Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìfẹ́

Ìfẹ́

Kí ni Jèhófà ṣe tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa?

Jer 31:3; Jo 3:16; Ro 5:8; 1Jo 4:8, 19

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 1:1, 26-31; 2:8, 9, 15, 16—Bí Jèhófà ṣe ṣẹ̀dá ayé, tó sì fún Ádámù àti Éfà ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó lè mú kí wọ́n gbádùn ayé wọn fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn

    • Sm 104:27-30—Ẹni tó kọ sáàmù yìí yin Jèhófà torí bó ṣe ń fìfẹ́ bójú tó àwọn ohun alààyè

Àwọn ọ̀nà wo la lè máa gbà fìfẹ́ hàn?

Jo 13:34, 35; 15:12, 13; 1Pe 4:8; 1Jo 4:10, 11; 5:3

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Mt 22:36-39—Jésù sọ pé àwọn àṣẹ méjì tó tóbi jù lọ ni pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ká sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn

    • 1Kọ 13:1-8—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì ká máa nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn; ó sì sọ bá a ṣe lè máa ṣe bẹ́ẹ̀