Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé èèyàn lè wà láàyè títí láé?

Ṣé èèyàn lè wà láàyè títí láé?

Kí ni ìdáhùn rẹ?

  • Bẹ́ẹ̀ ni.

  • Bẹ́ẹ̀ kọ́.

  • Kò dá mi lójú.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.”​SÁÀMÙ 37:29.

ÀǸFÀÀNÍ WO LÓ MÁA ṢE Ẹ́?

Inú ẹ á máa dùn, wàá sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ.​JEREMÁYÀ 29:11.

Kì í ṣe àkókò díẹ̀ ni wàá fi gbádùn ayé ẹ, àmọ́ ńṣe ni wàá máa gbádùn ayé ẹ títí láé.​SÁÀMÙ 22:26.

ṢÉ O LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?

Bẹ́ẹ̀ ni! Tó o bá fẹ́ mọ ìdí tó fi yẹ kó o gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́, jọ̀ọ́ wo àwọn ẹ̀rí tó wà nínú ẹ̀kọ́ mẹ́ta tó wà nínú ìwé yìí. Àkòrí wọn ni: