SỌ WỌ́N DỌMỌ Ẹ̀YÌN
Ẹ̀KỌ́ 10
Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ìkẹ́kọ̀ọ́
Ìlànà: “A ti pinnu pé kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan la máa fún yín, a tún máa fún yín ní ara wa, torí ẹ ti di ẹni ọ̀wọ́n sí wa.”—1 Tẹs. 2:8.
Ohun Tí Jésù Ṣe
1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Jòhánù 3:1, 2. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Kí lo rò pé ó mú kí Nikodémù lọ bá Jésù lálẹ́?—Wo Jòhánù 12:42, 43.
-
Jésù gbà láti bá Nikodémù sọ̀rọ̀ lálẹ́. Báwo nìyẹn ṣe fi hàn pé ọwọ́ pàtàkì ló fi mú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn?
Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?
2. Tá a bá fẹ́ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó yẹ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, ká lè sọ wọ́n dọmọ ẹ̀yìn.
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
3. Múra tán láti kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ẹ ní àkókò àti ibi tó rọrùn fún un. Ó lè jẹ́ pé ọjọ́ tàbí àkókò pàtó kan ló máa ń rọrùn fún un. Ronú nípa ibi tó ti máa ń rọ̀ ọ́ lọ́rùn jù láti kẹ́kọ̀ọ́. Ṣé ibiṣẹ́ ni, ilé àbí ibòmíì? Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní àkókò àti ibi tó rọrùn fún un.
4. Máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Tó ò bá ní ráyè kọ́ ẹni náà lẹ́kọ̀ọ́ lọ́sẹ̀ kan, má torí ìyẹn wọ́gi lé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, o lè ṣe ọ̀kan nínú àwọn ohun mẹ́ta yìí:
5. Bẹ Jèhófà pé kó má jẹ́ kó sú ẹ. Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kó o máa fọwọ́ pàtàkì mú ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹni náà, tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè tàbí kì í yá a lára láti fàwọn ìlànà Bíbélì sílò. (Fílí. 2:13) Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o ráwọn ìwà tó dáa tẹ́ni náà ní, ìyẹn ò ní jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ̀ sú ẹ.