Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Tóbi Ju Ọkàn-àyà Wa Lọ

Jèhófà Tóbi Ju Ọkàn-àyà Wa Lọ

Jèhófà Tóbi Ju Ọkàn-àyà Wa Lọ

“ONÍSÁÀMÙ náà kọ̀wé pé: “Jèhófà ní ìdùnnú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.” Ní ti tòótọ́, inú Ẹlẹ́dàá máa ń dùn nígbà tó bá ń wo ẹnì kọ̀ọ̀kan lára àwọn ènìyàn tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń tiraka láti di àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ mú gírígírí. Ọlọ́run ń bù kún àwọn adúróṣinṣin, ó ń fún wọn níṣìírí, ó sì ń tù wọ́n nínú láwọn àkókò tí ìbànújẹ́ bá dorí wọn kodò. Ó mọ̀ pé aláìpé ni àwọn ìránṣẹ́ òun, nítorí náà kì í béèrè ohun tó bá ju agbára wọn lọ.—Sáàmù 147:11.

Ó lè rọrùn fún wa láti gbà gbọ́ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ tó ga fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní gbogbo gbòò. Àmọ́ ṣá, ó dà bí ẹni pé àṣìṣe tí àwọn kan ṣe ti gbà wọ́n lọ́kàn débi tí wọ́n fi gbà pé Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́ àwọn láé. Wọ́n lè parí èrò sí pé, “pẹ̀lú gbogbo àìpé mi yìí, Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́ mi láé.” Dájúdájú, gbogbo wa la máa ń lérò òdì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, ó dà bí ẹni pé gbogbo ìgbà làwọn kan máa ń lérò pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan.

Ìdoríkodò

Nínú Bíbélì, àwọn bíi mélòó kan lára àwọn olóòótọ́ ló ní èrò tó mú kí ìbànújẹ́ dorí wọn kodò. Jóòbù kórìíra ẹ̀mí rẹ̀, ó sì rò pé Ọlọ́run ti pa òun tì. Hánà, tó wá di ìyá Sámúẹ́lì, fìgbà kan banú jẹ́ gan-an nítorí àìbímọ rẹ̀, ó sì sunkún kíkorò. Dáfídì “tẹrí ba mọ́lẹ̀ ní ìwọ̀n tí ó dé góńgó,” bẹ́ẹ̀ náà ni Ẹpafíródítù soríkọ́ nítorí ìròyìn nípa àìlera rẹ̀ tó kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn ará.—Sáàmù 38:6; 1 Sámúẹ́lì 1:7, 10; Jóòbù 29:2, 4, 5; Fílípì 2:25, 26.

Àwọn Kristẹni òde òní wá ńkọ́? Ó lè jẹ́ àìsàn, ọjọ́ ogbó, tàbí àwọn ìṣòro ara ẹni mìíràn ló ká àwọn kan lọ́wọ́ kò, tí wọn ò fi lè ṣe tó bí wọ́n ṣe fẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́. Èyí lè sún wọn láti parí èrò sí pé àwọn ti já Jèhófà àti àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn kulẹ̀. Àwọn kan lè máa dá ara wọn lẹ́bi ṣáá nítorí àwọn àṣìṣe tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn, láìmọ̀ bóyá Jèhófà ti dárí jì wọ́n. Ó sì lè jẹ́ pé ìdílé oníwàhálà tí àwọn mìíràn dàgbà sí ló jẹ́ kí wọ́n gbà pé àwọn ò tiẹ̀ yẹ lẹ́ni táa ń fìfẹ́ hàn sí rárá. Báwo lèyí ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?

