Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Yóò Ṣe

Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Yóò Ṣe

Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Yóò Ṣe

“Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—MÁTÍÙ 6:10.

1. Kí ni dídé Ìjọba Ọlọ́run yóò túmọ̀ sí?

 NÍGBÀ tí Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà fún Ìjọba Ọlọ́run, ó mọ̀ pé dídé rẹ̀ yóò fòpin sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún táwọn èèyàn ti fi ṣàkóso láìsí pé Ọlọ́run dá sí wọn. Láàárín gbogbo àkókò yẹn, ìfẹ́ Ọlọ́run kò tíì di ṣíṣe kárí gbogbo ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 147:19, 20) Àmọ́ lẹ́yìn fífi ìdí Ìjọba náà múlẹ̀ ní ọ̀run, ìfẹ́ Ọlọ́run yóò wá di ṣíṣe níbi gbogbo. Àkókò ìyípadà ẹlẹ́rù jẹ̀jẹ̀ látorí ìṣàkóso ènìyàn bọ́ sórí ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run ti ọ̀run ti sún mọ́lé gan-an.

2. Kí ni yóò sàmì sí ìyípadà látinú ìṣàkóso ènìyàn bọ́ sínú ìṣàkóso Ìjọba náà?

2 Ohun tí yóò sàmì sí ìyípadà yìí ni àkókò tí Jésù pè ní “ìpọ́njú ńlá . . . , irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” (Mátíù 24:21) Bíbélì kò sọ bí àkókò yẹn ti máa pẹ́ tó, àmọ́ àwọn àjálù ibi tó máa ṣẹlẹ̀ láàárín rẹ̀ yóò burú ju ohunkóhun tí ayé tíì rí rí. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá náà, ohun kan yóò ṣẹlẹ̀ tí yóò fa ìdààmú ọkàn fún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ènìyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé: ìyẹn ni ìparun gbogbo ìsìn èké. Ìyẹn ò lè fa ìdààmú ọkàn fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà o, nítorí ó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń retí kí èyí ṣẹlẹ̀. (Ìṣípayá 17:1, 15-17; 18:1-24) Ìpọ́njú ńlá náà yóò parí sí Amágẹ́dọ́nì nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run yóò fọ́ gbogbo ètò Sátánì túútúú.—Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 16:14, 16.

3. Báwo ni Jeremáyà ṣe ṣàpèjúwe ìpín àwọn aláìgbọràn?

3 Kí ni èyí yóò túmọ̀ sí fún àwọn ènìyàn “tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere” nípa Ìjọba rẹ̀ ti ọ̀run ní ọwọ́ Kristi? (2 Tẹsalóníkà 1:6-9) Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sọ fún wa pé: “Wò ó! Ìyọnu àjálù kan ń jáde lọ láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè, ìjì líle sì ni a ó ru dìde láti apá jíjìnnàréré jù lọ ní ilẹ̀ ayé. Àwọn tí Jèhófà pa yóò sì wà dájúdájú ní ọjọ́ yẹn láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ ayé títí lọ dé ìpẹ̀kun kejì ilẹ̀ ayé. A kì yóò pohùn réré ẹkún nítorí wọn, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò kó wọn jọpọ̀ tàbí kí a sin wọ́n. Bí ajílẹ̀ lórí ilẹ̀ ni wọn yóò dà.”—Jeremáyà 25:32, 33.

Òpin Ìwà Ibi

4. Èé ṣe tí Jèhófà kò fi jẹ̀bi rárá tó bá mú ètò búburú yìí wá sópin?

4 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni Jèhófà Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi, ó ti fàyè gbà á fún àkókò tí ó gùn tó fún àwọn olódodo láti rí i pé jàǹbá ńlá ni ìṣàkóso ènìyàn jẹ́. Fún àpẹẹrẹ, ní ọ̀rúndún ogún yìí nìkan ṣoṣo, ó lé ní àádọ́jọ mílíọ̀nù ènìyàn tó bógun lọ, tí wọ́n kú nígbà ìyípadà tegbòtigaga, àti lákòókò àwọn rògbòdìyàn mìíràn, gẹ́gẹ́ bí ìsọfúnni kan ti sọ. Ìgbà tí àìtóótun ènìyàn hàn gbangba jù lọ ni àkókò tí Ogun Àgbáyé Kejì ń lọ lọ́wọ́, nígbà tí wọ́n pa àwọn bí àádọ́ta mílíọ̀nù ènìyàn, tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn sì kú ikú oró nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Násì. Bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ gẹ́ẹ́ ló rí, ní àkókò tiwa, ‘àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà ti tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.’ (2 Tímótì 3:1-5, 13) Lóde òní, ìwà pálapàla, ìwà ọ̀daràn, ìwà ipá, ìwà ìbàjẹ́, àti títẹ́ńbẹ́lú ìlànà Ọlọ́run ti di ohun tó wà káàkiri. Nítorí náà, Jèhófà kò jẹ̀bi rárá tó bá mú ètò búburú yìí wá sópin.

