Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà


Bó o ṣe lè jàǹfààní púpọ̀ látinú ẹ̀kọ́ Bíbélì

Bó o ṣe lè jàǹfààní púpọ̀ látinú ẹ̀kọ́ Bíbélì

Jẹ́ kí ẹnì kan kọ́ ẹ: Sọ fún Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó fún ẹ ní ìwé yìí pé kó máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tàbí kó o béèrè fún ẹ̀kọ́ Bíbélì lórí ìkànnì wa, jw.org.

APÁ ÀKỌ́KỌ́

Ka ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, títí kan àwọn ìbéèrè tá a fi àwọ̀ tó yàtọ̀ kọ (A) àti àwọn ẹsẹ Bíbélì (B) tó gbé àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ yọ. Kíyè sí i pé o tún máa ka àwọn ẹsẹ Bíbélì kan tá a kọ “ka” sí.

ÀÁRÍN

Ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ (D) lábẹ́ Kẹ́kọ̀ọ́ Jinlẹ̀ jẹ́ àlàyé nípa ohun tó kàn. Àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ (E) sọ ohun tá a máa jíròrò. Ka àwọn ẹsẹ Bíbélì, dáhùn àwọn ìbéèrè, kó o sì wo àwọn fídíò tó wà níbẹ̀ (Ẹ).

Fara balẹ̀ wo àwọn àwòrán, ka àlàyé wọn (F), kó o sì ronú nípa bó o ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà lábẹ́ Àwọn Kan Sọ Pé (G).

APÁ TÓ GBẸ̀YÌN

Kókó Pàtàkì àti Kí Lo Rí Kọ́? (GB) la fi parí ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan. Kọ déètì tẹ́ ẹ parí ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan. Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe (H) sọ àwọn ohun tó o máa ṣe fúnra rẹ. Ṣèwádìí (I) jẹ́ àfikún ìsọfúnni tó o lè kà tàbí tó o lè wò.

Bó o ṣe lè rí àwọn ẹsẹ Bíbélì

Orúkọ ìwé Bíbélì ló máa ń ṣáájú (A), orí ìwé á tẹ̀ lé e (B), lẹ́yìn náà ẹsẹ tàbí àwọn ẹsẹ (D). Bí àpẹẹrẹ, Jòhánù 17:3 tọ́ka sí ìwé Jòhánù, orí 17, ẹsẹ 3.