Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣíṣiṣẹ́ Nínú “Pápá” Ṣáájú Ìkórè

Ṣíṣiṣẹ́ Nínú “Pápá” Ṣáájú Ìkórè

Ṣíṣiṣẹ́ Nínú “Pápá” Ṣáájú Ìkórè

Ó YA àwọn ọmọ ẹ̀yìn Olùkọ́ Ńlá náà lẹ́nu. Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ìtàn kúkúrú kan nípa àlìkámà àti èpò fún wọn tán ni. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àkàwé bíi mélòó kan tó sọ lọ́jọ́ yẹn. Nígbà tó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ kúrò níbẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ̀ pé àwọn àkàwé rẹ̀ gbọ́dọ̀ ní ìtumọ̀ pàtó kan—àgàgà èyí tó sọ nípa àlìkámà àti èpò. Wọ́n mọ̀ pé Jésù kì í kàn án ṣe asọ̀tàn tó lárinrin lásán.

Mátíù ròyìn pé wọ́n ní: “Ṣàlàyé àpèjúwe àwọn èpò inú pápá fún wa.” Láti dá wọn lóhùn, Jésù túmọ̀ àkàwé náà, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìpẹ̀yìndà ńlá tí yóò ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn tó pe ara wọn ní àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. (Mátíù 13:24-30, 36-38, 43) Èyí ṣẹlẹ̀ lóòótọ́, kíá ni ìpẹ̀yìndà sì tàn kálẹ̀ lẹ́yìn ikú àpọ́sítélì Jòhánù. (Ìṣe 20:29, 30; 2 Tẹsalóníkà 2:6-12) Ipa tó ní rinlẹ̀ débi pé ìbéèrè tí Jésù béèrè, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ Lúùkù 18:8, dà bí èyí tó bá a mu wẹ́kú pé:“ “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé, yóò ha bá ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀ ayé ní ti gidi bí?”

Dídé Jésù yóò sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ “ìkórè” àwọn Kristẹni tó dà bí àlìkámà. Ìyẹn yóò jẹ́ àmì ‘ìparí ètò àwọn nǹkan,’ tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1914. Nítorí náà kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí fi ìfẹ́ hàn sí òtítọ́ Bíbélì ní àkókò tó ṣáájú ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè náà.—Mátíù 13:39.

Àyẹ̀wò kan lórí àkọsílẹ̀ ìtàn jẹ́ kó hàn gbangba pé ní pàtàkì jù lọ láti ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún síwájú ni àwọn èèyàn ti ń hára gàgà, kódà láàárín àwùjọ Kirisẹ́ńdọ̀mù tí wọ́n dà bí “èpò,” tàbí àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà. Bí Bíbélì ṣe di ohun tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo ènìyàn, tí wọ́n sì tún ṣe àwọn atọ́ka Bíbélì jáde, àwọn aláìlábòsí-ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí fara balẹ̀ wá inú Ìwé Mímọ́ káàkiri.

Ìmọ́lẹ̀ Náà Ń Mọ́lẹ̀ Sí I

Lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tó wà láyé nígbà tí ọ̀rúndún kọkàndínlógún fi máa bẹ̀rẹ̀ ni Henry Grew (1781 sí 1862) láti Birmingham, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá, òun àti ìdílé rẹ̀ tukọ̀ kọjá Òkun Àtìláńtíìkì lọ sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, wọ́n gúnlẹ̀ ní July 8, 1795. Wọ́n tẹ̀dó sí Providence, ní erékùṣù Rhode. Àwọn òbí rẹ̀ gbin ìfẹ́ fún Bíbélì sí i lọ́kàn. Lọ́dún 1807, nígbà tó di ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, wọ́n ké sí Grew láti wá ṣe pásítọ̀ Ìjọ Onítẹ̀bọmi ní Hartford, Connecticut.

