Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Owó

Owó

Kí nìdí tó fi léwu téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ owó?

Báwo ni Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé kò burú tẹ́nì kan bá ń ṣiṣẹ́ kára kó lè rówó gbọ́ bùkátà ìdílé ẹ̀?

Onw 7:12; 10:19; Ef 4:28; 2Tẹ 3:10; 1Ti 5:8, 18

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 31:38-42—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé léraléra ni Lábánì rẹ́ Jékọ́bù jẹ, ó ṣì ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ fún Lábánì, Jèhófà sì bù kún Jékọ́bù torí pé ó jẹ́ òṣìṣẹ́ kára

    • Lk 19:12, 13, 15-23—Àpèjúwe kan tí Jésù sọ jẹ́ ká rí i pé nígbà tó wà láyé, àwọn èèyàn sábà máa ń kó owó sórí òwò kí wọ́n lè rí owó tó pọ̀ sí i

Kí ni Bíbélì sọ nípa kéèyàn máa yá owó àti kéèyàn máa yá àwọn èèyàn lówó?

Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa yá owó nígbà tí kò pọn dandan?

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Ne 5:2-8—Nígbà ayé Nehemáyà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan máa ń hùwà ìkà sáwọn tó jẹ wọ́n lówó

    • Mt 18:23-25—Jésù sọ àpèjúwe kan tó rán wa létí pé wọ́n lè fìyà jẹ ẹni tó yá owó tí kò san án pa dà

Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣe ká tó bá ẹnì kan dòwò pọ̀, ẹni náà ì báà jẹ́ Kristẹni bíi tiwa, ẹni tí kì í ṣe Kristẹni, tàbí mọ̀lẹ́bí wa?

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 23:14-20—Nígbà tí Ábúráhámù fẹ́ lọ sin òkú ìyàwó ẹ̀, ó ra ilẹ̀ àti ihò kan, ó sì san owó níwájú àwọn ẹlẹ́rìí, kí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ àti ihò náà má bàa dìjà lọ́jọ́ iwájú

    • Jer 32:9-12—Nígbà tí wòlíì Jeremáyà ra ilẹ̀ lọ́wọ́ ọmọ arákùnrin bàbá ẹ̀, ó ṣe ìwé àdéhùn, ó ṣe ẹ̀dà ìwé náà, ó sì san owó ilẹ̀ náà níwájú àwọn ẹlẹ́rìí

Kí nìdí tó fi yẹ kéèyàn máa ṣètò bó ṣe fẹ́ náwó?

Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni máa kíyè sára kí ọ̀rọ̀ owó má bàa dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ?

Báwo la ṣe lè lo owó wa lọ́nà tó máa fi wá lọ́kàn balẹ̀ tó sì máa fún wa láyọ̀ tòótọ́?