Jèhófà, Jèhófà sì ràn án lọ́wọ́

Ọ̀dọ̀ ta la ti lè rí ìmọ̀ràn tó dáa jù lọ tá a bá fẹ́ ṣèpinnu, báwo ló sì ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣèpinnu tó dáa?

Sm 119:105; Owe 3:5, 6; 2Ti 3:16, 17

Tún wo Sm 19:7; Owe 6:23; Ais 51:4

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Iṣe 15:13-18—Nígbà tí ìgbìmọ̀ olùdarí tó wà ní Jerúsálẹ́mù fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì kan, wọ́n gbára lé Bíbélì, ìyẹn sì mú kí wọ́n ṣèpinnu tó tọ́

Àwọn ìpinnu nípa:

Gbogbo apá ìgbésí ayé

Iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́

Wo “Iṣẹ́

Eré ìdárayá

Wo “Eré Ìnàjú

Ìgbéyàwó

Wo “Ìgbéyàwó

Ìtọ́jú ìṣègùn

Le 19:26; Di 12:16, 23; Lk 5:31; Iṣe 15:28, 29

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Iṣe 19:18-20—Àwọn ará tó wà ní Éfésù pinnu pé àwọn ò ní lọ́wọ́ sí idán pípa àti ìbẹ́mìílò mọ́

Àwọn nǹkan tá a lè ṣe ká lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà

Bá a ṣe ń lo àkókò wa

Báwo làwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa?

Job 12:12; Owe 11:14; Heb 5:14

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Ọb 1:11-31, 51-53—Bátí-ṣébà tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí wòlíì Nátánì fún un, ìyẹn sì yọ òun àti Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ nínú ewu

Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa retí pé káwọn èèyàn ṣèpinnu fún wa?

Kí nìdí tó fi yẹ ká pinnu pé àá máa tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn Jèhófà dípò tí àá fi máa fojú kéré wọn?

Sm 18:20-25; 141:5; Owe 8:33

Tún wo Lk 7:30

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 19:12-14, 24, 25—Lọ́ọ̀tì kìlọ̀ fáwọn ọkùnrin tó fẹ́ fi àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ṣe aya pé Ọlọ́run fẹ́ pa ìlú wọn run, àmọ́ wọn ò fetí sí i

    • 2Ọb 17:5-17—Àwọn ọ̀tá kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sígbèkùn torí bí wọ́n ṣe ń kọ ìmọ̀ràn Jèhófà léraléra

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa kíyè sí ohun tí ẹ̀rí ọkàn wa bá sọ nígbà tá a bá fẹ́ ṣèpinnu?

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú nípa ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tá a bá ṣe ìpinnu kan?

Bí ìpinnu wa ṣe kan àwọn míì

Bí ìpinnu wa ṣe kan ọjọ́ ọ̀la wa

Bí ìpinnu wa ṣe kan àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà

Kí nìdí tí kò fi yẹ ká dá ẹlòmíì lẹ́bi torí ìpinnu tá a ṣe?