Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìṣírí

Ìṣírí

Kí nìdí tó fi yẹ káwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa fún ara wa níṣìírí?

Ais 35:3, 4; Kol 3:16; 1Tẹ 5:11; Heb 3:13

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Kr 32:2-8—Ọba Hẹsikáyà fún àwọn èèyàn ẹ̀ níṣìírí nígbà táwọn ọmọ ogun Ásíríà ń halẹ̀ mọ́ wọn

    • Da 10:2, 8-11, 18, 19—Nígbà tí Dáníẹ́lì darúgbó, tó sì rẹ̀ ẹ́ nígbà kan, áńgẹ́lì kan bá a sọ̀rọ̀ tó fún un níṣìírí, tó sì tún fún un lókun

Kí nìdí tí Jèhófà fi fẹ́ káwọn alàgbà máa fún àwọn ará níṣìírí?

Ais 32:1, 2; 1Pe 5:1-3

Tún wo Mt 11:28-30

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Di 3:28; 31:7, 8—Nígbà tí Jèhófà yan Jóṣúà láti di aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ fún wòlíì Mósè pé kó fún un níṣìírí, Mósè sì ṣe bẹ́ẹ̀

    • Iṣe 11:22-26; 14:22—Nígbà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sáwọn Kristẹni tó wà ní Áńtíókù, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Bánábà fún wọn níṣìírí

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn ará látọkàn wá tá a bá fẹ́ fún wọn níṣìírí?

Owe 31:28, 29; 1Kọ 11:2

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Ond 11:37-40—Torí pé ọmọbìnrin Jẹ́fútà yọ̀ǹda ara ẹ̀ kó lè máa sìn ní àgọ́ ìjọsìn, ọdọọdún làwọn obìnrin Ísírẹ́lì máa ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹ̀ kí wọ́n lè fún un níṣìírí

    • Ifi 2:1-4—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù bá àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù wí, ó kọ́kọ́ gbóríyìn fún wọn torí àwọn nǹkan dáadáa tí wọ́n ṣe

Báwo làwa ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe lè máa fún ara wa níṣìírí?

Owe 15:23; Ef 4:29; Flp 1:13, 14; Kol 4:6; 1Tẹ 5:14

Tún wo 2Kọ 7:13, 15, 16

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Sa 23:16-18—Jónátánì mọ̀ pé Dáfídì nílò ìṣírí, torí náà ó lọ sọ́dọ̀ Dáfídì, ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó fún un lókun

    • Jo 16:33—Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé òun ti ṣẹ́gun ayé, àwọn náà sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ òun, ọ̀rọ̀ yẹn sì fún wọn lókun

    • Iṣe 28:14-16—Nígbà tí wọ́n ń mú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọ sí Róòmù kí wọ́n lè gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀, àwọn arákùnrin kan rìnrìn àjò láti pàdé ẹ̀ lọ́nà kí wọ́n lè fún un níṣìírí, ohun tí wọ́n ṣe yẹn sì fún un lókun

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn, ká má sì máa ṣàríwísí wọn?

Flp 2:14-16; Jud 16-19

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Nọ 11:10-15—Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ aláìgbọràn wọ́n sì tún máa ń ṣàríwísí, ìyẹn sì mú kí nǹkan tojú sú wòlíì Mósè

    • Nọ 13:31, 32; 14:2-6—Àwọn amí mẹ́wàá tí kò nígbàgbọ́ nínú Jèhófà ṣàríwísí, wọ́n sì sọ̀rọ̀ tó kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èyí sì mú káwọn èèyàn náà ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà

Tá a bá ń lo àkókò pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, báwo nìyẹn ṣe máa fún wa níṣìírí?

