Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀

Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀

Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn onírẹ̀lẹ̀ àtàwọn agbéraga?

Sm 138:6; Owe 15:25; 16:18, 19; 22:4; 1Pe 5:5

Tún wo Owe 29:23; Ais 2:11, 12

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Kr 26:3-5, 16-21—Ọba Ùsáyà di agbéraga; ó rú Òfin Ọlọ́run, inú sì bí i nígbà tí wọ́n fún un nímọ̀ràn, torí náà Jèhófà fi ẹ̀tẹ̀ kọ lù ú

    • Lk 18:9-14—Jésù sọ àpèjúwe kan láti fi ṣàlàyé ojú tí Jèhófà fi ń wo àdúrà àwọn agbéraga àtàwọn onírẹ̀lẹ̀

Kí ni Jèhófà máa ṣe tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀, tó sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn?

2Kr 7:13, 14; Sm 51:2-4, 17

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Kr 12:5-7—Ọba Rèhóbóámù àtàwọn ìjòyè Júdà rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Jèhófà, torí náà Jèhófà ṣàánú wọn, kò sì pa wọ́n run mọ́

    • 2Kr 32:24-26—Ọba rere ni Hẹsikáyà, àmọ́ ó di agbéraga nígbà tó yá, ṣùgbọ́n nígbà tó rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀, Jèhófà dárí jì í

Tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, báwo nìyẹn ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn?

Ef 4:1, 2; Flp 2:3; Kol 3:12, 13

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 33:3, 4—Inú ń bí Ísọ̀ sí Jékọ́bù, àmọ́ Jékọ́bù fi hàn pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ nígbà táwọn méjèèjì pàdé, ìyẹn sì mú kí àlàáfíà jọba láàárín wọn lẹ́ẹ̀kan sí i

    • Ond 8:1-3—Gídíónì fi ìrẹ̀lẹ̀ sọ fáwọn ọkùnrin Éfúrémù pé wọ́n sàn ju òun lọ, ìyẹn sì mú kí ìbínú wọn rọlẹ̀

Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?

Mt 18:1-5; 23:11, 12; Mk 10:41-45

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Ais 53:7; Flp 2:7, 8—Níbàámu pẹ̀lú ohun táwọn wòlíì sọ, Jésù jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó gbà láti wá sáyé kó lè wá kú ikú oró, kí wọ́n sì pa á ní ìpa ìkà

    • Lk 14:7-11—Jésù sọ àpèjúwe kan nípa báwọn èèyàn ṣe ń jókòó níbi àsè kó lè jẹ́ ká rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀

    • Jo 13:3-17—Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé ó yẹ kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ nígbà tó rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀ tó sì fọ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀

Tá a bá ń fi ojú tó tọ́ wo ara wa àtàwọn ẹlòmíì, báwo nìyẹn ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?

Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn máa ṣojú ayé bíi pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?