Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọtí Mímu

Ọtí Mímu

Ṣé Bíbélì sọ pé a ò gbọ́dọ̀ mutí rárá?

Sm 104:14, 15; Onw 9:7; 10:19; 1Ti 5:23

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Joh 2:1-11—Iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ tí Jésù ṣe ni pé ó sọ omi di wáìnì níbi ìgbéyàwó kan, kójú má bàa ti ọkọ àti ìyàwó náà

Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá mutí lámujù tàbí tá a mutí yó?

Èrò wo làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní nípa mímu ọtí ní àmupara?

1Kọ 5:11; 6:9, 10; Ef 5:18; 1Ti 3:2, 3

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 9:20-25—Nígbà tí Nóà mutí yó tó sì sùn lọ, ọmọ ọmọ rẹ̀ ṣe ohun tó burú gan-an

    • 1Sa 25:2, 3, 36—Nábálì jẹ́ òpònú àti ìkà, ó sì máa ń ṣe àwọn nǹkan tó burú gan-an irú bíi kó mutí yó bìnàkò

    • Da 5:1-6, 22, 23, 30, 31—Ọba Bẹliṣásárì mutí lámujù, ó sì tàbùkù sí Ọlọ́run; òru ọjọ́ yẹn ni wọ́n pa á

Tá ò bá tiẹ̀ mutí yó, kí nìdí tó fi yẹ ká kíyè sí bí ọtí tá a fẹ́ mu ṣe máa pọ̀ tó?

Tó o bá mọ arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó sábà máa ń mutí lámujù, báwo lo ṣe lè ràn án lọ́wọ́?