Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

DÍdúpẹ́ Lọ́wọ́ Jèhófà—Nípa Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún!

DÍdúpẹ́ Lọ́wọ́ Jèhófà—Nípa Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún!

Ìtàn Ìgbésí Ayé

DÍdúpẹ́ Lọ́wọ́ Jèhófà—Nípa Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún!

GẸ́GẸ́ BÍ STANLEY E. REYNOLDS ṢE SỌ Ọ́

Wọ́n bí mi ní London, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ní ọdún 1910. Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn òbí mi kó lọ sí abúlé kékeré kan tí wọ́n ń pè ní Westbury Leigh ní ẹkùn ilẹ̀ Wiltshire. Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, gbogbo ìgbà ni mo máa ń ṣe kàyéfì pé, ‘Ta ni Ọlọ́run?’ Kò sẹ́ni tó lè sọ fún mi. N ò sì mọ ohun tó fà á tí irú abúlé kékeré bíi tiwa yẹn ṣe ní láti ní ṣọ́ọ̀ṣì kéékèèké méjì àti ṣọ́ọ̀ṣì ńlá kan láti jọ́sìn Ọlọ́run.

NÍ 1935, ọdún mẹ́rin ṣáájú Ogun Àgbáyé Kejì, èmi àti Dick, àbúrò mi ọkùnrin, gun kẹ̀kẹ́ lọ sí Weymouth tí ń bẹ létíkun gúúsù ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, níbi táa ti lọ fún ìsinmi nínú àgọ́. Báa ṣe jókòó sínú àgọ́ wa táa ń gbọ́ bí ọ̀wàrà òjò ṣe ń dà yàà, táa sì ń ronú nípa ohun táa lè ṣe ni baba àgbàlagbà kan wá bá wa, ó fi àwọn ìwé mẹ́ta tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ mí—Duru Ọlọrun, Light Apá Kìíni, àti Light Apá Kejì. Mo gbà wọ́n, inú mi sì dùn pé màá rí nǹkan fi àkókò yẹn ṣe. Kíá ni ohun tí mo ń kà fà mí lọ́kàn mọ́ra, àmọ́ n ò mọ̀ nígbà yẹn pé òun ló máa yí ìgbésí ayé èmi àti àbúrò mi padà pátápátá.

Nígbà tí mo padà délé, màmá mi sọ fún mi pé Kate Parsons, tó ń gbé lábúlé wa, máa ń pín irú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé obìnrin ọ̀hún ti ń dàgbà, a mọ̀ ọ́n bí ẹní mowó nítorí pé ó máa ń gun alùpùpù kékeré kan láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tó wà láwọn ìletò tó wà gátagàta lágbègbè wa. Mo lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, inú rẹ̀ sì dùn láti fún mi ní àwọn ìwé Creation àti Ọrọ àti àwọn ìwé mìíràn tó jẹ́ ti Watch Tower Society. Ó tún sọ fún mi pé òun jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Lẹ́yìn tí mo ka àwọn ìwé wọ̀nyí pẹ̀lú Bíbélì mi, mo mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́, mo sì fẹ́ kọ́ bí a ṣe ń sìn ín. Bí mo ṣe kọ̀wé sí ṣọ́ọ̀ṣì wa nìyẹn pé n kì í ṣe ara wọn mọ́, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí lọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ilé John àti Alice Moody. Wọ́n ń gbé Westbury, ìyẹn ìlú tó sún mọ́ wa jù lọ. Àwa méje péré la máa ń wà láwọn ìpàdé wọ̀nyẹn. Kate Parsons máa ń tẹ dùùrù rẹ̀ bí gbogbo wa ti ń fi ìtara ọkàn kọ àwọn orin Ìjọba náà ṣáájú ìpàdé, àti lẹ́yìn tí ìpàdé bá parí!

Ní Ìbẹ̀rẹ̀

Mo rí i pé àkókò pàtàkì là ń gbé, ó sì wù mí láti kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù tí a sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nínú Mátíù 24:14. Nítorí bẹ́ẹ̀, mo ṣíwọ́ sìgá mímu, mo ra àpò ìkówèésí kan, mo sì ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà, Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo.

