Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwà Àìdáa

Ìwà Àìdáa

Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa táwọn èèyàn bá hùwà àìdáa sí wa?

Sm 69:20; Owe 18:14; Onw 4:1-3; Mal 2:13-16; Kol 3:21

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Sa 10:1-5—Nígbà táwọn ọ̀tá dójú ti àwọn kan lára àwọn ọmọ ogun Ọba Dáfídì, ó fi inúure hàn sí wọn

    • 2Sa 13:6-19—Támárì sunkún, ó sì fa aṣọ ara ẹ̀ ya lẹ́yìn tí Ámínónì fipá bá a lò pọ̀, tó dojú tì í, tó sì lé e jáde

Tí wọ́n bá hùwà àìdáa sẹ́nì kan, báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà mọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀, kí ló sì máa ṣe nípa ẹ̀?

Job 34:21, 22; Sm 37:8, 9; Ais 29:15, 19-21; Ro 12:17-21

Tún wo Sm 63:6, 7

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Sa 25:3, 14-17, 21, 32-38—Nábálì sọ̀rọ̀ burúkú sí Ọba Dáfídì, èyí sì fi ẹ̀mí àwọn ará ilé ẹ̀ sínú ewu. Nígbà tó yá, Jèhófà fìyà jẹ Nábálì, ó sì kú

    • Jer 20:1-6, 9, 11-13—Jeremáyà kọ́kọ́ rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí àlùfáà kan tó ń jẹ́ Páṣúrì lù ú, tó sì fi í sínú àbà; lẹ́yìn náà, Jèhófà fún Jeremáyà lókun, ó sì gbà á sílẹ̀