Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbàgbọ́

Ìgbàgbọ́

Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà ka ìgbàgbọ́ sí ohun tó ṣe pàtàkì?

Jo 3:16, 18; Ga 3:8, 9, 11; Ef 6:16; Heb 11:6

Tún wo 2Kọ 5:7

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Heb 11:1–12:3—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ ohun tí ìgbàgbọ́ túmọ̀ sí, ó sì tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n nígbàgbọ́ bí Ébẹ́lì àti Jésù Kristi

    • Jem 2:18-24—Bíi ti Ábúráhámù, Jémíìsì sọ pé ó yẹ ká ṣe ohun tó fi hàn pé a nígbàgbọ́

Kí ló máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára?

Ro 10:9, 10, 17; 1Kọ 16:13; Jem 2:17

Tún wo Heb 3:12-14

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Kr 20:1-6, 12, 13, 20-23—Nígbà táwọn ọ̀tá wá gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run, Ọba Jèhóṣáfátì jẹ́ káwọn èèyàn Ọlọ́run mọ̀ pé, tí wọ́n bá fẹ́ ṣàṣeyọrí wọ́n gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jèhófà àtàwọn wòlíì rẹ̀

    • 1Ọb 18:41-46—Nígbà tí òjò ò rọ̀ fún àkókò gígùn, wòlíì Èlíjà ṣe ohun tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́, ní ti pé ó fi sùúrù dúró dìgbà tí Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