Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Inúnibíni

Inúnibíni

Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni máa retí inúnibíni?

Tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa, kí nìdí tó fi yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́?

Sm 55:22; 2Kọ 12:9, 10; 2Ti 4:16-18; Heb 13:6

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Ọb 19:1-18—Nígbà tí wọ́n ṣenúnibíni sí wòlíì Èlíjà, ó sọ gbogbo bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ̀ fún Jèhófà, Jèhófà wá fún un níṣìírí, ó sì tù ú nínú

    • Iṣe 7:9-15—Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ṣenúnibíni sí i, àmọ́ Jèhófà dúró tì í, ó kó o yọ nínú ìṣòro, ó sì lò ó láti ran ìdílé ẹ̀ lọ́wọ́

Àwọn ọ̀nà wo ni wọ́n lè gbà ṣe inúnibíni sí wa?

Wọ́n lè sọ̀rọ̀ burúkú sí wa

2Kr 36:16; Mt 5:11; Iṣe 19:9; 1Pe 4:4

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Ọb 18:17-35—Rábúṣákè tó jẹ́ aṣojú ọba Ásíríà pẹ̀gàn Jèhófà, ó sì sọ̀rọ̀ àbùkù sáwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù

    • Lk 22:63-65; 23:35-37—Àwọn tó ṣenúnibíni sí Jésù sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí i, wọ́n sì fi í ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà tí wọ́n fi sí àhámọ́ àti nígbà tí wọ́n kàn án mọ́gi oró

Àwọn ìdílé wa lè ta kò wá

Wọ́n lè fàṣẹ ọba mú wa, kí wọ́n sì gbé wa lọ sílé ẹjọ

Wọ́n lè lù wá

Àwọn jàǹdùkú lè gbéjà kò wá

Wọ́n lè pa wá

Kí ló yẹ káwa Kristẹni ṣe tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa?

Mt 5:44; Iṣe 16:25; 1Kọ 4:12, 13; 1Pe 2:23

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì

    • Iṣe 7:57–8:1—Nígbà tí Sọ́ọ̀lù ará Tásù àtàwọn jàǹdùkú kan fẹ́ pa ọmọ ẹ̀yìn tó ń jẹ́ Sítéfánù, nínú ìrora tó wà, ó ṣì bẹ Ọlọ́run pé kó dárí jì wọ́n

    • Iṣe 16:22-34—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lu Pọ́ọ̀lù tí wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n, ó fi inúure hàn sí ọkùnrin tó ń ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, ìyẹn sì mú kí ọkùnrin náà àti agbo ilé ẹ̀ di onígbàgbọ́

Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni kan lọ́gọ́rùn-ún ọdún kìíní?

Báwo ló ṣe yẹ kó rí lára wa tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa?

Tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa, báwo làwọn nǹkan rere tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú ṣe lè fún wa lókun?

Tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa, kí nìdí tí kò fi yẹ kójú tì wá tàbí ká rẹ̀wẹ̀sì, kí sì nìdí tí kò fi yẹ ká jẹ́ kíyẹn mú ká fi Jèhófà sílẹ̀?

Sm 56:1-4; Iṣe 4:18-20; 2Ti 1:8, 12

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Kr 32:1-22—Nígbà tí Ọba Senakérúbù kó ọmọ ogun tó pọ̀ láti wá bá Jerúsálẹ́mù jà, Ọba Hẹsikáyà jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ó gbẹ́kẹ̀ lé e, ó tún fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù lókun, Jèhófà sì ràn án lọ́wọ́

    • Heb 12:1-3—Àwọn alátakò fẹ́ dójú ti Jésù, àmọ́ kò jẹ́ kí nǹkan tí wọ́n ṣe mú kóun rẹ̀wẹ̀sì

Tí wọ́n bá ṣenúnibíni sí wa, àǹfààní wo ló lè mú wá?

Tá a bá fara da àdánwò, ó máa múnú Jèhófà dùn, ó sì máa mú ìyìn bá orúkọ rẹ̀

1Pe 2:19, 20; 4:12-16

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Job 1:6-22; 2:1-10—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù ò mọ̀ pé Sátánì ló ń mú kí nǹkan burúkú máa ṣẹlẹ̀ sóun, ó pinnu pé òun ò ní fi Jèhófà sílẹ̀. Ohun tó ṣe yìí fògo fún Jèhófà, ó sì fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì

    • Da 1:6, 7; 3:8-30—Ọba Nebukadinésárì tó jẹ́ abọ̀rìṣà yin Jèhófà níwájú gbogbo èèyàn torí pé Hananáyà, Míṣáẹ́lì, àti Asaráyà (Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò) ṣe tán láti kú dípò kí wọ́n ṣàìgbọràn sí Jèhófà

Inúnibíni lè mú ká láǹfààní láti wàásù fáwọn èèyàn tó pọ̀ sí i

Lk 21:12, 13; Iṣe 8:1, 4

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Iṣe 11:19-21—Inúnibíni mú káwọn Kristẹni tú ká ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, síbẹ̀ wọ́n ń bá a lọ láti máa wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo ibi tí wọ́n lọ

    • Flp 1:12, 13—Inú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dùn pé bí wọ́n ṣe fi òun sẹ́wọ̀n mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere

Tá a bá ń fara da inúnibíni, ìyẹn á mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ará wa túbọ̀ lágbára

Àwọn wo ló sábà máa ń wà nídìí inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwa èèyàn Jèhófà?

Jer 26:11; Mk 3:6; Jo 11:47, 48, 53; Iṣe 25:1-3

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Iṣe 19:24-29—Àwọn tó ń ṣe ojúbọ Átẹ́mísì nílùú Éfésù gbà pé ńṣe ni ìwàásù àwọn Kristẹni máa gba ìjẹ lẹ́nu àwọn, torí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni

    • Ga 1:13, 14—Kí Pọ́ọ̀lù (Sọ́ọ̀lù) tó di Kristẹni, ó nítara gan-an fún Ìsìn Àwọn Júù, èyí sì mú kó máa ṣenúnibíni sí ìjọ Kristẹni

Ta lẹni tó ń mú kí wọ́n ṣenúnibíni sáwa èèyàn Jèhófà?