Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

SỌ WỌ́N DỌMỌ Ẹ̀YÌN

Ẹ̀KỌ́ 12

Má Bẹ̀rù Láti Sọ Òótọ́ Ọ̀rọ̀

Má Bẹ̀rù Láti Sọ Òótọ́ Ọ̀rọ̀

Ìlànà: “Òróró àti tùràrí máa ń mú ọkàn yọ̀; bẹ́ẹ̀ ni adùn ọ̀rẹ́ máa ń wá látinú ìmọ̀ràn àtọkànwá.”—Òwe 27:9.

Ohun Tí Jésù Ṣe

1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Máàkù 10:17-22. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  1.    Àwọn ìwà dáadáa wo ló ṣeé ṣe kí Jésù rí lára ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ náà?

  2.   Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù nífẹ̀ẹ́ ọkùnrin náà, kí nìdí tí kò fi yẹ kó bẹ̀rù láti bá a sòótọ́ ọ̀rọ̀?

Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?

2. Ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ó tún yẹ ká máa bá wọn sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ tó máa jẹ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù

3. Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ mọ ohun tó yẹ kó ṣe àti bó ṣe máa ṣe é.

  1.   a. Ẹ máa jíròrò apá tá a pè ní “Ohun tó yẹ kó o ṣe” ní ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!

  2.  b. Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ mọ àwọn nǹkan pàtó tó yẹ kó ṣe, kọ́wọ́ ẹ̀ lè tẹ àwọn àfojúsùn ẹ̀ ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú.

  3.  d. Máa gbóríyìn fún un bó ṣe ń tẹ̀ síwájú.

4. Mọ àwọn ohun tí kò jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ tẹ̀ síwájú, kó o sì ràn án lọ́wọ́ kó lè borí wọn.

  1.    Bi ara ẹ pé:

    • ‘Kí ló ń dí ẹni tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ tí kò fi gbé ìgbésẹ̀ láti ṣèrìbọmi?’

    • ‘Kí ni mo lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́?’

  2.   Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fìfẹ́ tọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ẹ sọ́nà, kó o má sì bẹ̀rù láti bá a sọ òótọ́ ọ̀rọ̀.

5. Tẹ́nì kan ò bá fẹ́ tẹ̀ síwájú, fòpin sí ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀.

  1.    Kó o lè mọ̀ bóyá ó yẹ kó o fòpin sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, bi ara ẹ pé:

    • ‘Ṣé ẹni tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ń fi ohun tó ń kọ́ sílò?’

    • ‘Ṣó máa ń wá sípàdé, ṣó sì máa ń sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn míì?’

    • ‘Lẹ́yìn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì débì kan, ṣó wù ú láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?’

  2.   Tí kò bá wu ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì tó máa jẹ́ kó tẹ̀ síwájú:

    • Ní kó ronú lórí ohun tí kò jẹ́ kó tẹ̀ síwájú.

    • Fìfẹ́ ṣàlàyé ìdí tó o fi fẹ́ fòpin sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.

    • Jẹ́ kó mọ àwọn ohun tó yẹ kó ṣe, kó tó lè pa dà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀.