Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

PA DÀ LỌ

Ẹ̀KỌ́ 9

Máa Fọ̀rọ̀ Ro Ara Ẹ Wò

Máa Fọ̀rọ̀ Ro Ara Ẹ Wò

Ìlànà: “Ẹ máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń yọ̀; ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn tó ń sunkún.”—Róòmù 12:15.

Ohun Tí Jésù Ṣe

1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Máàkù 6:30-34. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  1.    Kí nìdí tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀ fi fẹ́ lọ síbi “tí àwọn nìkan máa wà”?

  2.   Kí ló mú kó wu Jésù láti kọ́ èrò rẹpẹtẹ náà?

Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?

2. Tá a bá ń fọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ro ara wa wò, kì í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan la máa sọ fún wọn, àá tún ràn wọ́n lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù

3. Máa fetí sílẹ̀ dáadáa. Jẹ́ kí ẹni náà sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. Má ṣe já lu ọ̀rọ̀ ẹ̀, má sì fojú kéré ìṣòro ẹ̀ àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀. Bákan náà, má ṣe bínú tí kò bá fara mọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì kan. Tó o bá fetí sílẹ̀ dáadáa, ẹni náà á rí i pé o ka ọ̀rọ̀ òun sí.

4. Máa ronú nípa ẹni náà. Ronú nípa ohun tẹ́ ẹ jọ sọ, kó o sì bi ara ẹ pé:

  1.    ‘Kí nìdí tó fi yẹ kó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?’

  2.   ‘Tó bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kí ìgbé ayé ẹ̀ àti ọjọ́ iwájú ẹ̀ dáa sí i?’

5. Sọ ohun tó máa ràn án lọ́wọ́. Tètè jẹ́ kó rí i pé tó bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó máa rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè ẹ̀, ayé ẹ̀ á sì dáa sí i.