Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọgbọ́n

Ọgbọ́n

Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ ní ọgbọ́n tòótọ́?

Ibo la ti lè rí ọgbọ́n tòótọ́?

Ṣó yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún wa ní ọgbọ́n?

Kol 1:9; Jem 1:5

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 2Kr 1:8-12—Nígbà tí Ọba Sólómọ́nì wà lọ́dọ̀ọ́, ó sọ pé kí Jèhófà fún òun ní ọgbọ́n kóun lè jẹ́ ọba tó dáa. Inú Jèhófà dùn sí nǹkan tó béèrè, ó sì fún un

    • Owe 2:1-5—Bíbélì fi ọgbọ́n, òye, àti ìfòyemọ̀ wé ìṣura tó ṣeyebíye tó yẹ kéèyàn wá, ó sì jẹ́ kó da wá lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fara balẹ̀ wá a

Báwo ni Jèhófà ṣe ń fún wa ní ọgbọ́n?

Ais 11:2; 1Kọ 1:24, 30; 2:13; Ef 1:17; Kol 2:2, 3

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Owe 8:1-3, 22-31—Bíbélì ṣàpèjúwe ọgbọ́n bíi pé èèyàn ni, àpèjúwe náà sì bá Jésù mú torí pé òun ni àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá

    • Mt 13:51-54—Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù ti mọ̀ ọ́n láti kékeré, torí náà ó yà wọ́n lẹ́nu nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tó ń sọ

Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ọgbọ́n Ọlọ́run?

Tá a bá ní ọgbọ́n, báwo ló ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ tó sì tún máa dáàbò bò wá?

Báwo ni ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe ṣeyebíye tó?

Onw 3:13, 14; 8:11

Tún wo Job 28:18

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Job 28:12, 15-19—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù ń jìyà gan-an tó sì ti pàdánù ọ̀pọ̀ nǹkan, ó ṣì ń yin Jèhófà torí ọgbọ́n rẹ̀

    • Sm 19:7-9—Ọba Dáfídì sọ pé tẹ́nì kan bá tiẹ̀ jẹ́ aláìmọ̀kan, tó bá ń tẹ̀ lé àwọn òfin Jèhófà àtàwọn ìránnilétí rẹ̀, ó máa di ọlọ́gbọ́n

Tá a bá ń tẹ̀ lé ọgbọ́n ayé yìí, àkóbá wo ló lè ṣe fún wa?