Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

lbo Lo Ti Lè Rí Ìbàlẹ̀ Ọkàn?

lbo Lo Ti Lè Rí Ìbàlẹ̀ Ọkàn?

lbo Lo Ti Lè Rí Ìbàlẹ̀ Ọkàn?

Ọ̀pọ̀ nǹkan ni àkókò tiwa yìí fi yàtọ̀ sí àkókò Thoreau tí a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú. Ìyàtọ̀ pàtàkì kan ni pé ìmọ̀ràn lórí bí a ṣe lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn wà káàkiri lóde òní. Àwọn afìṣemọ̀rònú wà, a tún láwọn tó ń kọ àwọn ìwé báyìí-làá-ṣe-é, kódà àwọn oníwèé ìròyìn pàápàá, ń sọ àwọn èrò wọn jáde. Àwọn ìmọ̀ràn wọn lè ṣèrànwọ́ fúngbà díẹ̀; àmọ́ ká tó lè rí ojútùú pípẹ́ títí, ó pọndandan láti ṣe ohun kan tó jinlẹ̀ ju ìyẹn lọ. Ohun tí àwọn táa mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú ṣe nìyẹn.

IBI ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti tọ́ Antônio, Marcos, Gerson, Vania, àti Marcelo dàgbà, ìṣòro wọ́n sì yàtọ̀ síra. Àmọ́, ó kéré tán, ohun mẹ́ta lọ̀ràn wọ́n fi bára mu. Èkíní, ìgbà kan wà tí wọn ‘kò ní ìrètí kankan, tí wọ́n sì wà ní ayé láìní Ọlọ́run.’ (Éfésù 2:12) Èkejì, wọ́n ń wá ìbàlẹ̀ ọkàn. Ìkẹta ni pé, gbogbo wọn ló rí ìbàlẹ̀ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n gbà kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa bá wọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú ni wọ́n ń rí i pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn. Ní tòótọ́, Ọlọ́run “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa,” gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ fún àwọn ará Áténì ìgbà ayé rẹ̀. (Ìṣe 17:27 ) Fífi tọkàntọkàn gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí jẹ́ kókó pàtàkì kan táa fi lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn.

Èé Ṣe Tí Kò Fi Fi Bẹ́ẹ̀ Sí Àlàáfíà?

Bíbélì sọ ohun méjì pàtàkì tó fà á tí kò fi sí àlàáfíà ní ayé—ì báà jẹ́ ìbàlẹ̀ ọkàn tàbí àlàáfíà láàárín àwọn ènìyàn. Ó ṣàlàyé ìkínní nínú ìwé Jeremáyà 10:23, tó sọ pé: “Ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” Èèyàn ò ní ọgbọ́n tàbí òye tó fi lè ṣàkóso ara rẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́, ìrànlọ́wọ́ kan ṣoṣo tó jẹ́ ojúlówó ń wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Kò sí bí àwọn èèyàn tí kò wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run ṣe lè ní àlàáfíà pípẹ́ títí. Ìdí kejì tí kò fi sí àlàáfíà ni èyí tí a rí nínú ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Jòhánù pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Láìsí ìdarí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, gbogbo ìsapá ènìyàn láti ní àlàáfíà yóò máa kùnà ṣáá ni nítorí ìgbòkègbodò Sátánì, “ẹni burúkú náà,” tí a kò lè fojú rí, àmọ́ tí ó wà—tó tún jẹ́ alágbára gan-an.

Nítorí àwọn ìdí méjì wọ̀nyí—pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn ni wọn kì í wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run àti pé ńṣe ni Sátánì ń lọ tó ń bọ̀ nínú ayé—ìran ènìyàn lódindi ti wá wà nínú ìpọ́njú ńláǹlà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe rẹ̀ dáadáa pé: “Gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.” (Róòmù 8:22) Ta ló lè ta ko ohun tó sọ yìí? Ní àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ àtàwọn tí kò lọ́rọ̀ pàápàá, àwọn ìṣòro ìdílé, ìwà ọ̀daràn, ojúsàájú, ìforígbárí, ọrọ̀ ajé tí kò dúró lójú kan, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ìninilára, àìsàn, àti ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn, ni kò jẹ́ kí àwọn ènìyàn ní ìbàlẹ̀ ọkàn.

