Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbọràn

Ìgbọràn

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká máa ṣègbọràn?

Ẹk 19:5; Di 10:12, 13; Onw 12:13; Jem 1:22

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Sa 15:17-23—Wòlíì Sámúẹ́lì bá Ọba Sọ́ọ̀lù wí torí pé ó ṣàìgbọràn sí Jèhófà; lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ ká máa ṣègbọràn

    • Heb 5:7-10—Ẹni pípé ni Jésù, ìgbà gbogbo ló sì máa ń ṣègbọràn sí Bàbá rẹ̀. Àmọ́ nígbà tó wá sáyé, ó kọ́ bó ṣe lè máa ṣègbọràn sí Bàbá rẹ̀ nígbà ìṣòro

Kí ló yẹ kí Kristẹni kan ṣe táwọn aláṣẹ bá ní kó ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́?

Iṣe 5:29

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Da 3:13-18 —Àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta kan tó jẹ́ olóòótọ́ kọ̀ láti forí balẹ̀ fún ère tí Ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí wọ́n ṣe yẹn lè mú kí wọ́n pa wọ́n

    • Mt 22:15-22—Jésù sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa ń ṣègbọràn sáwọn aláṣẹ àyàfi tí wọ́n bá ní kí wọ́n ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́

    • Iṣe 4:18-31—Nígbà táwọn aláṣẹ sọ pé àwọn àpọ́sítélì ò gbọ́dọ̀ wàásù, ńṣe ni wọ́n ń bá a lọ láti máa fìgboyà wàásù

Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ máa bá a lọ láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà?

Di 6:1-5; Sm 112:1; 1Jo 5:2, 3

Tún wo Sm 119:11, 112; Ro 6:17

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Ẹsr 7:7-10—Àlùfáà Ẹ́sírà múra ọkàn ẹ̀ sílẹ̀ kó lè múpò iwájú nínú pípa Òfin Jèhófà mọ́, kó sì lè kọ́ àwọn èèyàn lófin náà

    • Jo 14:31—Jésù sọ ìdí tó fi jẹ́ pé ohun tí Bàbá ẹ̀ ní kó ṣe gẹ́lẹ́ ló máa ń ṣe

Kí ló yẹ kó máa mú wa ṣègbọràn sí Jèhófà àti Jésù?

Tá a bá jẹ́ onígbọràn, báwo nìyẹn ṣe máa fi hàn pé a nígbàgbọ́ tó lágbára?

Ro 1:5; 10:16, 17; Jem 2:20-23

Tún wo Di 9:23

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 6:9-22; Heb 11:7—Nóà kan ọkọ̀ áàkì “gẹ́lẹ́” bí Jèhófà ṣe ní kó kàn án, èyí sì fi hàn pé ó nígbàgbọ́

    • Heb 11:8, 9, 17—Ábúráhámù fi hàn pé òun nígbàgbọ̀ bó ṣe ṣègbọràn sí ohun tí Jèhófà sọ, ó fi ìlú Úrì sílẹ̀, ó sì tún múra tán láti fi ọmọ rẹ̀ rúbọ

Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń bù kún àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn?

Jer 7:23; Mt 7:21; 1Jo 3:22

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Le 26:3-6—Jèhófà ṣèlérí pé òun máa bù kún àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn, òun sì máa bójú tó wọn

    • Nọ 13:30, 31; 14:22-24—Jèhófà bù kún Kélẹ́bù torí pé ó jẹ́ onígbọràn

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sẹ́ni tó bá jẹ́ aláìgbọràn?

Ro 5:19; 2Tẹ 1:8, 9

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 2:16, 17; 3:17-19—Torí pé Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà, wọ́n pàdánù Párádísè tí Ọlọ́run dá wọn sí, wọn ò láǹfààní láti jẹ́ ẹni pípé mọ́, wọ́n sì tún pàdánù ìyè àìnípẹ̀kun

    • Di 18:18, 19; Iṣe 3:12, 18, 22, 23—Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé wòlíì kan ń bọ̀ tó máa tóbi ju Mósè, ó sì sọ pé òun máa fìyà jẹ àwọn tó bá ṣàìgbọràn sí i

    • Jud 6, 7—Nígbà táwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ àtàwọn ará ìlú Sódómù àti Gòmórà ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ohun tí wọ́n ṣe yẹn múnú bí Jèhófà gan-an

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣègbọràn sí Jésù Kristi?

Jẹ 49:10; Mt 28:18

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jo 12:46-48; 14:24—Jésù sọ pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣègbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ òun máa gba ìdájọ́ tó lágbára

Kí nìdí tó fi yẹ káwọn Kristẹni máa ṣègbọràn sáwọn alábòójútó nínú ìjọ?

Kí nìdí tó fi yẹ kí aya tó jẹ́ Kristẹni máa tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀?

Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọmọ máa jẹ́ onígbọràn sáwọn òbí wọn?

Owe 23:22; Ef 6:1; Kol 3:20

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 37:3, 4, 8, 11-13, 18—Nígbà tí Jósẹ́fù wà ní kékeré, ó ń ṣègbọràn sí bàbá ẹ̀, ó rìnrìn àjò lọ wo àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kórìíra ẹ̀

    • Lk 2:51—Ẹni pípé ni Jésù, àmọ́ aláìpé ni Jósẹ́fù àti Màríà tí wọ́n jẹ́ òbí ẹ̀, síbẹ̀ ó ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu

Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu ká máa ṣègbọràn sáwọn tó gbà wá síṣẹ́, tí kò bá tiẹ̀ sí ẹni tó ń ṣọ́ wa?

Kí nìdí táwọn Kristẹni fi máa ń ṣègbọràn sí ìjọba?