Àwọn kan dàgbà láwọn ìdílé tó jẹ́ pé ẹ̀mí tó gbilẹ̀ jù níbẹ̀ kì í ṣe ti ìfẹ́ bí kò ṣe ti ìmọtara-ẹni-nìkan, ti ìpẹ̀gàn, àti ti ìbẹ̀rù. Wọ́n lè máà rí i rí kí bàbá wọn tiẹ̀ fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn dénú, kó máa wá ọ̀nà láti yìn wọ́n àti láti fún wọn níṣìírí, kó máa gbójú fo àwọn àṣìṣe tí ò tó nǹkan dá, kó sì múra tán láti dárí àwọn àṣìṣe wíwúwo pàápàá jì wọ́n, kó sì jẹ́ bàbá tí ọkàn gbogbo ìdílé rẹ̀ balẹ̀ nítorí bó ṣe ń yá mọ́ wọn. Níwọ̀n bí wọn ò ti fìgbà kan rí ní baba kan tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ lórí ilẹ̀ ayé, ó lè wá ṣòro púpọ̀ fún wọn láti lóye ohun tó túmọ̀ sí láti ní Baba onífẹ̀ẹ́ lọ́run.

Fún àpẹẹrẹ, Fritz kọ̀wé pé: “Ìwà àìnífẹ̀ẹ́ tí baba mi máa ń hù nípa tó lágbára lórí mi nígbà tí mo wà lọ́mọdé àti ìgbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́. a Kò fún mi ní ìṣírí kankan rí, èmi náà ò sì sún mọ́ ọn. Àní, ṣàṣà nígbà tẹ́rù rẹ̀ kì í bà mí.” Nítorí ìdí èyí, Fritz, tó ti lé lẹ́ni àádọ́ta ọdún báyìí, ṣì ń lérò pé òun ò tóótun. Margarette náà ṣàlàyé pé: “Àwọn òbí mi kì í túra ká, wọn ò sì nífẹ̀ẹ́. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ṣòro fún mi láti mọ irú bàbá táa lè pè ní bàbá onífẹ̀ẹ́.”

Ohun yòówù kí ìṣòro náà jẹ́, irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ lè túmọ̀ sí pé, nígbà mìíràn, kì í ṣe ìfẹ́ ni ohun náà gan-an tó ń sún wa ṣe iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run bí kò ṣe èrò ẹ̀bi àti ìbẹ̀rù lọ́pọ̀ ìgbà. Bó ti wù ká ṣe nǹkan lọ́nà tó dára jù lọ tó, èrò pé a ò tíì ṣe dáadáa tó la óò máa ní. Ìfẹ́ wa láti wu Jèhófà àti àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa lè mú kí a máa rò pé a ti lo okun wa ré kọjá ààlà. Nípa bẹ́ẹ̀, a lè má lè lé góńgó wa bá, kí a máa dá ara wa lẹ́bi, ká sì wá soríkọ́.

Kí la lè ṣe? Bóyá ṣe ló yẹ ká rán ara wa létí pé elétíi gbáròyé ni Jèhófà. Ẹnì kan tó lóye apá yìí nínú àwọn ànímọ́ Ọlọ́run ni àpọ́sítélì Jòhánù.

“Ọlọ́run Tóbi Ju Ọkàn-Àyà Wa Lọ”

Ní òpin ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, Jòhánù kọ̀wé sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Nípa èyí ni àwa yóò mọ̀ pé a pilẹ̀ṣẹ̀ láti inú òtítọ́, a óò sì fún ọkàn-àyà wa ní ìdánilójú níwájú rẹ̀ ní ti ohun yòówù nínú èyí tí ọkàn-àyà wa ti lè dá wa lẹ́bi, nítorí Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.” Èé ṣe tí Jòhánù fi kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí?—1 Jòhánù 3:19, 20.

Jòhánù mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí ìránṣẹ́ Jèhófà ní èrò ẹ̀bi nínú ọkàn-àyà rẹ̀. Bóyá Jòhánù pàápàá ti ní irú èrò bẹ́ẹ̀ rí. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́kùnrin tó le lẹ́dàá, àwọn ìgbà kan wà tí Jésù Kristi tún èrò Jòhánù ṣe nítorí ọwọ́ tó fi mú àwọn ẹlòmíràn ti le jù. Àní Jésù tiẹ̀ fún Jòhánù àti arákùnrin rẹ̀ Jákọ́bù ní “orúkọ àpèlé náà Bóánágè, èyí tí ó túmọ̀ sí àwọn Ọmọ Ààrá.”—Máàkù 3:17; Lúùkù 9:49-56.