Ibi Tí A Ti Lè Rí Ìbàlẹ̀ Ọkàn

Nígbà tí Antônio, Marcos, Gerson, Vania, àti Marcelo kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n kọ́ àwọn nǹkan tó yí ìgbésí ayé wọn padà. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pé ipò nǹkan yóò yàtọ̀ lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ kan. Èyí kì í ṣe àlá kan ti kò lè ṣẹ pé gbogbo nǹkan yóò dára níkẹyìn. Òótọ́ pọ́ńbélé tó fúnni ní ìdánilójú pé Ọlọ́run ní ète kan fun aráyé ni, kódà a lè jàǹfààní nínú ète yẹn báyìí táa bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Wọ́n fi àwọn ohun tí wọ́n kọ́ nínú Bíbélì sílò, nǹkan sì ṣẹnuure fún wọn. Wọ́n ní ayọ̀ àti àlàáfíà tó ju èyí tí wọ́n fọkàn sí pàápàá lọ.

Antônio ò bá wọ́n lọ́wọ́ sí ìwọ́de àti gbọ́nmisi-omi-ò-to àwọn òṣìṣẹ́ mọ́. Ó mọ̀ pé bí àwọn nǹkan tiẹ̀ tipa bẹ́ẹ̀ yí padà, fúngbà díẹ̀ ni, ó sì níwọ̀n. Aṣáájú àwọn òṣìṣẹ́ tẹ́lẹ̀ yìí ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Èyí ni Ìjọba tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn máa ń gbàdúrà fún nígbà tí wọ́n bá ń ka Àdúrà Olúwa (tàbí, Baba Wa Tí Ń Bẹ Lọ́run) tí wọ́n sì ń sọ fún Ọlọ́run pé: “Kí ìjọba rẹ dé.” (Mátíù 6:10a) Antônio kẹ́kọ̀ọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ojúlówó ìṣàkóso ti ọ̀run, èyí tí yóò mú ojúlówó àlàáfíà wa fún aráyé.

Marcos kẹ́kọ̀ọ́ bí a ṣe ń fi ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì nípa ìgbéyàwó sílò. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹni tó ti fìgbà kan jẹ́ òṣèlú yìí ti wá di ẹni tó ń fi ayọ̀ gbé ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú aya rẹ̀ báyìí. Òun náà ń retí àkókò náà, tí yóò dé láìpẹ́, nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run yóò fi ìjọba tó dára jù rọ́pò ètò ayé yìí tó jẹ́ oníwọra àti onímọtara-ẹni-nìkan. Ó ti túbọ̀ lóye àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Àdúrà Olúwa yẹn dáadáa, tó kà pé: “Kí ìfẹ́ rẹ di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé bí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run.” (Mátíù 6:10b, New International Version) Nígbà tí a bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé, àwọn èèyàn yóò gbádùn ìgbésí ayé tí wọn kò rí irú rẹ̀ rí.

Gerson náà ńkọ́? Ó ti kúrò ní alárìnkiri, kò sì jalè mọ́. Ìgbésí ayé ọmọ asùnta tẹ́lẹ̀ yìí ti wá nítumọ̀ báyìí nítorí pé ó ti wá ń lo okun tó ní láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn kí wọ́n lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn ìrírí wọ̀nyí fi hàn, kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti fífi ohun tó sọ sílò lè yí ìgbésí ayé ẹni padà sí rere.