Kò fi àwọn ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ ṣeré rárá, ó sì gbìyànjú láti ran àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa gbé ìgbé ayé wọn ní ìbámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́. Àmọ́ o, ó gbà gbọ́ pé kò yẹ kí ẹnikẹ́ni tó ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ wà nínú ìjọ, kí ìjọ lè wà ní mímọ́ tónítóní. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, òun, àtàwọn ọkùnrin mìíràn tó lẹ́rù iṣẹ́ nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà, máa ń yọ àwọn tó bá dẹ́ṣẹ̀ àgbèrè tàbí àwọn tó bá hu àwọn ìwà àìmọ́ mìíràn lẹ́gbẹ́.

Àwọn ìṣòro mìíràn tún wà nínú ṣọ́ọ̀ṣì yẹn tó ń dà á láàmú. Àwọn ọkùnrin kan wà tí wọn kì í ṣe mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì náà àmọ́ tí wọ́n wá ń bá wọn bójú tó ọ̀rọ̀ ìnáwó tí wọ́n sì tún ń ṣáájú orin kíkọ nígbà tí ààtò ìsìn bá ń lọ lọ́wọ́. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tiẹ̀ lè dìbò lórí àwọn ọ̀ràn tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọ kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ máa darí àwọn kan lára àwọn àlámọ̀rí rẹ̀. Nítorí ìlànà yíya ara ẹni sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé, ó dá Grew lójú gidigidi pé kìkì àwọn ọkùnrin olóòótọ́ ló yẹ kó máa ṣe àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí. (2 Kọ́ríńtì 6:14-18; Jákọ́bù 1:27) Lójú tiẹ̀, ó gbà pé ọ̀rọ̀ òdì pátápátá ni kí àwọn aláìgbàgbọ́ máa kọ orin ìyìn sí Ọlọ́run. Nítorí ojú ìwòye yìí, ṣọ́ọ̀ṣì náà lé Henry Grew dà nù lọ́dún 1811. Àwọn mẹ́ńbà mìíràn tí wọ́n ní irú èrò bíi tirẹ̀ ya ara wọn kúrò nínú ṣọ́ọ̀ṣì ọ̀hún láàárín àkókò kan náà.

Kíkúrò Nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù

Ẹgbẹ́ yìí, títí kan Henry Grew, bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú èrò pé àwọn yóò mú ìgbésí ayé àwọn àti àwọn ìgbòkègbodò àwọn bá àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ mu. Kíá ni ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń ṣe jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ lóye òtítọ́ Bíbélì gan-an, tó sì mú kí wọ́n máa tú àwọn ìṣìnà Kirisẹ́ńdọ̀mù fó. Fún àpẹẹrẹ, ní 1824, Grew ronú jinlẹ̀ kọ ìwé kan tó fi hàn pé ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan jẹ́ èké. Wo ọgbọ́n tó wà nínú àyọkà yìí táa mú jáde látinú àwọn ìwé tó kọ pé: “‘Ní ti ọjọ́ yẹn, àti wákàtí yẹn kò sí ènìyàn kan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́run pàápàá ò mọ̀ ọ́n, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe BABA nìkan.’ [Máàkù 13:32] Kíyè sí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ipò tí olúkúlùkù wọn wà. Ènìyàn, Àwọn Áńgẹ́lì, Ọmọ, Baba. . . . Olúwa wa kọ́ wa pé Baba nìkan lo mọ ọjọ́ yẹn. Àmọ́ èyí kì í ṣòótọ́, táa bá gbé e ka èrò àwọn kan pé, Baba, Ọ̀rọ̀, àti Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ ẹni mẹ́ta nínú Ọlọ́run kan: nítorí pé ní ìbámu pẹ̀lú [ẹ̀kọ́, ìyẹn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan] yìí, . . . kò sóhun tí Baba mọ̀ tí ọmọ kò mọ̀.”

