Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 153

Jẹ́ Kí N Ní Ìgboyà

Jẹ́ Kí N Ní Ìgboyà

(2 Ọba 6:16)

  1. 1. Ìbẹ̀rù ti bò mí​—

    Ìdààmú gbọkàn mi.

    Ọlọ́run jọ̀ọ́ fi mí mọ̀nà;

    Mo mọ̀ pó o máa gbà mí.

    Ìṣòro pọ̀ láyé,

    Ṣùgbọ́n mo gbà gbọ́ pé:

    Atóófaratì mà ni ọ́;

    Ayé mi dọwọ́ rẹ.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà, fún mi nígbàgbọ́

    Kí n lè máa rántí pé

    Àwọn ọ̀tá kò lè borí wa.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n nígboyà.

    Kí n sì ṣọkàn akin;

    Kí n fara dà á dópin.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n ní ìgboyà;

    Ìwọ ni aṣẹ́gun.

  2. 2. Tí ìbẹ̀rù bá dé.

    Ó ń múni rẹ̀wẹ̀sì.

    Ìwọ làpáta ààbò mi;

    O kì í jáni kulẹ̀.

    Jẹ́ kí n ní ìgboyà,

    Kí n má sì ṣe jáyà.

    Bó ti wù kí ‘ṣòro le tó​—

    Tìrẹ ni màá ṣe láé.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà, fún mi nígbàgbọ́

    Kí n lè máa rántí pé

    Àwọn ọ̀tá kò lè borí wa.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n nígboyà.

    Kí n sì ṣọkàn akin;

    Kí n fara dà á dópin.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n ní ìgboyà;

    Ìwọ ni aṣẹ́gun.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà, fún mi nígbàgbọ́

    Kí n lè máa rántí pé

    Àwọn ọ̀tá kò lè borí wa.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n nígboyà.

    Kí n sì ṣọkàn akin;

    Kí n fara dà á dópin.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n ní ìgboyà;

    Ìwọ ni aṣẹ́gun.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n ní ìgboyà;

    Ìwọ ni aṣẹ́gun.