Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwà Tútù

Ìwà Tútù

Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ oníwà tútù?

Mt 11:28, 29; Jo 14:9

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Ọb 19:12—Nígbà tí wòlíì Èlíjà rẹ̀wẹ̀sì tí ọkàn ẹ̀ ò sì balẹ̀, Jèhófà fi “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́” bá a sọ̀rọ̀

    • Jon 3:10–4:11—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wòlíì Jónà fìbínú bá Jèhófà sọ̀rọ̀, Jèhófà fi sùúrù kọ́ ọ pé ó yẹ kó jẹ́ aláàánú

Àwọn nǹkan wo la lè ṣe tó máa fi hàn pé a jẹ́ oníwà tútù?

Owe 15:1; Ef 4:1-3; Tit 3:2; Jem 3:13, 17; 1Pe 3:15

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Nọ 11:26-29—Nígbà táwọn ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bíi wòlíì, Jóṣúà sọ fún Mósè pé kó pa wọ́n lẹ́nu mọ́, àmọ́ Mósè dáhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́

    • Ond 8:1-3—Nígbà táwọn ọkùnrin kan bínú sí Gídíónì tí wọ́n sì fẹ́ bá a jà, ó bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́, èyí sì mú kí ara wọn balẹ̀