Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àánú

Àánú

Kí ló túmọ̀ sí tí wọ́n bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ aláàánú?

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Sm 51:1, 2—Nígbà tí Ọba Dáfídì bẹ Jèhófà pé kó ṣàánú òun, ohun tó ń sọ ni pé kí Jèhófà dárí ji òun kó sì wẹ ẹ̀ṣẹ̀ òun mọ́

    • Lk 10:29-37—Jésù kọ́ wa nípa bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká jẹ́ aláàánú nígbà tó sọ àpèjúwe ará Samáríà tó fi inúure hàn sí Júù kan, tó sì gba tiẹ̀ rò

Kí nìdí tó fi máa ń wu àwa èèyàn kí wọ́n fàánú hàn sí wa?

Báwo la ṣe mọ̀ pé aláàánú ni Jèhófà?

Ẹk 34:6; Ne 9:17; Sm 103:8; 2Kọ 1:3

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Job 42:1, 2, 6-10; Jem 5:11—Jèhófà fàánú hàn sí Jóòbù, ó sì tún jẹ́ kó mọ bó ṣe lè jẹ́ aláàánú

    • Lk 15:11-32—Jésù jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe máa ń fàánú hàn nígbà tó sọ àpèjúwe bàbá kan tí ọmọ ẹ̀ ya ọlọ̀tẹ̀. Nígbà tí ọmọ náà ronú pìwà dà, bàbá ẹ̀ dárí jì í

Kí nìdí tí Jèhófà fi máa ń ṣàánú wa?

Báwo ni ẹbọ ìràpadà Kristi ṣe ń jẹ́ kí Ọlọ́run dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá?

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa bẹ Jèhófà pé kó fàánú hàn sí wa, kí sì nìdí tí kò fi yẹ ká ṣi àǹfààní náà lò?

Lk 11:2-4; Heb 4:16

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Sm 51:1-4—Inú Ọba Dáfídì bà jẹ́ gan-an nígbà tó hùwà tí kò dáa, torí náà ó rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀, ó sì bẹ Jèhófà pé kó dárí ji òun

    • Lk 18:9-14—Jésù sọ àpèjúwe kan ká lè mọ bí Jèhófà ṣe máa ń fàánú hàn sáwọn tó bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì gbà pé àwọn ṣàṣìṣe

Tẹ́nì kan bá tiẹ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, kí ló mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run lè fàánú hàn sí ẹni náà?

Di 4:29-31; Ais 55:7

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Kr 33:9-13, 15—Ọba Mánásè hùwà tó burú gan-an, àmọ́ ó ronú pìwà dà, ó sì bẹ Jèhófà pé kó dárí ji òun, Jèhófà wá sọ ọ́ di ọba lẹ́ẹ̀kan sí i. Lẹ́yìn náà, ọba yìí ṣe ohun tó fi hàn pé òun ti yíwà pa dà pátápátá

    • Jon 3:4-10—Àwọn ará ìlú Nínéfè burú gan-an, wọ́n máa ń hùwà ipá, ọ̀pọ̀ èèyàn ni wọ́n sì ti pa. Àmọ́ nígbà tí wọ́n ronú pìwà dà, Ọlọ́run fàánú hàn sí wọn

Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wá, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, ká sì yíwà pa dà?

Tí Jèhófà bá tiẹ̀ fi àánú hàn sí ẹnì kan, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ó máa dáàbò bo ẹni náà kó má bàa jìyà ohun tó ṣe

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣàánú àwọn èèyàn?

Tá ò bá ṣàánú àwọn èèyàn, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà?

Mt 9:13; 23:23; Jem 2:13

Tún wo Owe 21:13

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Mt 18:23-35—Jésù sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ ká rí i pé tá ò bá fàánú hàn sáwọn èèyàn, Jèhófà ò ní fàánú hàn sí wa

    • Lk 10:29-37—Jésù sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ ká rí i pé inú òun àti Bàbá ẹ̀ ò dùn sáwọn tí kì í ṣàánú àwọn èèyàn, àmọ́ ó fi hàn pé inú wọn dùn sáwọn tó bá ń ṣe bíi ti aláàánú ará Samáríà

Kí ni Jèhófà máa ṣe fáwọn tó bá jẹ́ aláàánú?