Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE LÈ BẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ WA

Ẹ̀KỌ́ 1

Sọ Ohun Táwọn Èèyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí

Sọ Ohun Táwọn Èèyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí

Ìlànà: “Ìfẹ́ . . . kì í wá ire tirẹ̀ nìkan.”—1 Kọ́r. 13:4, 5.

Ohun Tí Jésù Ṣe

1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Jòhánù 4:6-9. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  1.    Kí ni Jésù kíyè sí nípa obìnrin náà kó tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀?

  2.   Jésù sọ pé: “Fún mi lómi mu.” Kí nìdí tí ọ̀nà tí Jésù gbà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ yìí fi dáa?

Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?

2. Tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tó kan àwọn èèyàn àti ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí lo fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ, ó máa jẹ́ kí wọ́n fetí sí ẹ.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù

3. Múra láti sọ ọ̀rọ̀ míì. Má ṣe ronú pé ọ̀rọ̀ tó o ti ní lọ́kàn láti sọ náà lo gbọ́dọ̀ sọ. Ohun táwọn èèyàn ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ni kó o fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ. Bi ara ẹ pé:

  1.    ‘Kí ni wọ́n ń sọ nínú ìròyìn?’

  2.   ‘Kí làwọn ará àdúgbò, ará ibiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọ iléèwé mi ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀?’

4. Máa lákìíyèsí. Bi ara ẹ pé:

  1.   a. ‘Kí lẹni náà ń ṣe lọ́wọ́? Kí ló ṣeé ṣe kó máa ronú nípa ẹ̀?’

  2.  b. ‘Kí ni aṣọ tó wọ̀, ìrísí ẹ̀, tàbí bí ilé ẹ̀ ṣe rí jẹ́ kí n mọ̀ nípa ẹ̀sìn tó ń ṣe tàbí àṣà ìbílẹ̀ ẹ̀?’

  3.  d. ‘Ṣó yẹ kí n bá ẹni náà sọ̀rọ̀ lásìkò yìí?’

5. Máa fetí sílẹ̀.

  1.    Má sọ̀rọ̀ jù.

  2.   Jẹ́ kí ẹni náà sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. Bi í ní ìbéèrè nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀.