Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Tí Kò Lọ́kọ Tàbí Láya

Àwọn Tí Kò Lọ́kọ Tàbí Láya

Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ẹ̀bùn ni kéèyàn wà láìlọ́kọ tàbí láìláya?

Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fipá mú Kristẹni kan láti lọ́kọ tàbí láya?

1Kọ 7:28, 32-35; 1Tẹ 4:11

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Ro 14:10-12—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ìdí tí kò fi yẹ ká máa dá Kristẹni bíi tiwa lẹ́jọ́

    • 1Kọ 9:3-5—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lẹ́tọ̀ọ́ láti gbéyàwó, àmọ́ bí kò ṣe níyàwó jẹ́ kó lè lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà

Ṣó yẹ káwọn tí kò tíì gbéyàwó máa rò pé ó dìgbà táwọn bá lọ́kọ tàbí láya káyé àwọn tó nítumọ̀?

1Kọ 7:8

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Ond 11:30-40—Ọmọbìnrin Jẹ́fútà ò lọ́kọ, àmọ́ ìgbésí ayé ẹ̀ nítumọ̀

    • Iṣe 20:35—Ọ̀rọ̀ tí Kristi sọ jẹ́ ká rí i pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò láya, ó láyọ̀ torí pé ó máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́

    • 1Tẹ 1:2-9; 2:12—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kò gbéyàwó, àmọ́ ó sọ bí iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe fún òun láyọ̀

Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tí kò tíì lọ́kọ tàbí láya máa yẹra fún ìṣekúṣe bíi ti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó kù?

1Kọ 6:18; Ga 5:19-21; Ef 5:3, 4

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Owe 7:7-23—Ọba Sólómọ́nì sọ̀rọ̀ nípa ohun burúkú tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́kùnrin kan tí kò kíyè sára, tó lọ kó sọ́wọ́ obìnrin oníṣekúṣe kan

    • Sol 4:12; 8:8-10—Wọ́n gbóríyìn fún ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì torí pé kì í ṣe oníṣekúṣe

Kí ló lè mú kí Kristẹni kan pinnu pé òun máa lọ́kọ tàbí láya?