Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 158

“Kò Ní Pẹ́ Rárá!”

“Kò Ní Pẹ́ Rárá!”

(Hábákúkù 2:3)

  1. 1. Àwòyanu ni,

    iṣẹ́ rẹ Baba,

    Torí pó o fẹ́ wa,

    lo ṣe dá gbogbo wọn.

    Ṣùgbọ́n ìṣòro

    ti pọ̀ jù láyé;

    a mọ̀ pé láìpẹ́,

    Wàá yanjú gbogbo rẹ̀.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà Baba wa,

    jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa.

    Jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ kó sú wa.

    À ń retí ọjọ́ náà,

    táyé tuntun máa dé.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè ní sùúrù.

    Ká fìwà jọ ọ́.

  2. 2. Téèyàn wa bá kú,

    ó máa ń dùn wá gan-an.

    O ṣèlérí pé

    wàá jí òkú dìde.

    A mọ̀ dájú pé

    ọ̀rọ̀ rẹ máa ṣẹ.

    Alèwílèṣe,

    jọ̀ọ́ jẹ́ ká ní sùúrù.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà Baba wa,

    jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa.

    Jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ kó sú wa.

    À ń retí ọjọ́ náà,

    táyé tuntun máa dé.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè ní sùúrù.

    Ká fìwà jọ ọ́.

  3. 3. Ikú ẹlẹ́ṣẹ̀

    kò wù ọ́ Baba.

    O fẹ́ kí gbogbo

    èèyàn wá dọ̀rẹ̀ẹ́ rẹ.

    O rán wa jáde,

    ká wàásù fún wọn,

    Káwa àtàwọn

    lè wà láàyè láéláé.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà Baba wa,

    jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa.

    Jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ kó sú wa.

    À ń retí ọjọ́ náà,

    táyé tuntun máa dé.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè ní sùúrù.

    Ká fìwà jọ ọ́.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè ní sùúrù!

(Tún wo Kól. 1:11.)