ORIN 152
Ilé Tó Máa Mú Ìyìn Wá Bá Ọ
(1 Àwọn Ọba 8:27; 1 Kíróníkà 29:14)
1. Jèhófà, ìwọ lo dá ọ̀run,
Síbẹ̀, ọ̀run kò lè gbà ọ́.
Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ilé yìí,
Jọ̀ọ́, jẹ́ kẹ́mìí rẹ wà níbí.
Àwa tí a jẹ́ ènìyàn rẹ
Ti kọ́ ibi ìjọsìn yìí.
Ìjọsìn rẹ ń mú inú wa dùn;
Jọ̀ọ́, tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa.
(ÀSOPỌ̀)
Ìwọ náà lo fún wa
Ní gbogbo ohun tá a ní.
Inú ohun tó o fún wa
La ti ń fún ọ, Bàbá.
(ÈGBÈ)
A dúpẹ́ fún gbogbo ‘hun tó o ṣe,
Jèhófà, à ń kọrin yìn ọ́.
O ti jẹ́ ká lè kọ́ ilé yìí
Tó máa mú ìyìn wá bá ọ.
2. O mọ̀ pé a fẹ́ kọ́ ilé kan
Tó máa mú ìyìn wá bá ọ,
Tó máa ṣèrànwọ́ fẹ́gbẹ́ ará,
Táá sì ran àwọn míì lọ́wọ́.
A ti kọ́ ilé náà tán báyìí.
Iṣẹ́ ṣì pọ̀ gan-an láti ṣe.
Ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣiṣẹ́ tí
Ọmọ rẹ gbé lé wa lọ́wọ́.
(ÀSOPỌ̀)
A fi àkókò wa
Àti ohun ìní wa
Bọlá fún ọ torí pé
Ìwọ nìkan ló yẹ.
(ÈGBÈ)
A dúpẹ́ fún gbogbo ‘hun tó o ṣe,
Jèhófà, à ń kọrin yìn ọ́.
O ti jẹ́ ká lè kọ́ ilé yìí
Tó máa mú ìyìn wá bá ọ.