Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE LÈ BẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ WA

Ẹ̀KỌ́ 4

Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀

Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀

Ìlànà: “Ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ.”—Fílí. 2:3.

Ohun Tí Pọ́ọ̀lù Ṣe

1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Ìṣe 26:2, 3. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  1.    Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ nígbà tó ń bá Ọba Ágírípà sọ̀rọ̀?

  2.   Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jèhófà àti Ìwé Mímọ́ lòun gbára lé?—Wo Ìṣe 26:22.

Kí La Rí Kọ́ Lára Pọ́ọ̀lù?

2. Tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tá a sì ń bọ̀wọ̀ fáwọn tá à ń bá sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ wa máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù

3. Má ṣe máa fojú pa àwọn èèyàn rẹ́. Má wo ara ẹ bíi pé o ti mọ gbogbo nǹkan tán, má sì wo àwọn míì bíi pé wọn ò mọ nǹkan kan. Máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.

4. Jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé inú Bíbélì ni ọ̀rọ̀ rẹ ti wá. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń wọni lọ́kàn gan-an. Torí náà, tó bá jẹ́ pé ohun tó wà nínú Bíbélì lò ń kọ́ àwọn èèyàn, ìgbàgbọ́ wọn á túbọ̀ lágbára.

5. Máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́. Má ṣe fi dandan mú àwọn èèyàn láti fara mọ́ ohun tó o sọ, má sì máa bá àwọn èèyàn jiyàn. Tó o bá ń ní sùúrù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, tó o sì ń tètè kúrò níbì kan kọ́rọ̀ tó di wàhálà, wàá fi hàn pé onírẹ̀lẹ̀ ni ẹ́. (Òwe 17:14; Títù 3:2) Tó o bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́, èyí lè mú kó wù wọ́n láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ nígbà míì.