Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìfòyebánilò

Ìfòyebánilò

Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni máa fòye báni lò?

Flp 4:5; Tit 3:2; Jem 3:17

Tún wo 1Ti 3:2, 3

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Jẹ 18:23-33—Jèhófà ní sùúrù fún Ábúráhámù nígbà tó ń bi í ní ìbéèrè nípa ìparun Sódómù àti Gòmórà

    • Jẹ 19:16-22, 30—Lọ́ọ̀tì ní kí Jèhófà jẹ́ kóun sá lọ sí Sóárì dípò tóun á fi sá lọ sí agbègbè olókè, Jèhófà sì gbà kó ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé Jèhófà máa ń fòye báni lò

    • Mt 15:21-28—Jésù fi hàn pé òun máa ń fòye báni lò, ó ṣe ohun tí obìnrin ará Foníṣíà kan béèrè nígbà tó rí i pé obìnrin náà ní ìgbàgbọ́ tó lágbára