Grew tú àṣírí àgàbàgebè àwọn àlùfáà àtàwọn ọ̀gágun tí wọ́n ń díbọ́n pé àwọn ń ṣé iṣẹ́ ìsìn sí Kristi. Ó polongo lọ́dún 1828 pé: “Ǹjẹ́ a tún lè ronú nípa ohun mìíràn tí kò bára dọ́gba ju èyí lọ pé kí Kristẹni kan jáde láti inú ìyẹ̀wù rẹ̀, níbi tó ti ń gbàdúrà fún àwọn ọ̀tá rẹ̀, kó sì wá sọ pé kí àwọn ọmọ ogun òun fi ìbínú tó lé kenkà fi ohun ìjà tó ń ṣekú pani gún ọkàn-àyà àwọn ọ̀tá rẹ̀ yẹn? Lọ́nà tó múni láyọ̀, ó jọ Ọ̀gá rẹ̀ tó ń kú lọ lọ́nà kan; àmọ́ tá ló wá fi òdì kejì jọ? Jésù gbàdúrà fún àwọn tó pa á. Àwọn tó jẹ́ Kristẹni wá ń pa àwọn tí wọ́n ń gbàdúrà fún.

Kódà lọ́nà tó túbọ̀ lágbára sí i, Grew kọ̀wé pé:“ “Ìgbà wo la fẹ́ gba Olódùmarè gbọ́, ẹni tó mú un dá wa lójú pé a kò lè fi òun ‘ṣe ẹlẹ́yà?’ Ìgbà wo la fẹ́ lóye bí ìsìn mímọ́ yẹn ṣe rí, ìyẹn ni pé ohun tó túmọ̀ sí, tó ní ká fà sẹ́yìn kúrò nínú ‘ohun tó fara jọ ibi’ pàápàá? . . . Ǹjẹ́ ẹ̀gàn kọ́ lèyí jẹ́ fún Ọmọ ìbùkún náà, láti ronú pé ìsìn rẹ̀ gbà pé kí ẹnì kan hùwà bí áńgẹ́lì ní ipò kan, kó sì tún fàyè gbà á láti hùwà bí ẹ̀mí èṣù nípò mìíràn?”

A Kò Bí Iyè Ayérayé Mọ́ Wa

Láwọn ọdún wọ̀nyẹn, kó tó di pé rédíò àti tẹlifíṣọ̀n dé, ọ̀nà tó gbajúmọ̀ jù lọ tàwọn èèyàn fi ń sọ èrò wọn jáde ní pé kí wọ́n kọ nǹkan sínú ìwé ìléwọ́ kékeré, kí wọ́n sì pín in káàkiri. Ní nǹkan bí ọdún 1835, Grew kọ ìwé ìléwọ́ pàtàkì kan tó fi tú àṣírí ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn àti iná ọ̀run àpáàdì pé wọn ò bá Ìwé Mímọ́ mu. Ó ronú pé àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí ń sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run.

Ipa tí ìwé ìléwọ́ kékeré yìí ní kọjá kèrémí. Lọ́dún 1837, George Storrs tó jẹ́ ẹni ogójì ọdún rí ẹ̀dà kan ní ojú ọ̀nà rélùwéè. Ọmọ ilẹ̀ Lẹ́bánónì, ní New Hampshire ni Storrs, àmọ́ Utica, ní New York ló ń gbé nígbà yẹn.

Òjíṣẹ́ kan tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún gidigidi ni nínú ìjọ Mẹ́tọ́díìsì ti Episcopal. Bó ṣe ka ìwé ìléwọ́ kékeré náà tán, ó wú u lórí pé ẹnì kan lè ṣe irú àlàyé tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ bẹ́ẹ̀ láti tako àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti Kirisẹ́ńdọ̀mù wọ̀nyí, tí òun kò ṣiyè méjì nípa wọn rí. Kò mọ ẹni tó kọ ìwé ìléwọ́ náà, kò sì mọ̀ ọ́n títí di àwọn ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn náà, ìyẹn ní nǹkan bí 1844, nígbà tó pàdé Henry Grew lákòókò táwọn méjèèjì ń gbé Filadéfíà, ní Pennsylvania. Àmọ́, odindi ọdún mẹ́ta gbáko ní Storrs fi ń gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò fúnra rẹ̀, tó sì ń bá kìkì àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Níkẹyìn, níwọ̀n ìgbà tí kò ti sí ẹni tó lè já àwọn nǹkan tí George Storrs ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní koro, ó wá pinnu pé òun ò lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run tí òun bá ṣì wà nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì. Bó ṣe kọ̀wé fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ́dún 1840 nìyẹn, tó si kó lọ sí Albany, ní New York.

Níbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìrúwé ọdún 1842, Storrs sọ ọ̀wọ́ àwọn àsọyé mẹ́fà fún ọ̀sẹ̀ mẹ́fà lórí kókó náà, “Ìwádìí Kan—Ṣé Àwọn Ẹni Ibi Kì Í Kú?” Àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí i gan-an ni débi pé ó ní láti tún un kọ fún ìtẹ̀jáde, ní ohun tó sì lé ní ogójì ọdún tó tẹ̀ lé e, ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] ẹ̀dà ló ti wà káàkiri ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà àti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Storrs àti Grew jọ fìmọ̀ ṣọ̀kan láti ṣe àwọn àlàyé tó tako ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ àìleèkú ọkàn. Grew ń bá fífi tìtaratìtara wàásù nìṣó títí ó fi kú ní August 8, 1862, ní Filadéfíà.

Kété lẹ́yìn tí Storrs sọ ọ̀wọ́ àwọn àwíyé rẹ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà táa mẹ́nu kan yẹn tán, ó bẹ̀rẹ̀ sí fìfẹ́ hàn sí ìwàásù William Miller, ẹni tó ń retí ìpadàbọ̀ Kristi tó ṣeé fojú rí lọ́dún 1843. Fún nǹkan bí ọdún méjì ni Storrs fi ń fi taratara kópa nínú wíwàásù ìsọfúnni yìí káàkiri àríwá ìhà ìlà oòrùn Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn 1844, ó dẹ́kun dídá ọjọ́ fún ìpadàbọ̀ Kristi, ṣùgbọ́n kò lòdì sí i bí àwọn mìíràn bá fẹ́ wádìí déètì náà. Storrs gbà gbọ́ pé ìpadàbọ̀ Kristi ti sún mọ́lé, àti pé ó ṣe pàtàkì fún àwọn Kristẹni láti jí gìrì, kí wọ́n sì wà lójúfò nípa tẹ̀mí, kí wọ́n múra de ọjọ́ ìbẹ̀wò. Ṣùgbọ́n ó kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ Miller nítorí pé wọ́n gba àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu gbọ́, ìyẹn àwọn ẹ̀kọ́ bí àìleèkú ọkàn, jíjó ayé run, àti àìsí ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun kankan fún àwọn tó kú láìmọ̀kan.

Kí Ni Ìfẹ́ Ọlọ́run Yóò Já Sí?

Storrs kórìíra èrò àwọn ẹlẹ́sìn Adventist pé Ọlọ́run yóò jí àwọn ènìyàn búburú dìde kìkì kí o lè pa wọ́n lẹ́ẹ̀kejì. Kò rí ẹ̀rí kankan nínú Ìwé Mímọ́ pé Ọlọ́run yóò ṣe ohun tí kò nítumọ̀ tó sì tún jẹ́ ìwà ìgbẹ̀san bẹ́ẹ̀. Storrs àtàwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tún wá ki àṣejù bọ̀ ọ́, wọ́n sì parí èrò sí pé àwọn ẹni ibi kò ní jíǹde rárá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro fún wọn láti ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó tọ́ka sí àjíǹde àwọn aláìṣòótọ́, síbẹ̀ ibi tí wọ́n parí èrò sí ló dà bí èyí tó túbọ̀ bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu lójú tiwọn. Ìgbésẹ̀ mìíràn tí wọ́n fi máa lóye ète Ọlọ́run ò ní pẹ́ẹ́ dé.

