Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE LÈ BẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ WA

Ẹ̀KỌ́ 6

Jẹ́ Onígboyà

Jẹ́ Onígboyà

Ìlànà: “Ọlọ́run wa mú kí a mọ́kàn le kí a lè sọ ìhìn rere . . . fún yín.”—1 Tẹs. 2:2.

Ohun Tí Jésù Ṣe

1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Lúùkù 19:1-7. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  1.    Kí ló ṣeé ṣe kó mú káwọn kan kórìíra Sákéù?

  2.   Kí ló mú kí Jésù wàásù fún un?

Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?

2. A gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà ká tó lè wàásù ìhìn rere fún gbogbo èèyàn.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù

3. Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ran Jésù lọ́wọ́ láti wàásù, ẹ̀mí mímọ́ lè ran ìwọ náà lọ́wọ́. (Mát. 10:19, 20; Lúùkù 4:18) Tẹ́rù bá ń bà ẹ́ láti bá àwọn kan sọ̀rọ̀, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kó o nígboyà.—Ìṣe 4:29.

4. Má ṣe rò pé wọn ò ní gbọ́. Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o má wàásù fáwọn kan torí ìrísí wọn, bí wọ́n ṣe ń hùwà, ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe, ipò tí wọ́n wà láwùjọ àbí torí pé wọ́n jẹ́ olówó tàbí tálákà. Àmọ́, fi sọ́kàn pé:

  1.    A ò lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn, Jèhófà àti Jésù nìkan ló mọ̀ ọ́n.

  2.   Kò sẹ́ni tí Jèhófà ò lè ràn lọ́wọ́.

5. Jẹ́ onígboyà, àmọ́ máa ṣọ́ra. (Mát. 10:16) Má ṣe máa bá àwọn èèyàn jiyàn. Tẹ́nì kan ò bá fẹ́ gbọ́rọ̀ ẹ tàbí tó o rí i pé ó léwu láti máa bá ọ̀rọ̀ ẹ lọ pẹ̀lú ẹni náà, á dáa kó o rọra fi ibẹ̀ sílẹ̀.—Òwe 17:14.