5, 6. Ṣàpèjúwe ìwà ibi tó wà ní Kénáánì ìgbàanì.

5 Bí ipò nǹkan ṣe rí báyìí dà bíi ti Kénáánì ní nǹkan bí egbèjìdínlógún ó dín ọgọ́rùn-ún [3,500] ọdún sẹ́yìn. Bíbélì sọ pé: “Ohun gbogbo tí ó jẹ́ ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà tí ó sì kórìíra ní ti gidi ni wọ́n ti ṣe sí àwọn ọlọ́run wọn, pé àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn pàápàá ni wọ́n ń sun nínú iná déédéé sí àwọn ọlọ́run wọn.” (Diutarónómì 12:31) Jèhófà sọ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé “Ní tìtorí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi lé wọn kúrò níwájú rẹ.” (Diutarónómì 9:5) Òpìtàn Bíbélì nì, Henry H. Halley sọ pé: “Ìjọsìn Báálì, Áṣítórétì, àti àwọn òrìṣà àwọn ará Kénáánì mìíràn, ní àwọn ààtò bòńkẹ́lẹ́ aláṣerégèé jù lọ nínú; àwọn tẹ́ńpìlì wọn jẹ́ ojúkò ìwà abèṣe.”

6 Halley fi bí ìwà ibi wọ́n ṣe burú lékenkà tó hàn, nítorí pé ní ọ̀kan lára irú àwọn àgbègbè bẹ́ẹ̀, àwọn awalẹ̀pìtàn “rí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn àgbá tó ní egungun àwọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n ti fi rúbọ sí Báálì nínú.” Ó sọ pé: “Gbogbo àgbègbè náà ló jẹ́ sàréè fún àwọn ọmọ àṣẹ̀ṣẹ̀bí. . . . Àwọn ará Kénáánì jọ́sìn, nípa fífi ìwà pálapàla kẹ́ra, gẹ́gẹ́ bí ààtò ẹ̀sìn, níṣojú àwọn òrìṣà wọn; lẹ́yìn náà nípa pípa àwọn àkọ́bí ọmọ wọn, gẹ́gẹ́ bí ohun ìrúbọ sí àwọn òrìṣà kan náà wọ̀nyí. Ó dà bíi pé dé ìwọ̀n gíga, ilẹ̀ Kénáánì dà bíi Sódómù àti Gòmórà káàkiri orílẹ̀-èdè náà. . . . Ǹjẹ́ ó tọ́ kí ilẹ̀ ọ̀làjú oníwà ìbàjẹ́ tó gogò àti ìwà òkú òǹrorò bẹ́ẹ̀ máa bá a nìṣó? . . . Àwọn awalẹ̀pìtàn tí wọ́n walẹ̀ níbi òkìtì àlàpà ìlú àwọn ará Kénáánì ṣe kàyéfì nípa ìdí tí Ọlọ́run kò fi tètè pa wọ́n run ṣáájú àkókò tí ó pa wọ́n run.”

Jíjogún Ilẹ̀ Ayé

7, 8. Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe fọ ilẹ̀ ayé mọ́?

7 Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe fọ Kénáánì mọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe fọ gbogbo ilẹ̀ ayé mọ́ láìpẹ́, tí yóò sì fi fún àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an.” (Òwe 2:21, 22) Onísáàmù sì sọ pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:10, 11) A óò mú Sátánì pẹ̀lú kúrò, “kí ó má bàa ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi dópin.” (Ìṣípayá 20:1-3) Dájúdájú, “ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17.

8 Nígbà tí Jésù ń ṣàkópọ̀ ìrètí kíkọyọyọ tó wà fún àwọn tí yóò wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Sáàmù orí kẹtàdínlógójì, ẹsẹ ìkọkàndínlọ́gbọ̀n ló ń tọ́ka sí, èyí tó sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” Jésù mọ̀ pé ète Jèhófà ni pé kí àwọn olódodo gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé títí láé. Jèhófà sọ pé: “Èmi ni mo ṣe ilẹ̀ ayé, aráyé àti àwọn ẹranko tí ó wà lórí ilẹ̀ nípasẹ̀ agbára ńlá mi . . . , mo sì ti fi fún ẹni tí ó tọ́ ní ojú mi.”—Jeremáyà 27:5.

