Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹni Tó Dàgbà Nípa Tẹ̀mí

Ẹni Tó Dàgbà Nípa Tẹ̀mí

Kí nìdí tó fi yẹ kí gbogbo Kristẹni máa ṣiṣẹ́ kára kí òtítọ́ lè jinlẹ̀ nínú wọn?

Tá a bá lóye ohun tó wà nínú Bíbélì, báwo nìyẹn ṣe lè mú kí òtítọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ nínú wa?

Ṣé àwọn tó ti dàgbà nìkan ni òtítọ́ lè jinlẹ̀ nínú wọn?

Job 32:9; 1Ti 4:12

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Da 1:6-20—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́ ni Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà

    • Iṣe 16:1-5—Nígbà tí Tímótì ṣì wà ní nǹkan bí ọmọ ogún ọdún, wọ́n fún un láǹfààní láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ pàtàkì nínú ìjọ

Tá a bá láwọn ọ̀rẹ́ tó dáa nínú ìjọ, báwo nìyẹn ṣe máa ṣe wá láǹfààní?

Àwọn nǹkan wo ló máa fi hàn pé Kristẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí ni wá?

Kí nìdí tó fi yẹ káwọn arákùnrin tó dàgbà nípa tẹ̀mí múra tán láti ṣe iṣẹ́ tó pọ̀ sí i nínú ìjọ?

Kí ni ohun kan ṣoṣo tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè dàgbà nípa tẹ̀mí, ká sì jẹ́ olùkọ́ tó já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni?

Lk 21:14, 15; 1Kọ 2:6, 10-13

Tún wo Lk 11:13

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Mt 10:19, 20—Jésù ṣèlérí fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ ohun tí wọ́n máa sọ táwọn èèyàn bá ń ṣenúnibíni sí wọn