Ní August 1936, Joseph F. Rutherford, tó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà ṣèbẹ̀wò sí Glasgow, Scotland, láti sọ̀rọ̀ lórí kókó náà, “Amágẹ́dọ́nì.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Glasgow tó nǹkan bí ẹgbẹ̀ta kìlómítà sí ọ̀dọ̀ wa, mo pinnu láti wà níbẹ̀, kí n sì ṣe ìrìbọmi ní àpéjọpọ̀ yẹn. Owó tí mo ní lọ́wọ́ ò tó nǹkan, mo wá gbé kẹ̀kẹ́ mi wọ ọkọ̀ ojú irin tó ń lọ sí Carlisle, ìlú kan tó wà ní ààlà Scotland, ibẹ̀ ni mo ti wá fi kẹ̀kẹ́ rin ọgọ́jọ kìlómítà lọ sí ìhà àríwá jíjìnnà. Èyí tí mo fi gun kẹ̀kẹ́ ló pọ̀ jù nígbà tí mo ń padà sílé, ó rẹ̀ mí tẹnutẹnu àmọ́, mo lókun nípa tẹ̀mí.

Láti ìgbà yẹn lọ, kẹ̀kẹ́ ni mo máa ń gùn nígbàkigbà tí mo bá fẹ́ lọ bá àwọn ènìyàn tó wà láwọn abúlé itòsí sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ mi. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan ló ní káàdì ìjẹ́rìí tirẹ̀ lọ́wọ́, ìyẹn ni káàdì tó láwọn ìsọfúnni tó bá Ìwé Mímọ́ mu nínú táa máa ń fún àwọn onílé kà. A tún ń lo ohun èlò agbóhùnjáde tó rí mọ́ńbé láti gbọ́ àwọn àsọyé Bíbélì tí a gbà sílẹ̀ látẹnu ààrẹ Society. Àmọ́, a tún máa ń gbé àpò ìwé ìròyìn, a tó ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá.

Ṣíṣe Aṣáájú Ọ̀nà Lákòókò Ogun

Àbúrò mi ọkùnrin ṣe ìrìbọmi ní 1940. Ogun Àgbáyé Kejì ti bẹ̀rẹ̀ ní 1939, àwa méjèèjì sì rí ìdí tó fi jẹ́ kánjúkánjú láti ní àwọn oníwàásù alákòókò kíkún. Nítorí náà, a fọwọ́ sí ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. A dúpẹ́ gan-an ni pé wọ́n yan àwa méjèèjì sí ilé àwọn aṣáájú ọ̀nà tó wà ní Bristol, ibẹ̀ la ti lọ dara pọ̀ mọ́ Edith Poole, Bert Farmer, Tom àti Dorothy Bridges, Bernard Houghton, àti àwọn aṣáájú ọ̀nà mìíràn tí ìgbàgbọ́ wọn máa ń wú wa lórí gan-an.

Kò pẹ́ tí mọ́tò kékeré kan tí wọ́n kọ “ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ” gàdàgbà-gadagba sí lára dé tó sì gbé wa. Stanley Jones ló wa ọkọ̀ náà, òun náà tún wá di míṣọ́nnárì ní China, wọ́n sì jù ú sínú àhámọ́ àdáwà níbẹ̀ fún ọdún méje gbáko nítorí iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀.

Bí ogun náà ti ń le sí i, agbára káká la fi ń rí oorun sùn lóru. Bọ́ǹbù máa ń bú gbàù ní àyíká ilé aṣáájú ọ̀nà wa ni, a sì ní láti máa wà lójúfò ní gbogbo ìgbà nítorí àwọn àdó oníná. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, a kúrò ní àárín gbùngbùn ìlú Bristol lẹ́yìn táa parí àpéjọ kan tó mìrìngìndìn, tí igba àwọn Ẹlẹ́rìí péjọ sí, a sì gba àárín ìràlẹ̀rálẹ̀ ohun ọṣẹ́ tó ti bú gbàù tó fọ́n ká sí gbogbo ilẹ̀, dé ilé wa táa lè sọ pé ó ní ààbò díẹ̀.

Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, èmi àti Dick padà lọ sáàárín ìlú láti lọ kó àwọn nǹkan díẹ̀ táa gbàgbé. Jìnnìjìnnì mú wa. Bristol ti di òkìtì àlàpà. Gbogbo àárín ìlú ti fọ́ yángá, wọ́n sì ti dáná sun ún. Òpópónà Park, tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa wà tẹ́lẹ̀ ti di òkìtì pàǹtírí tí ń rú èéfín. Àmọ́, kò sí Ẹlẹ́rìí kankan tí wọ́n pa tàbí tó fara pa. Inú wa dùn pé a ti kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa kúró ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, a sì ti pín wọn káàkiri ilé àwọn mẹ́ńbà ìjọ. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé àwọn ará ò kú, àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa ò sì run.

Òmìnira Àìròtẹ́lẹ̀

Ìjọ Bristol tí mo ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó olùṣalága tí gbèrú débi tó ti ní àwọn òjíṣẹ́ mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ní àkókò tí mo rí ìwé gbà pé kí n wá fún iṣẹ́ ológun. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ni wọ́n ti rán lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n nítorí àìdá sí tọ̀túntòsì wọn, mo sì retí pé èmi náà yóò pàdánù òmìnira àtiwàásù. Ilé Ẹjọ́ kan ládùúgbò Bristol ni wọ́n ti gbọ́ ẹjọ́ mi, níbi tí Arákùnrin Anthony Buck, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n tẹ́lẹ̀, ti gbẹnu sọ fún mi. Ọkùnrin onígboyà tí kì í bẹ̀rù ni, ó tún jẹ́ ẹnì kan tí kì í fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú òtítọ́ Bíbélì, ó ṣe gudugudu méje nígbà ìgbẹ́jọ́ náà, wọ́n sì dá mi sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú iṣẹ́ ológun láìròtẹ́lẹ̀, ìyẹn tí mo bá ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tí mo ń ṣe lọ ni o!

Inú mi dùn pé mo ní òmìnira, mo sì pinnu láti fi wàásù dé ibi tí agbára mi bá lè gbé e dé. Nígbà tí mo gbọ́ ìpè pé kí n wá sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ ní London láti wá bá Albert D. Schroeder, tó jẹ́ alábòójútó ẹ̀ka sọ̀rọ̀, àyà mi là gàrà nítorí pé n ò mọ ohun tí mo máa bá ńbẹ̀. Fojú inú wo bó ṣe yà mí lẹ́nu tó nígbà tí wọ́n ní kí n wá lọ sí Yorkshire láti sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò, kí n máa bẹ ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́, kí n sì gba àwọn ará níyànjú. Ó ṣe mi bí ẹni pé n ò tóótun rárá láti ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, àmọ́, wọ́n kúkú ti fún mi lómìnira mo sì láǹfààní àtilọ. Nítorí náà mo tẹ́wọ́ gba ibi tí Jèhófà darí mi sí, mo sì fi tinútinú lọ.

Albert Schroeder fi mí han àwọn ará ní àpéjọ kan ní Huddersfield, ìgbà tó sì di April 1941, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tuntun tí a yàn fún mi. Inú mi mà dùn gan-an o, pé mo wá mọ àwọn arákùnrin ọ̀wọ́n wọ̀nyẹn! Ìfẹ́ àti inú rere wọn jẹ́ kí n túbọ̀ mọyì pé Jèhófà ní àwọn èèyàn kan tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ pátápátá fún un tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn.—Jòhánù 13:35.

