Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdáríjì

Ìdáríjì

Ṣé Jèhófà ṣe tán láti dárí jì wá lóòótọ́?

Sm 86:5; Da 9:9; Mik 7:18

Tún wo 2Pe 3:9

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Sm 78:40, 41; 106:36-46—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n sì ba Jèhófà nínú jẹ́, léraléra ló dárí jì wọ́n

    • Lk 15:11-32—Jésù fi Jèhófà wé Bàbá aláàánú kan tí ọmọ ẹ̀ hùwà burúkú, àmọ́ tó dárí ji ọmọ náà nígbà tó ronú pìwà dà

Kí ni Jèhófà ṣe ká lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà?

Jo 1:29; Ef 1:7; 1Jo 2:1, 2

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Heb 9:22-28—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé bó ṣe jẹ́ pé ẹbọ ìràpadà Jésù nìkan ló mú kó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá

    • Ifi 7:9, 10, 14, 15—Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé Ọlọ́run dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” jì wọ́n torí pé wọ́n nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù

Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, kí la gbọ́dọ̀ ṣe táwọn míì bá ṣẹ̀ wá?

Mt 6:14, 15; Mk 11:25; Lk 17:3, 4; Jem 2:13

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Job 42:7-10—Kó tó di pé Jèhófà wo Jóòbù sàn, tó sì bù kún un, ó ní kí Jóòbù gbàdúrà fáwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó sọ̀rọ̀ burúkú sí i

    • Mt 18:21-35—Jésù sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ ká rí i pé tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wá, àwa náà gbọ́dọ̀ máa dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá

Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa ká sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn?

Iṣe 3:19; 26:20; 1Jo 1:8-10

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Sm 32:1-5; 51:1, 2, 16, 17—Nígbà tí Ọba Dáfídì dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, inú ẹ̀ bà jẹ́ gan-an ó sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn

    • Jem 5:14-16—Jémíìsì sọ pé tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú gan-an, ó yẹ ká sọ fáwọn alàgbà

Àwọn àyípadà wo la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wá?

Owe 28:13; Ais 55:7; Ef 4:28

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Ọb 21:27-29; 2Kr 18:18-22, 33, 34; 19:1, 2—Nígbà tí Ọba Áhábù gbọ́ pé Jèhófà máa fìyà jẹ òun inú ẹ̀ bà jẹ́ gan-an, àmọ́ kò ronú pìwà dà tọkàntọkàn torí náà Jèhófà ò dárí jì í

    • 2Kr 33:1-16—Ọba Mánásè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tó burú gan-an, àmọ́ Jèhófà dárí jì í torí pé ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Mánásè gbìyànjú láti fòpin sí ìbọ̀rìṣà, káwọn èèyàn lè máa jọ́sìn Jèhófà, ìyẹn sì fi hàn pé ó yí pa dà lóòótọ́

Ṣé Jèhófà máa ń dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà pátápátá?

Sm 103:10-14; Ais 1:18; 38:17; Jer 31:34; Mik 7:19

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Sa 12:13; 24:1; 1Ọb 9:4, 5—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì dẹ́ṣẹ̀ tó burú gan-an, Jèhófà dárí jì í torí pé ó ronú pìwà dà. Nígbà tó sì yá, Jèhófà sọ pé Dáfídì rìn pẹ̀lú òtítọ́ ọkàn

Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun máa ń dárí jini fàlàlà bíi ti Jèhófà?

Sm 86:5; Lk 23:33, 34

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Mt 26:36, 40, 41—Ńṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó sún mọ́ ọn jù lọ sùn nígbà tó nílò ìrànlọ́wọ́ wọn jù, àmọ́ kò bínú sí wọn torí pé ó mọ ibi tágbára wọn mọ

    • Mt 26:69-75; Lk 24:33, 34; Iṣe 2:37-41 —Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù sọ pé òun ò mọ Jésù, àmọ́ ó ronú pìwà dà Jésù sì dárí jì í. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó lọ bá Pétérù ó sì fún un níṣẹ́ pàtàkì nínú ìjọ

Báwo la ṣe mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ni Jèhófà máa dárí jì?

Mt 12:31; Heb 10:26, 27; 1Jo 5:16, 17

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Mt 23:29-33—Jésù jẹ́ káwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí mọ̀ pé wọn ò ní bọ́ nínú ìdájọ́ Gẹ̀hẹ́nà, ìyẹn ìparun ráúráú

    • Jo 17:12; Mk 14:21—Jésù pé Júdásì Ìsìkáríọ́tù ní “ọmọ ìparun,” ó sì sọ pé ì bá sàn ká ní wọn ò bí ọ̀dàlẹ̀ ọkùnrin yìí

Kí ló máa ran àwa Kristẹni lọ́wọ́ ká lè máa dárí jini?