Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Inú Rere

Inú Rere

Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé onínúure ni Jèhófà?

Ro 3:23, 24; Tit 3:3-6; Heb 2:9; 1Pe 5:5

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jon 3:10; 4:11—Jèhófà fi inúure hàn sáwọn ará Nínéfè, ó dárí jì wọ́n, kódà ó gba tàwọn ẹran wọn rò

    • Lk 6:32-36—Jésù kọ́ wa pé Jèhófà máa ń fi inúure hàn sí gbogbo èèyàn títí kan àwọn aláìmoore àtàwọn ẹni burúkú, torí náà ó rọ̀ wá pé káwa náà jẹ́ onínúure

Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a jẹ́ onínúure?

Owe 19:17; 22:9; Lk 6:35; Ef 4:32

Tún wo Owe 11:17; 31:10, 26; Heb 13:16

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Mk 14:3-9; Joh 12:3—Jésù gbóríyìn fún Màríà arábìnrin Lásárù torí pé ó jẹ́ ọ̀làwọ́, ó sì tún jẹ́ onínúure

    • 2Ti 1:16-18—Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n, Ónẹ́sífórù mára tù ú