Àwọn Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Púpọ̀ Sí I

A ṣe àpéjọpọ̀ mánigbàgbé kan fún ọjọ́ márùn-ún gbáko ní Gbọ̀ngàn De Montfort tó wà nílùú Leicester ní ọdún 1941. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíṣọ́ là ń ṣọ́ oúnjẹ jẹ, tí àwọn ohun ìrìnnà kò sì lè rìn bí wọ́n ṣe fẹ́, síbẹ̀ iye àwọn tó wá pọ̀ gan-an táa fi wọ ẹgbẹ̀rún méjìlá ní ọjọ́ Sunday; bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìwọ̀nba díẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní orílẹ̀-èdè náà fi lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá nígbà yẹn. A gbọ́ àwọn àsọyé tí wọ́n ti gbà sílẹ̀ lórí ẹ̀rọ látẹnu ààrẹ Society, ibẹ̀ ni wọ́n sì ti mú ìwé Children jáde. Ó dájú pé àpéjọpọ̀ yẹn jẹ́ mánigbàgbé nínú ìtàn ìṣàkóso àtọ̀runwá ti àwọn ènìyàn Jèhófà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, bẹ́ẹ̀ ìgbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ń lọ lọ́wọ́ la ṣe é.

Kété lẹ́yìn àpéjọpọ̀ yìí ni wọ́n ké sí mi pé kí n wá sìn pẹ̀lú ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní London. Ibẹ̀ ni mo ti ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìkówèéránṣẹ́ àti ìdìwé, ìgbà tó yá mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì, tí mo wá ń bójú tó àwọn ọ̀ràn tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ìjọ.

Ìdílé Bẹ́tẹ́lì dojú kọ wàhálà bọ́ǹbù táwọn ọkọ̀ òfuurufú ń rọ̀jò rẹ̀ sórí ìlú London tọ̀sán tòru, bẹ́ẹ̀ náà ni wàhálà bí àwọn aláṣẹ ṣe ń fi gbogbo ìgbà tọpinpin àwọn arákùnrin tó ń bójú tó iṣẹ́ níbẹ̀. Wọ́n ju Pryce Hughes, Ewart Chitty, àti Frank Platt sẹ́wọ̀n nítorí àìdásí-tọ̀tún-tòsì, níkẹyìn wọ́n ní kí Albert Schroeder káńgárá ẹ̀ kúrò lórílẹ̀-èdè àwọn, kó máa lọ sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Láìfi gbogbo pákáǹleke wọ̀nyí pè, a ń bá a lọ láti máa bójú tó àwọn ìjọ àti ire Ìjọba náà dáradára.

Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead Yá!

Nígbà tí ogun parí ní 1945, mo kọ̀wé béèrè fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ míṣọ́nnárì ní ilé ẹ̀kọ Watchtower Bible School of Gilead, wọ́n sì pè mí fún kíláàsì kẹjọ ní 1946. Society ṣètò fún àwa bíi mélòó kan, títí kan Tony Attwood, Stanley Jones, Harold King, Don Rendell, àti Stanley Woodburn, láti rìnrìn àjò lójú òkun láti èbútékọ̀ ẹja pípa ti ẹkùn ilẹ̀ Cornwall tí ń bẹ ní ìpínlẹ̀ Fowey Ẹlẹ́rìí kan tó wà ládùúgbò náà ti forúkọ wa sílẹ̀ pé ká wọkọ̀ òkun tó ń kó ohun èlò amọ̀ funfun. Ibi tí wọ́n fi wá sí há gádígádí, omi sì fẹ́rẹ̀ẹ́ bo ara ọkọ̀ náà tán. Kẹ́ẹ wá wo bí ọkàn wa ṣe balẹ̀ tó nígbà táà ń sún mọ́ èbúté táa máa gúnlẹ̀ sí, ìyẹn ni ìpínlẹ̀ Filadéfíà!

Ọgbà ilé ẹ̀kọ́ Gilead jẹ́ ibi rírẹwà kan tí wọ́n kọ́ sí Gúúsù Lansing níhà àríwá New York, ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ níbẹ̀ sì jọ mí lójú gan-an ni. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní kíláàsì wa wá láti orílẹ̀-èdè méjìdínlógún—ìgbà àkọ́kọ́ tí Society pe àwọn òjíṣẹ́ tó pọ̀ gan-an láti ilẹ̀ òkèèrè nìyẹn—a sì nífẹ̀ẹ́ ara wa bíi tọmọ tìyá. Mo gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ èmi àti Kalle Salavaara, alábàágbé mi tó wá láti Finland.

