PA DÀ LỌ
Ẹ̀KỌ́ 7
Má Jẹ́ Kó Sú Ẹ
Ìlànà: “Wọ́n ń kọ́ni láìdábọ̀, wọ́n sì ń kéde ìhìn rere.”—Ìṣe 5:42.
Ohun Tí Pọ́ọ̀lù Ṣe
1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Ìṣe 19:8-10. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí La Rí Kọ́ Lára Pọ́ọ̀lù?
2. Ó yẹ ká múra tán láti máa lo àkókò tó pọ̀ tó, ká sì máa ṣiṣẹ́ kára láti pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tá a wàásù fún, ká lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù
3. Lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn lásìkò tó rọrùn fún wọn. Bi ara ẹ pé: ‘Ìgbà wo lẹni náà máa ń ráyè jù? Ibo ló sì ti máa ń rọ̀ ọ́ lọ́rùn jù láti bá mi sọ̀rọ̀?’ Múra tán láti lọ sọ́dọ̀ ẹ̀, kódà tí àkókò náà ò bá rọrùn fún ẹ.
4. Ẹ jọ ṣàdéhùn. Gbogbo ìgbà tẹ́ ẹ bá ti parí ọ̀rọ̀ yín ni kó o máa béèrè ìgbà tó tún máa ráyè. Rí i pé o pa dà lọ lásìkò tẹ́ ẹ fi àdéhùn sí.
5. Má sọ̀rètí nù. Tó bá jẹ́ pé ẹnì kan kì í sábà sí nílé tàbí pé kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè, má rò pé ńṣe lẹni náà ò fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (1 Kọ́r. 13:4, 7) Òótọ́ ni pé o ò ní jẹ́ kó sú ẹ, síbẹ̀ má fàkókò ẹ ṣòfò.—1 Kọ́r. 9:26.