Ìbàlẹ̀ Ọkàn Nínú Ayé Wàhálà

Ẹni tó jẹ́ òpómúléró nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ ni Jésù Kristi, táwọn èèyàn bá sì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ohun púpọ̀ ni wọ́n máa ń kọ́ nípa rẹ̀. Ní òru ọjọ́ tí wọ́n bí i, àwọn áńgẹ́lì kọ orin ìyìn sí Ọlọ́run pé: “Ògo fún Ọlọ́run ní àwọn ibi gíga lókè, àti lórí ilẹ̀ ayé àlàáfíà láàárín àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà.” (Lúùkù 2:14) Nígbà tí Jésù dàgbà, bó ṣe máa mú kí ìgbésí ayé àwọn èèyàn sunwọ̀n sí i ló jẹ ẹ́ lógún. Ó lóye ìmọ̀lára wọn, ó sì fi ìyọ́nú àrà ọ̀tọ̀ hàn sí àwọn ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti àwọn aláìsàn. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn áńgẹ́lì wọ̀nyẹn sì sọ, ó mú ìbàlẹ̀ ọkàn wá fún àwọn ọlọ́kàn tútù títí dé àyè kan. Ní ìparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Mo fi àlàáfíà sílẹ̀ fún yín, mo fi àlàáfíà mi fún yín. Èmi kò fi í fún yín lọ́nà tí ayé gbà ń fi í fúnni. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn-àyà yín dààmú tàbí kí ó kó sókè nítorí ìbẹ̀rù.”—Jòhánù 14:27.

Jésù kì í kàn-án ṣe akiriṣoore lásán. Ó fi ara rẹ̀ wé olùṣọ́ àgùntàn, ó sì fi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ọlọ́kàn tútù wé àgùntàn nígbà tó sọ pé: “Èmi ti wá kí wọ́n lè ní ìyè, kí wọ́n sì ní in lọ́pọ̀ yanturu. Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà; olùṣọ́ àgùntàn àtàtà fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.” (Jòhánù 10:10, 11) Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú lóde òní, tó jẹ́ pé ti ara wọn ni wọ́n máa ń kọ́kọ́ gbájú mọ́, Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn rẹ̀.

Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ohun tí Jésù ṣe? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí bí ẹní mowó pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Lílo ìgbàgbọ́ nínú Jésù béèrè pé kí a kọ́kọ́ ní ìmọ̀ nípa rẹ̀ àti nípa Jèhófà, Baba rẹ̀. Ìmọ̀ nípa Ọlọ́run àti nípa Jésù Kristi lè mú kí a ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, èyí tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìbàlẹ̀ ọkàn.

Jésù sọ pé: “Àwọn àgùntàn mi ń fetí sí ohùn mi, mo sì mọ̀ wọ́n, wọ́n sì ń tẹ̀ lé mi. Èmi sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun, a kì yóò sì pa wọ́n run lọ́nàkọnà láé, kò sì sí ẹnì kankan tí yóò já wọn gbà kúrò ní ọwọ́ mi.” (Jòhánù 10:27, 28) Ọ̀rọ̀ ìtùnú amárayágágá mà lèyí o! Lóòótọ́, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá ọdún sẹ́yìn tí Jésù ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àmọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ṣì ń nípa lórí àwọn ènìyàn lónìí bó ṣe ní in nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Má ṣe gbàgbé láé pé Jésù Kristi ṣì wà láàyè, ó sì ń ṣiṣẹ́, ó ń ṣàkóso nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run. Gan–an gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ó ṣì ń ṣàníyàn nípa àwọn ọlọ́kàn tútù tí wọ́n ń wá ìbàlẹ̀ ọkàn. Síwájú sí i, òun ṣì ni Olùṣọ́ àwọn àgùntàn rẹ̀. Bí a bá tẹ̀ lé e, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìbàlẹ̀ ọkàn, títí kan ìrètí tí ń fọkàn ẹni balẹ̀, ìyẹn ni rírí ọjọ́ ọ̀la tó ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàáfíà—tí yóò túmọ̀ sí àìsí ìwà ipá, ogun, àti ìwà ọ̀daràn mọ́.

Ojúlówó àǹfààní ló máa ń wá látinú mímọ̀ àti gbígbàgbọ́ pé Jèhófà yóò tipasẹ̀ Jésù ràn wá lọ́wọ́. Ṣé ẹ rántí Vania, ìyẹn ọ̀dọ́mọbìnrin tí ẹrù wíwúwo já lé léjìká, tó sì wá rò pé Ọlọ́run ti gbàgbé òun? Nísinsìnyí, Vania ti wá mọ̀ pé Ọlọ́run kò pa òun tì. Ó sọ pé: “Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi, tó ní àwọn ànímọ́ tó fani mọ́ra. Ìfẹ́ ló sún un láti rán Ọmọ rẹ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé kí ó lè fún wa ní ìyè. Ó ṣe pàtàkì gan-an láti mọ èyí.”