Kíá lọjọ́ pé, bí oṣù márùn-ún náà sì ti ń parí ni Nathan H. Knorr, tó jẹ́ ààrẹ Society nígbà náà dé láti orílé-iṣẹ́ ní Brooklyn láti fún wa ní ìwé ẹ̀rí wa àti láti sọ ibi tí wọ́n yàn wá sí fún wa. Láyé ọjọ́un, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kì í mọ ibi tí a yàn wọ́n sí kí ó tó di ìgbà tí wọ́n bá kéde rẹ̀ ní ọjọ́ àṣeyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege wọn. Wọ́n ní kí n padà sí Bẹ́tẹ́lì ti London kí n máa bá iṣẹ́ mi lọ níbẹ̀.

Mo Padà sí London

Àwọn ọdún ẹ̀yìn ogun le koko ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ńṣe la rọra ń ṣọ́ oúnjẹ jẹ, táa sì ń ṣọ́ àwọn nǹkan mìíràn títí kan bébà lò. Ṣùgbọ́n a yí i mọ́ ọn, ire Ìjọba Jèhófà sì ń tẹ̀ síwájú. Ní àfikún sí iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì, mo tún ń sìn ní àwọn ìpàdé àgbègbè àti ti àyíká, mo sì tún ń bẹ àwọn ìjọ wò, títí kan àwọn ìjọ kan ní Ireland. Àǹfààní ló jẹ́ láti bá Erich Frost àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wá láti Yúróòpù pàdé, àti láti tẹnu wọn gbọ́ nípa ìwà títọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wa tí ojú wọ́n rí màbo nínú ọgbà ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti ìjọba Násì. Àǹfààní tó ní ìbùkún yabuga ni iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì jẹ́.

Ó ti pé ọdún mẹ́wàá tí mo ti mọ Joan Webb, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan tó ń sìn ní Watford, ìlú kan tó wà ní àríwá London gan-an. A ṣe ìgbéyàwó ní 1952. Àwa méjèèjì la fẹ́ máa bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún nìṣó, ìdí nìyẹn tí inú wa fi dùn gan-an nígbà tí wọ́n yàn mí sí iṣẹ́ alábòójútó àyíká lẹ́yìn tí mo kúrò ní Bẹ́tẹ́lì. Àyíká wa àkọ́kọ́ pàá wà ní etíkun gúúsù ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ní àgbègbè Sussex àti Hampshire. Iṣẹ́ alábòójútó àyíká ò rọrùn rárá nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Bọ́ọ̀sì, kẹ̀kẹ́, àti ẹsẹ̀ ni olórí ohun tí a fi ń rìnrìn àjò. Ọ̀pọ̀ ìjọ ló ní àwọn ìpínlẹ̀ tó tóbi gan-an láwọn eréko, tó sì máa ń ṣòro láti dé, àmọ́ iye àwọn Ẹlẹ́rìí ń pọ̀ sí i ṣáá ni.

New York City ní 1958

Lọ́dún 1957, mo rí ìkésíni mìíràn gbà láti Bẹ́tẹ́lì pé: “Ṣé wàá lè wá sí ọ́fíìsì kóo wá ràn wá lọ́wọ́ láti ṣètò ìrìn àjò fún ìpàdé àgbáyé tó ń bọ̀, tí a ó ṣe ní Pápá Ìṣeré Yankee àti Polo Grounds ti New York City ní 1958?” Láìpẹ́, èmi àti Joan ti bẹ̀rẹ̀ sí bójú tó àwọn ìwé ìforúkọsílẹ̀ tí àwọn ará ń fi ránṣẹ́ fún ọkọ̀ òfuurufú àti ọkọ̀ òkun tí Society háyà. Èyí ló wá jẹ́ Ìpàdé Àgbáyé Ìfẹ́ Àtọ̀runwá tí òkìkí rẹ̀ kàn, èyí tí àwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínláàádóje dín méjìdínlọ́gọ́rin [253,922]. Ní àpéjọpọ̀ yìí, ẹgbẹ̀rún méje, ọgọ́rùn-ún kan àti mẹ́rìndínlógójì [7,136] ló ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí àmì pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà—iye yẹn ju ìlọ́po méjì àwọn tó ṣe ìrìbọmi níbi ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé ti ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, bí Bíbélì ṣe ròyìn.—Ìṣe 2:41.

