Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìkóra-Ẹni-Níjàánu

Ìkóra-Ẹni-Níjàánu

Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun máa ń kó ara òun níjàánu?

Àwọn apá wo nínú ìgbésí ayé wa ló ti yẹ ká máa kó ara wa níjàánu?

Owe 16:32; 25:28; 1Kọ 9:25, 27

Tún wo 2Ti 2:23-25; Tit 1:7, 8

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Sa 16:5-14—Ọba Dáfídì kó ara ẹ̀ níjàánu nígbà tí Ṣíméì ń ṣépè fún un, tó sì ń sọ̀rọ̀ àbùkù sí i

    • 1Pe 2:21-23—Àpọ́sítélì Pétérù sọ bí Jésù ṣe kó ara ẹ̀ níjàánu lọ́nà tó lágbára nígbà táwọn èèyàn ń sọ̀rọ̀ àbùkù sí i, tí wọ́n sì ń fìyà jẹ ẹ́

Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè túbọ̀ máa kó ara wa níjàánu?

Lk 11:9-13; Ga 5:22, 23; Ef 4:23, 24; Kol 4:2

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Lk 11:5-8—Jésù jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká má ṣe jẹ́ kó sú wa láti máa bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́