Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọjọ́ Ogbó; Àgbàlagbà

Ọjọ́ Ogbó; Àgbàlagbà

Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa bá a ṣe ń dàgbà?

Sm 71:9; 90:10

Tún wo “Ìtùnú—Téèyàn ò bá lè ṣe tó bó ṣe fẹ́ torí ìṣòro àìlera àti ọjọ́ ogbó

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Onw 12:1-8—Ọba Sólómọ́nì kọ ewì kan tó fi sọ̀rọ̀ nípa àwọn àìlera téèyàn máa ń ní bó ṣe ń dàgbà, lára wọn ni kí ojú máa wò bàìbàì (‘àwọn ọmọge tó ń wo ìta lójú fèrèsé rí i pé òkùnkùn ṣú’), kéèyàn má sì gbọ́ràn dáadáa (‘ohùn gbogbo àwọn ọmọbìnrin tó ń kọrin kò dún sókè mọ́’)

Ṣé àwọn àgbàlagbà lè máa láyọ̀ tí wọn ò bá tiẹ̀ lè ṣe tó bí wọ́n ṣe fẹ́ torí àwọn ìṣòro tí ọjọ́ ogbó máa ń mú wá?

2Kọ 4:16-18; Jem 1:2-4

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Sa 12:2, 23—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wòlíì Sámúẹ́lì ti dàgbà, ó mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kóhun máa gbàdúrà nítorí àwọn èèyàn Jèhófà

    • 2Sa 19:31-39—Ọba Dáfídì mọyì bí Básíláì tó jẹ́ àgbàlagbà ṣe dúró tì í, tó sì ràn án lọ́wọ́, àmọ́ Básíláì fi hàn pé òun mọ̀wọ̀n ara òun nígbà tó sọ fún Dáfídì pé òun ò ní lè bá a lọ sí Jerúsálémù

    • Sm 71:9, 18—Ẹ̀rù ń ba Ọba Dáfídì pé òun ò ní lè wúlò fún Jèhófà mọ́ bóun ṣe ń dàgbà, torí náà ó bẹ Jèhófà pé kó má pa òun tì, àmọ́ kó ran òun lọ́wọ́ kóun lè máa kọ́ ìran tó ń bọ̀ nípa rẹ̀

    • Lk 2:36-38—Opó ni wòlíì obìnrin kan tó ń jẹ́ Ánà, ó ti darúgbò, síbẹ̀ ó jẹ́ olóòótọ́, ó sì ń sin Jèhófà tọkàntọkàn, torí náà Jèhófà bù kún un

Báwo ni Jèhófà ṣe fi dá àwọn àgbàlagbà lójú pé òun mọyì wọn?

Sm 92:12-14; Owe 16:31; 20:29; Ais 46:4; Tit 2:2-5

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 12:1-4—Nígbà tí Ábúráhámù pé ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rìn (75), Jèhófà fún un ní iṣẹ́ pàtàkì kan tó gba pé kó kúrò ní ìlú tí wọ́n bí i sí, láì tún ní pa dà síbẹ̀ mọ́

    • Da 10:11, 19; 12:13—Wòlíì Dáníẹ́lì ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún (90) ọdún nígbà tí áńgẹ́lì kan wá bá a, tó sì sọ fún un pé ó ṣeyebíye lójú Jèhófà àti pé Jèhófà máa san án lẹ́san torí pé ó jẹ́ olóòótọ́

    • Lk 1:5-13—Nígbà tí Sekaráyà àti Èlísábẹ́tì ti darúgbó, Jèhófà ṣe ohun ìyanu kan fún wọn, ó fún wọn ní ọmọkùnrin kan, ìyẹn Jòhánù

    • Lk 2:25-35—Jèhófà jẹ́ kí ọkùnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Síméónì láǹfààní láti rí ọmọ tó máa di Mèsáyà, Ọlọ́rùn sì mí sí i láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa ọmọ náà

    • Iṣe 7:23, 30-36—Ẹni ọgọ́rin (80) ọdún ni Mósè nígbà tí Jèhófà sọ ọ́ di aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì

Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn àgbàlagbà tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà?

Le 19:32; 1Ti 5:1

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 45:9-11; 47:12—Jósẹ́fù ní kí wọ́n lọ mú bàbá òun tó ti darúgbó wá sọ́dọ̀ òun, ó sì tọ́jú rẹ̀ títí tó fi kú

    • Rut 1:14-17; 2:2, 17, 18, 23—Rúùtù dúró ti obìnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Náómì, ó ń tù ú nínú, ó sì ń ràn án lọ́wọ́

    • Jo 19:26, 27—Nígbà tí Jésù wà lórí òpó igi oró, ó ní kí àpọ́sítélì Jòhánù máa bá òun tọ́jú ìyá òun tó ti dàgbà

Àwọn nǹkan wo la lè ṣe tá a fi lè ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́ nínú ìjọ?