Èmi àti Joan ò lè gbàgbé inú rere tí Arákùnrin Knorr fi hàn sí wa nígbà tó fúnra rẹ̀ pè wá láti lọ sí àpéjọ yẹn ká lè bá wọn bójú tó àwọn tí wọ́n wá sí àpéjọpọ̀ náà, tí wọ́n ń gúnlẹ̀ sí New York City láti orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélọ́gọ́fà. Ó jẹ́ ìrírí tó fún àwa méjèèjì láyọ̀ àti ìwúrí.

Àwọn Ìbùkún Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún

Nígbà táa padà dé, a tún ń bá iṣẹ́ arìnrìn-àjò wa lọ títí tí àìlera fi bẹ̀rẹ̀ sí yọjú. Wọ́n dá Joan dúró sí ilé ìwòsàn, èmi náà sì ní àrùn ẹ̀gbà díẹ̀. A wá padà sẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìyẹn, a tún láǹfààní àtisìn fúngbà díẹ̀ nínú iṣẹ́ alábòójútó àyíká lẹ́ẹ̀kan sí i. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, a padà sí Bristol, níbi táa ti wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún di ìsinsìnyí. Dick, àbúrò mi àti ìdílé rẹ̀ ń gbé nítòsí, gbogbo ìgbà la sì máa ń rántí àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá.

Ojú mi bà jẹ́ kọjá àtúnṣe ní 1971, nígbà tí awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí ń gba ìmọ́lẹ̀ wọlé kọṣẹ́. Àtìgbà yẹn ni àtikàwé ti di ìṣòrò ńlá fún mi, nípa bẹ́ẹ̀ mo wá rí i pé àwọn kásẹ́ẹ̀tì tí wọ́n ka àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí jẹ́ ohun àgbàyanu látọ̀dọ̀ Jèhófà. Èmi àti Joan ṣì máa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, a ti láǹfààní àtiran àwọn bí ogójì ènìyàn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ òtítọ́, títí kan ìdílé kan tó ní èèyàn méje nínú.

Nígbà táa ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Jèhófà ní ohun tó lé lọ́gọ́ta ọdún sẹ́yìn, ìfẹ́ ọkàn wa ni pé ká wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ká sì máa wà nínú rẹ̀ títí lọ. Ẹ wo bí a ṣe kún fún ìmoore tó pé a ṣì ní okun láti sin Jèhófà Atóbilọ́lá—ọ̀nà kan ṣoṣo táa lè gbà dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún oore rẹ̀ sí wa àti fún àwọn ọdún táa jọ fayọ̀ gbé pa pọ̀ nìyẹn!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àpò kan tí wọ́n fi aṣọ ṣe, tó ṣeé gbé kọ́ èjìká, ohun tí wọ́n sì ṣe é fún ni pé ká lè máa fi kó àwọn Ilé Ìṣọ́ àti Consolation (tó wá di Jí! níkẹyìn).

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Èmi àti Dick àbúrò mi ọkùnrin (Dick ló dúró lápá òsì pátápátá) àtàwọn aṣáájú ọ̀nà mìíràn níwájú ilé àwọn aṣáájú ọ̀nà tó wà ní Bristol

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ilé àwọn aṣáájú ọ̀nà ní Bristol ní 1940

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Stanley àti Joan Reynolds lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn, January 12, 1952, àti lónìí