Owe 27:17; Ro 1:11, 12; Heb 10:24, 25; 12:12

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Kr 20:1-19—Nígbà táwọn ọmọ ogun tó pọ̀ ń halẹ̀ mọ́ Ọba Jèhóṣáfátì, ó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ, wọ́n sì gbàdúrà

    • Iṣe 12:1-5, 12-17—Àwọn ará tó wà ní Jerúsálẹ́mù pàdé pọ̀ láti gbàdúrà nígbà tí Ọba Hẹ́rọ́dù pa àpọ́sítélì Jémíìsì, tó sì tún fi àpọ́sítélì Pétérù sẹ́wọ̀n

Tá a bá ń ronú nípa àwọn ohun rere tí Jèhófà ṣèlérí, báwo nìyẹn ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro?

Iṣe 5:40, 41; Ro 8:35-39; 1Kọ 4:11-13; 2Kọ 4:16-18; 1Pe 1:6, 7

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 39:19-23; 40:1-8—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n parọ́ mọ́ Jósẹ́fù tí wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n, ó ń bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ó sì máa ń wù ú láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́

    • 2Ọb 6:15-17—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun fẹ́ bá wòlíì Èlíṣà jà, ẹ̀rù ò bà á rárá, ó sì gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran ìránṣẹ́ òun lọ́wọ́ kóun náà lè nígboyà

Bíbélì lè fún wa níṣìírí

Kí ni Bíbélì sọ tó jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́?

Tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ aláàánú, tó sì tún máa ń ní sùúrù, báwo nìyẹn ṣe lè mú kára tù wá?

Kí ni Jèhófà máa ń ṣe fáwọn tó ti rẹ̀?

Sm 46:1; Ais 12:2; 40:29-31; Flp 4:13

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Sa 1:10, 11, 17, 18—Nígbà tí inú Hánà bà jẹ́ tí nǹkan sì tojú sú u, ó gbàdúrà sí Jèhófà, Jèhófà sì mú kára tù ú

    • 1Ọb 19:1-19—Nígbà tí nǹkan tojú sú wòlíì Èlíjà, Jèhófà fún un ní nǹkan tó nílò. Jèhófà sọ̀rọ̀ tó mú kó nírètí, ara sì tù ú

Tá a bá ń ronú nípa àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe fún wa, báwo nìyẹn ṣe lè mú ká nígboyà?

2Kr 15:7; Sm 27:13, 14; Heb 6:17-19; 12:2

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Job 14:1, 2, 7-9, 13-15—Nígbà tí gbogbo nǹkan tojú sú Jóòbù, ìrètí tó ní pé Jèhófà máa jí òun dìde mú kára tù ú

    • Da 12:13—Nígbà tí wòlíì Dáníẹ́lì tó ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún, áńgẹ́lì kan sọ fún un pé Jèhófà máa bù kún un lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn sì mú kára tù ú

Tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, tá a sì ń ronú nípa irú ẹni tó jẹ́, báwo nìyẹn ṣe máa fún wa níṣìírí?

Sm 18:6; 56:4, 11; Heb 13:6

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Sa 30:1-9—Nígbà tí nǹkan nira fún Ọba Dáfídì, ó gbàdúrà sí Jèhófà, Jèhófà sì fún un lókun

    • Lk 22:39-43—Nígbà tí Jésù ronú nípa ohun tó máa tó ṣẹlẹ̀ sóun, ó bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, Jèhófà sì rán áńgẹ́lì kan sí i kó lè fún un lókun

Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tá a bá gbọ́ ìròyìn rere, kí sì nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ káwọn míì mọ̀ nípa ẹ̀?

Owe 15:30; 25:25; Ais 52:7

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Iṣe 15:2-4—Àwọn ìjọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Bánábà bẹ̀ wò rí ìṣírí gbà, inú àwọn ará sì dùn gidigidi

    • 3Jo 1-4—Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù ti darúgbó, ó gbọ́ pé àwọn tóun wàásù fún rọ̀ mọ́ òtítọ́, ìyẹn sì mú kínú ẹ̀ dùn gan-an