Nígbà tó fi máa di ọgọ́ta ọdún lẹ́yìn náà, Jòhánù ti sinmi agbaja, ó ti di Kristẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà, tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́, tó sì láàánú. Ìgbà tí ó fi máa kọ ìwé rẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó ní ìmísí, tó sì jẹ́ pé nígbà yẹn òun nìkan ló ṣẹ́ kù lára àwọn àpọ́sítélì, ó ti wá mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké ní Jèhófà máa ń kà sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́rùn. Dípò ìyẹn, òun jẹ́ Baba ọlọ́yàyà, onínúure, ọ̀làwọ́, àti aláàánú, tó nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ sí gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń fi òtítọ́ sìn ín. Jòhánù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”—1 Jòhánù 4:8.

Inú Jèhófà Máa Ń Dùn sí Iṣẹ́ Ìsìn Wa Sí I

Ọlọ́run mọ àwọn àìlera tí a jogún àti àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó wa, ó sì máa ń ro èyí mọ́ wa lára. Dáfídì kọ̀wé pé: “Nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.” Jèhófà mọ ipa tí ipò táa gbé dàgbà lè ní lórí irú ènìyàn táa jẹ́. Àní, ó mọ̀ wá dáadáa ju bí a ti mọ ara wa lọ.—Sáàmù 103:14.

Ó mọ̀ pé ọ̀pọ̀ nínú wa ni ì bá fẹ́ láti jẹ́ èèyàn ọ̀tọ̀, àmọ́ kò ṣeé ṣe fún wa láti ṣẹ́pá àwọn àìpé wa. Ipò táa wà ṣeé fi wé ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ẹni tí ó kọ̀wé pé: “Rere tí mo fẹ́ ni èmi kò ṣe, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́ ni èmi fi ń ṣe ìwà hù.” Gbogbo wa pátá ló ń ja irú ìjàkadì yẹn. Láwọn ọ̀nà kan, èyí lè sọ wá di ẹni ti ọkàn-àyà rẹ̀ ń dá lẹ́bi.—Róòmù 7:19.

Máa rántí èyí ní gbogbo ìgbà, pé: Ojú tí Jèhófà fi ń wò wá ló ṣe pàtàkì ju ojú tí a fi ǹ wo ara wa lọ. Nígbàkigbà tó bá rí i pé a ń gbìyànjú láti múnú òun dùn, ṣe ni ó máa ń kún fáyọ̀, kì í ṣe pé ó kàn máa ń gbà á bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀. (Òwe 27:11) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí a ṣe lè kéré gan-an lójú tiwa, báa ṣe múra tán láti ṣe é àti irú ẹ̀mí tí a fi ṣe é máa ń mú inú rẹ̀ dùn. Ó máa ń wò ré kọjá ohun tí a ṣàṣeparí rẹ̀; ó ń fòye mọ ohun tí a fẹ́ ṣe; ó sì tún mọ àwọn ohun tó wù wá àti ìfẹ́ ọkàn wa. Jèhófà lè mọ ọkàn-àyà wa.—Jeremáyà 12:3; 17:10.

Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló jẹ́ onítìjú àti èèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, tí wọ́n máa ń fẹ́ rọra máa lọ ní ìlọ wọn. Fún irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀, wíwàásù ìhìn rere láti ilé dé ilé lè jẹ́ òkè ìṣòro. Síbẹ̀, ìfẹ́ tí wọ́n ní láti sin Ọlọ́run àti láti ran àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́ ń sún àwọn tí wọ́n jẹ́ onítìjú pàápàá láti kọ́ bí wọn ó ṣe tọ àwọn aládùúgbò wọn lọ, tí wọn ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Wọ́n lè máa rò pé ìwọ̀nba díẹ̀ làwọn ń ṣe, irú èrò bẹ́ẹ̀ sì lè sọ wọ́n di ẹni tí kò láyọ̀. Ọkàn-àyà wọn lè máa sọ fún wọn pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba tí wọ́n ń ṣe ò já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́, ó dájú pé inú Jèhófà máa ń dùn sí bí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ṣe ń sapá gidigidi nínú iṣẹ́ ìsìn wọn. Láfikún sí i, wọn ò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú nípa ìgbà tí àwọn irúgbìn òtítọ́ tí wọ́n gbìn yóò hù àti ìgbà tí yóò dàgbà, tí yóò sì mú èso jáde.—Oníwàásù 11:6; Máàkù 12:41-44; 2 Kọ́ríńtì 8:12.

Àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn ń ṣe àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ tàbí kárúgbó ti máa dé sí wọn. Fún irú wọn, lílọ sí ìpàdé déédéé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba lè kún fún ìrora àti ọ̀pọ̀ wàhálà. Gbígbọ́ àsọyé tó dá lórí iṣẹ́ ìwàásù náà lè rán wọn létí ohun tí wọ́n máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ àti ohun tí wọ́n ṣì fẹ́ láti ṣe, àmọ́ tí àìlera ń fa ọwọ́ aago wọn sẹ́yìn. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè máa dá ara wọn lẹ́bi nítorí pé wọn ò lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn náà tó bí wọ́n ṣe fẹ́. Síbẹ̀, ó dájú pé Jèhófà mọyì ìdúróṣinṣin àti ìfaradà wọn. Níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ṣáà ti jẹ́ adúróṣinṣin, òun ò jẹ́ gbàgbé ipa ọ̀nà ìwà títọ́ tí wọ́n tọ̀.—Sáàmù 18:25; 37:28.

“Fún Ọkàn-Àyà Wa ní Ìdánilójú”

Nígbà tí Jòhánù di arúgbó, ó ti ní láti lóye tó pọ̀ nípa inú rere Ọlọ́run. Rántí pé ó kọ̀wé pé: “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.” Síwájú sí i, Jòhánù gbà wá níyànjú láti “fún ọkàn-àyà wa ní ìdánilójú.” Kí ni ọ̀rọ̀ Jòhánù wọ̀nyẹn túmọ̀ sí?

Ní ìbámu pẹ̀lú ìwé atúmọ̀ èdè náà,Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words, ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà táa tú sí “fún ní ìdánilójú” túmọ̀ sí “lílo ìyíniléròpadà, láti borí ẹnì kan tàbí láti mú kí ó gba nǹkan kan, láti yíni lọ́kàn padà.” Ní ọ̀rọ̀ mìíràn, láti fún ọkàn-àyà wa ní ìdánilójú, a ní láti borí ọkàn-àyà wa, kí a mú kí ó gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Lọ́nà wo?

Fritz, táa mẹ́nu kàn ní ìṣáájú, ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ọ̀kan lára ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ohun tó lé lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n báyìí, ó sì ti rí i pé ìdákẹ́kọ̀ọ́ lè fún ọkàn-àyà òun ní ìdánilójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun. Ó sọ pé: “Mo máa ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde wa déédéé. Èyí ń ràn mí lọ́wọ́ láti má máa ronú lórí ohun tó ti kọjá bí kò ṣe pé kí n máa wo àgbàyanu ọjọ́ iwájú ní kedere. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ohun tí mo ti ṣe sẹ́yìn máa ń wá sí mi lọ́kàn, ó sì máa ń jẹ́ kí n lérò pé Ọlọ́run kò lè nífẹ̀ẹ́ mi láé. Àmọ́, ní gbogbo gbòò, mo rí i pé kíkẹ́kọ̀ọ́ déédéé ti fún ọkàn-àyà mi lókun, ó ti fi kún ìgbàgbọ́ mi, ó sì ti ràn mí lọ́wọ́ láti jẹ́ aláyọ̀ àti oníwọ̀ntúnwọ̀nsì.”