Àgbàyanu Ayé Tuntun

9. Irú ayé wo ni Ìjọba Ọlọ́run yóò mú wá?

9 Lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì, Ìjọba Ọlọ́run yóò mú àgbàyanu “ilẹ̀ ayé tuntun” wá, nínú èyí tí “òdodo yóò . . . máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Ìtura ńláǹlà mà lèyí o fún àwọn tó bá la Amágẹ́dọ́nì já láti rí i pé ètò àwọn nǹkan tí ń nini lára yìí ti di èyí tí a mú kúrò! Ẹ ò rí i pé inú wọn á dùn jọjọ láti wà nínú ayé tuntun òdodo lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba ọ̀run, pẹ̀lú àgbàyanu ìbùkún àti ìyè àìnípẹ̀kun níwájú wọn!—Ìṣípayá 7:9-17.

10. Kí ni àwọn nǹkan búburú tí kò ní sí mọ́ lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba náà?

10 Kò ní sí pé ogun, ìwà ipá, ebi, tàbí àwọn ẹranko apanijẹ pàápàá tún ń halẹ̀ mọ́ni mọ́. “Dájúdájú, èmi yóò bá [àwọn ènìyàn mi] dá májẹ̀mú àlàáfíà, èmi yóò sì mú kí aṣeniléṣe ẹranko ẹhànnà kásẹ̀ nílẹ̀ ní ilẹ̀ náà . . . Igi pápá yóò sì mú èso rẹ̀ wá, ilẹ̀ náà yóò sì mú èso rẹ̀ wá, wọn yóò sì wà lórí ilẹ̀ wọn ní ààbò ní ti tòótọ́.” “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Wọn kì yóò gbé idà sókè, orílẹ̀-èdè lòdì sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́. Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.”—Ìsíkíẹ́lì 34:25-28; Míkà 4:3, 4.

11. Èé ṣe tí ọkàn wa fi lè balẹ̀ pé àwọn àìlera yóò dópin?

11 A óò mú àìsàn, ìbànújẹ́ àti ikú pàápàá kúrò. “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’ Àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ àwọn tí a ti dárí ìṣìnà wọn jì wọ́n.” (Aísáyà 33:24) “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ. . . . ‘Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.’” (Ìṣípayá 21:4, 5) Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi hàn pé òun lágbára láti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyẹn nípasẹ̀ agbára tí Ọlọ́run fún òun. Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn ẹ̀mí mímọ́, Jésù lọ jákèjádò ilẹ̀ náà tó ń mú arọ lára dá tó sì ń wo àwọn aláìsàn sàn.—Mátíù 15:30, 31.

12. Ìrètí wo ló wà fún àwọn òkú?

12 Jésù tiẹ̀ ṣe ohun tó ju ìyẹn lọ pàápàá. Ó jí òkú dìde. Kí ni àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe? Nígbà tó jí ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá dìde, àwọn òbí rẹ̀ “kò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe, nítorí tí ayọ̀ náà pọ̀ jọjọ.” (Máàkù 5:42) Àpẹẹrẹ nǹkan mìíràn tí Jésù máa ṣe jákèjádò ayé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba náà nìyí, nítorí pé nígbà náà “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Ẹ wo bí ayọ̀ náà yóò ti pọ̀ jọjọ tó nígbà tí àwọn òkú bá ń padà wá sí ìyè ní ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ tí wọ́n sì wá ń dara pọ̀ mọ́ àwọn olólùfẹ́ wọn! Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ńláǹlà yóò wà lábẹ́ àbójútó Ìjọba náà ki “ilẹ̀ ayé” lè “kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—Aísáyà 11:9.

A Dá Ipò Ọba Aláṣẹ Jèhófà Láre

13. Báwo ni ẹ̀tọ́ tí ìṣàkóso Ọlọ́run ní ṣe máa hàn kedere?

13 Ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso Ìjọba náà, a óò ti mú aráyé padà bọ̀ sí ìjẹ́pípé ní ti èrò inú àti ti ara. Ilẹ̀ ayé yóò jẹ́ ọgbà Édẹ́nì kan kárí ayé, ìyẹn Párádísè. Àlàáfíà, ayọ̀, ààbò, àti àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tó nífẹ̀ẹ́ yóò ti wà nígbà náà. A ò tíì rí ohun tó jọ èyí rí nínú ìtàn ìran ènìyàn ṣáájú ìṣàkóso Ìjọba náà. Ẹ ò rí i pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tó kọjá tí àwọn ènìyàn fi ṣàkóso lọ́nà tí ń máyé súni kò dára rárá ní ìfiwéra pẹ̀lú ìṣàkóso alárinrin lábẹ́ Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run fún ẹgbẹ̀rún ọdún! Yóò ti wá hàn kedere ní gbogbo ọ̀nà pé ìṣàkóso Ọlọ́run nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ ni èyí tó dára jù lọ. A óò ti dá ẹ̀tọ́ Ọlọ́run láti ṣàkóso, ìyẹn ipò ọba-aláṣẹ rẹ̀, láre pátápátá.

14. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọlọ̀tẹ̀ nígbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún náà bá parí?

14 Ní ìparí ẹgbẹ̀rún ọdún náà, Jèhófà yóò fàyè gba àwọn ẹ̀dá ènìyàn pípé láti lo òmìnira wọn ní yíyan ẹni tó wù wọ́n láti sìn. Bíbélì fi hàn pé, “A óò tú Sátánì sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n rẹ̀.” Yóò tún gbìyànjú láti ṣi àwọn èèyàn lọ́nà lẹ́ẹ̀kan sí i, tí àwọn kan lára wọn yóò yàn láti gba òmìnira kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Kí ‘wàhálà má bàa dìde nígbà kejì,’ Jèhófà yóò pa Sátánì, àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, àti gbogbo àwọn tó bá ṣọ̀tẹ̀ sí ipò ọba aláṣẹ Jèhófà rẹ́ ráúráú. Kò sẹ́ni tó máa ṣàròyé nígbà yẹn pé àyè ni ò tó fún ẹnikẹ́ni tó bá pa run títí láé tàbí pé àìpé ló fa ipa ọ̀nà búburú tí wọ́n yàn. Rárá o, ńṣe ni wọn yóò dà bí Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ ẹni pípé, tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ yàn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ìṣàkóso òdodo Jèhófà.—Ìṣípayá 20:7-10; Náhúmù 1:9.

15. Irú àjọṣe wo ní àwọn adúróṣinṣin yóò ní pẹ̀lú Jèhófà?

15 Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ó ṣeé ṣe kí àwọn tó pọ̀ jù lọ yàn láti gbé ipò ọba aláṣẹ Jèhófà lárugẹ. Nígbà táa bá ti pa gbogbo ọlọ̀tẹ̀ rún ráúráú, àwọn olódodo yóò dúró níwájú Jèhófà, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yege ìdánwò ìkẹyìn tí a fí dán ìdúróṣinṣin wọn wò. Jèhófà yóò wá tẹ́wọ́ gba àwọn adúróṣinṣin wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọkùnrin àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀. Wọn yóò wá padà bẹ̀rẹ̀ irú àjọṣe tí Ádámù àti Éfà ní pẹ̀lú Ọlọ́run kó tó di pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, Róòmù orí kẹjọ, ẹsẹ ìkọkànlélógún yóò nímùúṣẹ pé: “A óò dá ìṣẹ̀dá [aráyé] tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” Wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “[Ọlọ́run] yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.”—Aísáyà 25:8.

Ìrètí Ìyè Àìnípẹ̀kun

16. Èé ṣe tó fi tọ́ láti máa wọ̀nà fún èrè ìyè àìnípẹ̀kun?

16 Ìfojúsọ́nà àgbàyanu gbáà lèyí jẹ́ fún àwọn olóòótọ́, láti mọ̀ pé Ọlọ́run yóò máa rọ̀jò ọ̀pọ̀ yanturu àǹfààní tẹ̀mí àti ti ara lé wọn lórí títí láé ni! Onísáàmù náà tọ̀nà nígbà tó sọ pé: “Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn [títọ́] gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.” (Sáàmù 145:16) Jèhófà gba àwọn tó jẹ́ ẹgbẹ́ ti ilẹ̀ ayé níyànjú láti ní ìrètí wíwàláàyè nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé yìí gẹ́gẹ́ bí ara ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú òun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa ipò ọba aláṣẹ Jèhófà ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ, síbẹ̀ kò sọ pé káwọn ènìyàn máa sin òun láìsí ìrètí pé wọ́n máa gba èrè kankan. Látìbẹ̀rẹ̀ dópin Bíbélì ni ọ̀rọ̀ nípa ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run àti ìrètí ìyè ayérayé ti wà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn apá tó ṣe pàtàkì lára ìgbàgbọ́ tí Kristẹni kán ní nínú Ọlọ́run. “Ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”—Hébérù 11:6.

17. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé ó dára kí ìrètí táa ní máa gbé wa ró?

17 Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Níhìn-ín, ó so mímọ Ọlọ́run àtàwọn ète rẹ̀ mọ́ èrè tí èyí yóò mú wá. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí oníwà àìtọ́ kan sọ pé kí Jésù rántí òun nígbà tó bá dénú Ìjọba rẹ̀, Jésù sọ pé: “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:43) Kò sọ pé kí ọkùnrin náà ṣáá ní ìgbàgbọ́ kódà bí kò bá rí èrè kankan gbà. Ó mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ òun ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé tó di Párádísè, kíyẹn lè gbé wọn ró bí wọ́n ṣe ń kojú onírúurú àdánwò nínú ayé yìí. Nípa bẹ́ẹ̀, fífojúsọ́nà fún èrè náà jẹ́ ohun pàtàkì kan tó ń ṣèrànwọ́ láti máa fara dà á nìṣó gẹ́gẹ́ bí Kristẹni kan.

Ọjọ́ Ọ̀la Ìjọba Náà

18, 19. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Ọba àti Ìjọba táa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ní òpin Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún náà?

18 Níwọ̀n bí Ìjọba náà ti jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ àkóso tí Jèhófà yóò lò láti mú ayé àti àwọn èèyàn tó ń gbé inú rẹ̀ wá sí ìjẹ́pípé àti láti mú wọn padà bá òun rẹ́, kí wá ni ipa tí Jésù Kristi àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n jẹ́ ọba àti àlùfáà yóò kó lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rúndún náà? “Lẹ́yìn náà, ní òpin, nígbà tí ó bá fi ìjọba lé Ọlọ́run àti Baba rẹ̀ lọ́wọ́, nígbà tí ó bá ti sọ gbogbo ìjọba àti gbogbo ọlá àṣẹ àti agbára di asán. Nítorí òun gbọ́dọ̀ ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí Ọlọ́run yóò fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 15:24, 25.

19 Nígbà tí Kristi bá dá Ìjọba náà padà fún Ọlọ́run, òye wo ni ká wá ní nípa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa pé Ìjọba Kristi yóò wà títí láé? Àwọn ohun tí Ìjọba náà ṣe àṣeyọrí rẹ̀ yóò wà títí láé ni. A ó máa bọlá fún Kristi títí láé nítorí ipa tí ó kó nínú dídá ipò ọba aláṣẹ ti Ọlọ́run láre. Àmọ́, níwọ̀n bí a ó ti mú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú kúrò pátápátá nígbà yẹn, tí a ó sì ti tún ìran ènìyàn rà padà, èyí ti fòpin sí jíjẹ́ tí ó jẹ́ Olùtúnniràpadà. Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún Ìjọba náà yóò ti mú ète rẹ̀ ṣẹ ní kíkún; nítorí náà a ò tún ní nílò amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ àkóso kankan láti wà láàárín Jèhófà àti ìran ènìyàn onígbọràn mọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, “Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.”—1 Kọ́ríńtì 15:28.

20. Báwo la ṣe lè mọ ohun ti ọjọ́ iwájú ní nípamọ́ fún Kristi àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì?

20 Ipa wo ni Kristi àtàwọn àjùmọ̀ṣàkóso rẹ̀ yóò kó lọ́jọ́ iwájú lẹ́yìn tí Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún náà bá parí? Bíbélì kò sọ. Ṣùgbọ́n, ó lè dá wa lójú pé Jèhófà yóò fún wọn ní ọ̀pọ̀ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn sí i nínú ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa lóde òní gbé ipò ọba aláṣẹ Jèhófà lárugẹ, kí ìyè ayérayé sì tẹ̀ wá lọ́wọ́, kí a bàá lè wà láàyè lọ́jọ́ iwájú láti rí ohun tí Jèhófà ti pète fún Ọba náà àti àwọn ọba àti àlùfáà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, títí kan ohun tó pète fún gbogbo àgbàyanu àgbáálá ayé rẹ̀!

Àwọn Kókó fún Àtúnyẹ̀wò

• Ìyípadà nínú ìṣàkóso wo la ń sún mọ́?

• Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ṣèdájọ́ ẹni ibi àti olódodo?

• Àwọn ipò wo ló máa wà nínú ayé tuntun?

• Báwo la ó ṣe dá ipò ọba aláṣẹ Jèhófà láre ní kíkún?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

“Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn adúróṣinṣin yóò padà bẹ̀rẹ̀ àjọṣe tí ó tọ́ pẹ̀lú Jèhófà