Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àdúrà

Àdúrà

Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa ń tẹ́tí sí àdúrà wa tó sì máa ń dáhùn?

Sm 65:2; 145:18; 1Jo 5:14

Tún wo Sm 66:19; Iṣe 10:31; Heb 5:7

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Ọb 18:36-38—Nígbà táwọn wòlíì Báálì ń ta ko Èlíjà lórí Òkè Kámẹ́lì, ó gbàdúrà sí Jèhófà nípa ọ̀rọ̀ náà, Jèhófà sì dá a lóhùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀

    • Mt 7:7-11—Jésù ní ká tẹra mọ́ àdúrà, ó sì fi dá wa lójú pé Jèhófà Bàbá wa onífẹ̀ẹ́ máa dá wa lóhùn

Ta lẹnì kan ṣoṣo tó yẹ káwa Kristẹni máa gbàdúrà sí?

Orúkọ ta ló yẹ ká fi máa gbàdúrà sí Ọlọ́run?

Àdúrà àwọn wo ni Jèhófà máa ń dáhùn?

Àdúrà àwọn wo ni Jèhófà kì í dáhùn?

Owe 15:29; 28:9; Ais 1:15; Mik 3:4; Jem 4:3; 1Pe 3:7

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Joṣ 24:9, 10—Jèhófà kò dáhùn àdúrà Báláámù torí pé ohun tó béèrè ò bá ìfẹ́ rẹ̀ mu

    • Ais 1:15-17—Jèhófà ò gbọ́ àdúrà àwọn èèyàn ẹ̀ torí pé wọ́n ti di alágàbàgebè, ẹ̀jẹ̀ sì kún ọwọ́ wọn

Kí la máa ń sọ níparí àdúrà, kí sì nìdí tá a fi ń sọ ọ́?

Ṣé Bíbélì sọ pé ó pọn dandan ká kúnlẹ̀, ká dúró tàbí ká wà nípò kan pàtó tá a bá ń gbàdúrà?

Táwa èèyàn Jèhófà bá kóra jọ láti jọ́sìn, àwọn nǹkan wo la lè sọ nínú àdúrà wa?

Iṣe 4:23, 24; 12:5

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Kr 29:10-19—Ọba Dáfídì gbàdúrà níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n fi tinútinú ṣètìlẹyìn fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì

    • Iṣe 1:12-14—Àwọn àpọ́sítélì, àwọn arákùnrin Jésù, Màríà ìyá Jésù àtàwọn obìnrin olóòótọ́ míì kóra jọ sí yàrá òkè ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì ń gbàdúrà pa pọ̀

Tá a bá ń gbàdúrà, kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa gbéraga tàbí ká máa pe àfíyèsí sí ara wa?

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà tá a bá fẹ́ jẹun?

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo?

Ro 12:12; Ef 6:18; 1Tẹ 5:17; 1Pe 4:7

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Da 6:6-10—Wọ́n halẹ̀ mọ́ wòlíì Dáníẹ́lì pé wọ́n máa pa á, síbẹ̀ ó ń bá a lọ láti máa gbàdúrà sí Jèhófà nínú yàrá tó wà lórí òrùlé rẹ̀

    • Lk 18:1-8—Jésù sọ àpèjúwe kan nípa adájọ́ tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tó pa dà gbọ́ ẹjọ́ obìnrin opó kan torí pé obìnrin náà ò yéé wá sọ́dọ̀ ẹ̀. Ó lo àpèjúwe náà láti kọ́ wa pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà wa tá ò bá jẹ́ kó sú wa

Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run dárí ẹ̀sẹ̀ wa jì wá?

2Kr 7:13, 14

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Ọb 22:11-13, 18-20—Jèhófà ṣàánú Ọba Jòsáyà, ó sì fi inúure hàn sí i torí pé ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wá Jèhófà

    • 2Kr 33:10-13—Ọba Mánásè rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀, ó sì bẹ Jèhófà pé kó dárí ji òun. Jèhófà dárí jì í, ó sì dá a pa dà sórí ìtẹ́

Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà máa dárí jì wá, kí ló yẹ káwa náà máa ṣe?

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ?

Kí nìdí tí ìgbàgbọ́ fi ṣe pàtàkì tá a bá ń gbàdúrà?

Àwọn nǹkan wo la lè sọ nínú àdúrà?

Bí orúkọ Ọlọ́run ṣe máa di mímọ́

Bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa ṣàkóso ayé

Bí ìfẹ́ Jèhófà ṣe máa ṣẹ

Kí Jèhófà pèsè àwọn nǹkan tá a nílò fún wa

Kí Jèhófà dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá

Kí Jèhófà gbà wá lọ́wọ́ ìdẹwò

Ká máa dúpẹ́

Kí Jèhófà jẹ́ ká mọ ohun tó fẹ́, kó fún wa ní ọgbọ́n àti òye

Owe 2:3-6; Flp 1:9; Jem 1:5

Tún wo Sm 119:34

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Ọb 3:11, 12—Ọba Sólómọ́nì sọ pé kí Jèhófà fún òun ní ọgbọ́n, Jèhófà sì fún un lọ́gbọ́n tí kò láfiwé

Ní kí Jèhófà fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́

Máa gbàdúrà fáwọn ará, títí kan àwọn tí wọ́n ń ṣenúnibíni sí

Máa yin Jèhófà

Sm 86:12; Ais 25:1; Da 2:23

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Lk 10:21—Jésù yin Jèhófà ní gbangba torí pé ó fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ láǹfààní láti mọ òtítọ́

    • Ifi 4:9-11—Àwọn áńgẹ́lì máa ń fún Jèhófà ní ọlá àti ògo tó tọ́ sí i

Máa gbàdúrà nípa àwọn tó wà nípò àṣẹ kí wọ́n lè fún wa lómìnira láti máa sin Jèhófà ní fàlàlà, ká sì máa wàásù láìsí ìdíwọ́

Ṣé ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn gbàdúrà nígbà tó ń ṣèrìbọmi?

Ṣé ó yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn tó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí?

Kí nìdí táwọn ọkùnrin kì í fi í borí tí wọ́n bá ń gbàdúrà, kí sì nìdí táwọn obìnrin fi sábà máa ń bo orí tí wọ́n bá ń gbàdúrà?

Tá a bá tiẹ̀ ń gbàdúrà tó gùn tàbí tá à ń fi ìmọ̀lára tó lágbára hàn nínú àdúrà wa, kí lohun tó ṣe pàtàkì jù sí Jèhófà?

Ida 3:41; Mt 6:7

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Ọb 18:25-29, 36-39—Nígbà tí wòlíì Èlíjà pe àwọn wòlíì Báálì níjà, léraléra làwọn wòlíì náà ń pe ọlọ́run wọn, àmọ́ kò dá wọn lóhùn

    • Iṣe 19:32-41—Nǹkan bíi wákàtí méjì làwọn abọ̀rìṣà tó wà nílùú Éfésù fi ń ké pe òrìṣà Átẹ́mísì, àmọ́ kò dá wọn lóhùn, ni akọ̀wé ìlú náà bá fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ń da ìlú rú