Lóòótọ́, Bíbélì kíkà àti ṣíṣe àṣàrò lè máà yí ipò wa padà ní ti gidi. Àmọ́, ó lè yí ojú táa fi ń wo ipò wa padà. Mímú àwọn èrò látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wá sínú ọkàn-àyà wa máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti ronú bí òun ṣe ń ronú. Ní àfikún sí i, ìkẹ́kọ̀ọ́ ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti túbọ̀ lóye inú rere Ọlọ́run. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, a óò wá gbà pé Jèhófà kì í dá wa lẹ́bi nítorí àyíká táa wà nígbà ọmọdé, kì í sì í dá wa lẹ́bi nítorí àwọn àìlera wa. Ó mọ̀ pé àwọn ẹrù tí ń wọni lọ́rùn tí ọ̀pọ̀ lára wa ń gbé—yálà ní ti èrò tàbí èyí tó ṣeé fojú rí—kì í sábà jẹ́ àfọwọ́fà àwa fúnra wa, ó sì máa ń fi tìfẹ́tìfẹ́ ro èyí mọ́ wa lára.

Margarette táa mẹ́nu kan níṣàájú ńkọ́? Bákan náà ni kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ṣàǹfààní ńlá fún un nígbà tó wá mọ Jèhófà. Òun náà, bíi tí Fritz, ní láti tún èrò tó ní nípa baba ṣe. Àdúrà ran Margarette lọ́wọ́ láti ṣàkópọ̀ gbogbo ohun tó kọ́ nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́. Margarette sọ pé: “Lákọ̀ọ́kọ́ ná, mo ka Jèhófà sí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, nítorí pé ohun tí mo mọ̀ nípa àwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ pọ̀ ju ohun tí mo mọ̀ nípa baba tó nífẹ̀ẹ́ lọ. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo kọ́ bí n ó ṣe sọ gbogbo èrò mi, iyèméjì tí mo ní, àwọn àníyàn mi, àti àwọn ìṣòro mi fún Jèhófà. Léraléra ni mo máa ń bá a sọ̀rọ̀ nínú àdúrà, ní àkókò kan náà ni mo sì máa ń to gbogbo ohun tuntun tí mo ń kọ́ nípa rẹ̀ pa pọ̀, bí ìgbà táa bá to òkúta pọ̀ láti mọlé. Nígbà tó yá, èrò mi nípa Jèhófà ti yí padà gan-an débi pé n ò níṣòro mọ́ nísinsìnyí láti kà á sí baba mi onífẹ̀ẹ́.

Bíbọ́ Lọ́wọ́ Gbogbo Hílàhílo

Níwọ̀n ìgbà tí ètò nǹkan búburú ògbólógbòó yìí bá ṣì wà, kò sí ẹnì kan tó lè retí àtibọ́ pátápátá lọ́wọ́ hílàhílo. Fún àwọn Kristẹni kan, èyí túmọ̀ sí pé hílàhílo tàbí àìdára ẹni lójú lè máa bá wọn fínra lóòrèkóòrè, kí ó sì máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn. Àmọ́, a lè ní ìdánilójú náà pé Jèhófà mọ ẹ̀mí rere táa ní àti iṣẹ́ àṣekára tí a ń ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Kò ní gbàgbé ìfẹ́ tí a fi hàn fún orúkọ rẹ̀ láé.—Hébérù 6:10.

Nínú ayé tuntun tó ń bọ̀ lábẹ́ Ìjọba Mèsáyà, gbogbo àwọn olóòótọ́ ènìyàn lè retí láti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹrù wíwúwo tó wà nínú ètò Sátánì. Ìdẹ̀ra ńlá nìyẹn yóò mà jẹ́ o! Ìgbà yẹn la óò túbọ̀ rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn bí Jèhófà ṣe jẹ́ onínúure tó. Títí di ìgbà yẹn, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa mọ̀ dájú pé “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.”—1 Jòhánù 3:20.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ náà padà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 30]

Jèhófà kì í ṣe apàṣẹwàá tí kò lójú àánú ṣùgbọ́n ó jẹ́ Baba ọlọ́yàyà, onínúure, àti aláàánú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń ràn wá lọ́wọ́ láti ronú bí òun ṣe ń ronú