Marcelo ṣàlàyé pé ìbátan gidi ni òun ní pẹ̀lú Ọlọ́run. Ọmọ jayéjayé nígbà kan rí yìí sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́ kì í sábà mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe, ara wọn ni wọ́n sì máa ń pa lára níkẹyìn. Àwọn mìíràn máa ń di ajoògùnyó, bíi tèmi. Mo nírètí pé púpọ̀ sí i ni a ó bù kún, bí a ṣe bù kún mi, nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀.”

Nípa fífarabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Vania àti Marcelo mú ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run dàgbà, wọ́n sì tún ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú bó ṣe múra tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro wọn. Bí a bá ṣe ohun tí wọ́n ṣe—ìyẹn ni pé ká kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká sì fi ohun tó sọ sílò—a óò rí ìbàlẹ̀ ọkàn ńláǹlà, bíi tiwọn. Ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yóò wúlò fún wa gan-an ni, èyí tó sọ pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.”—Fílípì 4:6, 7.

Wíwá Ojúlówó Àlàáfíà Lónìí

Jésù Kristi ń ṣamọ̀nà àwọn tí ebi òtítọ́ ń pa sí ipa ọ̀nà tí ó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé. Bó ṣe ń ṣamọ̀nà wọn síbi ìjọsìn mímọ́ gaara ti Ọlọ́run ni wọ́n ń ní àlàáfíà tó bá èyí táa ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Bíbélì mu pé: “Àwọn ènìyàn mi yóò . . máa gbé ní ibi gbígbé tí ó kún fún àlàáfíà àti ní àwọn ibùgbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbọ́kànlé àti ní àwọn ibi ìsinmi tí kò ní ìyọlẹ́nu.” (Aísáyà 32:18) Bẹ́ẹ̀ ìwọ̀nba díẹ̀ nìyẹn jẹ́ lára àlàáfíà tí wọn óò gbádùn lọ́jọ́ iwájú. A kà á pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà. Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:11, 29.

Nítorí náà, ǹjẹ́ a lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ìyẹn nìkan kọ́ o, a tún lè ní ìdánilójú pé ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà, Ọlọ́run yóò fi àlàáfíà tí a kò rí irú rẹ̀ rí jíǹkí ìran ènìyàn onígbọràn. Nítorí náà, èé ṣe tí o ò fi béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nínú àdúrà pé kó fún ọ ní àlàáfíà rẹ̀? Bí o bá ní àwọn ìṣòro tó ń dà ọ́ láàmú, gbàdúrà bíi tí Dáfídì Ọba pé: “Wàhálà ọkàn-àyà mi ti di púpọ̀; mú mi jáde kúrò nínú másùnmáwo tí ó bá mi. Wo ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́ àti ìdààmú mi, kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.” (Sáàmù 25:17, 18) Jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé Ọlọ́run máa ń gbọ́ irú àdúrà bẹ́ẹ̀. Ó ń na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì ń pèsè àlàáfíà fún gbogbo àwọn tó ń fi ọkàn-àyà tòótọ́ wá a. Tìfẹ́tìfẹ́ la fi mú un dá wa lójú pé: “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é ní òótọ́. Ìfẹ́-ọkàn àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ni òun yóò mú ṣẹ, igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ ni òun yóò sì gbọ́, yóò sì gbà wọ́n là.”—Sáàmù 145:18, 19.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

Ènìyàn kò ní ọgbọ́n tàbí òye tó fi lè ṣàkóso ara rẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́, ìrànlọ́wọ́ kan ṣoṣo tó jẹ́ ojúlówó sì ń wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

Ìmọ̀ nípa Ọlọ́run àti Jésù Kristi lè mú kí a ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, èyí tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìbàlẹ̀ ọkàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Títẹ̀lé ìmọ̀ràn Bíbélì ń ṣàlékún ìgbésí ayé ìdílé alálàáfíà