Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀFIKÚN D

Bá A Ṣe Lè Fi Ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Bá A Ṣe Lè Fi Ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Ọ̀pọ̀ ìgbà la gbàdúrà tá a sì ṣe ìwádìí ká tó mú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! jáde. Káwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lè jàǹfààní dáadáa nínú ìwé yìí, tẹ̀ lé àwọn àbá yìí tó o bá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Kó o tó lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹnì kan

  1. 1. Múra sílẹ̀ dáadáa. Nígbà tó o bá ń múra sílẹ̀, ronú nípa ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ nílò, àwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó máa ṣẹlẹ̀ sí i, àti ojú tó fi ń wo nǹkan. Bákan náà, gbìyànjú láti ronú nípa àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣeé ṣe kó má tètè yé e àtàwọn nǹkan tó lè má rọrùn fún un láti fi sílò. Tún ronú nípa bó o ṣe lè fi apá tá a pè ní “Ṣèwádìí” ran akẹ́kọ̀ọ́ ẹ lọ́wọ́. Tó o bá sì rí ohun tó máa wúlò fún un ní apá yìí, ṣe tán láti lò ó nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́.

Tó o bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́

  1. 2. Tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ fàdúrà bẹ̀rẹ̀ kẹ́ ẹ sì fi parí.

  2. 3. Má jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ pọ̀ jù. Rí i pé ọ̀rọ̀ ẹ ò kọjá ohun tó wà nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, kó o sì jẹ́ kí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀.

  3. 4. Tẹ́ ẹ bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ apá kọ̀ọ̀kan nínú ìwé náà, rí i pé ẹ ka ohun tí apá náà dá lé, kó o sì mẹ́nu ba díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ tó wà níbẹ̀.

  4. 5. Tẹ́ ẹ bá ti parí apá kan, lo apá tá a pè ní “Kí lo rí kọ́? láti ran akẹ́kọ̀ọ́ ẹ lọ́wọ́ kó lè rántí àwọn ẹ̀kọ́ tó ti kọ́.

  5. 6. Bó o ṣe ń jíròrò ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́:

    1. a. Ka àlàyé tó wà nínú ẹ̀kọ́ náà.

    2. b. Ka gbogbo ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n kọ “Ka” sí.

    3. d. Ka àwọn ẹsẹ Bíbélì míì tó wà níbẹ̀ tó o bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀.

    4. e. Wo gbogbo fídíò tí wọ́n kọ “Wo” sí (tẹ́ ẹ bá lè rí i wò).

    5. ẹ. Bẹ́ ẹ ṣe ń jíròrò kókó kọ̀ọ̀kan, máa bi akẹ́kọ̀ọ́ ẹ láwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀.

    6. f. Ní kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ wo àwòrán tó wà ní apá tá a pè ní “Kẹ́kọ̀ọ́ Jinlẹ̀,” kó o sì ní kó ṣàlàyé ẹ̀.

    7. g. Lo àpótí náà “Ohun tó yẹ kó o ṣe” láti ràn án lọ́wọ́ kó lè mọ̀ bóyá òun ń tẹ̀ síwájú. O lè rọ̀ ọ́ pé kó ṣe ohun tí wọ́n kọ sínú àpótí náà, tàbí kó ronú nǹkan míì tó lè ṣe, ó sì lè ṣe méjèèjì.

    8. gb. Bi akẹ́kọ̀ọ́ ẹ pé, nígbà tó ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ sílẹ̀, èwo ló fẹ́ràn jù nínú àwọn àpilẹ̀kọ tàbí fídíò tó wà ní apá tá a pè ní “Ṣèwádìí.”

    9. h. Gbìyànjú láti parí ẹ̀kọ́ kan ní ìjókòó kan.

Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà

  1. 7. Máa ronú nípa ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹ lọ́wọ́ kó lè máa tẹ̀ síwájú, kó sì fún ìwọ náà lọ́gbọ́n kó o lè mọ bó o ṣe lè ràn án lọ́wọ́.