Ní 1870, àìsàn líle koko kan kọlu Storrs débí pé kò lè ṣiṣẹ́ fún àwọn oṣù bíi mélòó kan. Láàárín àkókò yìí, ó ṣeé ṣe fún un láti ṣàtúnyẹ̀wò gbogbo ẹ̀kọ́ tó ti kọ́ fún ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rin tó ti lò láyé. Ó wá parí èrò sí pé òun ti kùnà láti lóye apá pàtàkì kan nínú ète Ọlọ́run fún ìran ènìyàn, bó ṣe wà nínú májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá—pé ‘gbogbo ìdílé ayé yóò bù kún ara wọn nítorí pé Ábúráhámù fetí sí ohùn Ọlọ́run.’—Jẹ́nẹ́sísì 22:18; Ìṣe 3:25.

Èyí mú èrò tuntun wá sọ́kàn rẹ̀. Bí a óò bá bù kún “gbogbo àwọn ìdílé,” ǹjẹ́ kì í ṣe gbogbo wọn ló yẹ kó gbọ́ ìhìn rere náà? Báwo ni wọ́n ṣe máa gbọ́ ọ? Ǹjẹ́ kì í ṣe àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ló ti kú? Nígbà tó wá túbọ̀ yẹ Ìwé Mímọ́ wò, ó wá parí èrò sí pé ẹgbẹ́ méjì ni àwọn “ẹni burúkú” tí wọ́n ti kú pín sí, àwọn ni: àwọn tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ kọ ìfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àtàwọn tó kú láìmọ̀kan.

Storrs wá sọ pé ó yẹ kí a jí àwọn ti ìkẹyìn yìí dìde kúrò nínú òkú láti fún wọn láyè kí wọ́n lè jàǹfààní nínú ẹbọ ìràpadà Kristi Jésù. Àwọn tó bá tẹ́wọ́ gbà á yóò wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn tó bá kọ̀ ọ́ yóò pa run. Dájúdájú, Storrs gbà gbọ́ pé kò sí ẹnì kan tí Ọlọ́run máa jí dìde láìjẹ́ pé ìrètí kan wà fún un. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, kò ní sí ẹni tó tìtorí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù kú yàtọ̀ sí Ádámù fúnra rẹ̀! Àmọ́, àwọn tó máa wà láàyè nígbà tí Olúwa Jésù Kristi bá padà bọ̀ ńkọ́? Storrs wá rí i níkẹyìn pé iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé gbọ́dọ̀ di ṣíṣe láti dé ọ̀dọ̀ wọn. Kò tiẹ̀ ní òye kankan nípa ọ̀nà tí wọ́n lè gbé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ gbà, ṣùgbọ́n ó fi ìgbàgbọ́ kọ̀wé pé: “Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ ló jẹ́ pé tí wọn ò bá ti mọ ọ̀nà tí wọn óò gbé nǹkan kan gbà, wọ́n á kọ̀ ọ́ sílẹ̀, bí ẹni pé kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti ṣe é nítorí pé wọn o mọ ojútùú rẹ̀.”

George Storrs kú ní December 1879, ní ilé rẹ̀ tó wà ní Brooklyn, New York, tí kò ju ẹsẹ̀ bàtà bíi mélòó kan sí ibi tó wá di orísun iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé tó ti fi ìháragàgà retí.

À Ń Fẹ́ Ìmọ́lẹ̀ Sí I

Ǹjẹ́ àwọn ọkùnrin bíi Henry Grew àti George Storrs lóye òtítọ́ ní kedere tó bí a ṣe lóye rẹ̀ lónìí? Rárá o. Wọ́n mọ̀ pé ńṣe làwọn ń tiraka, gẹ́gẹ́ bí Storrs ṣe sọ ọ́ ní 1847 pé: “Ì bá dára ká máa rántí pé ṣe la ṣẹ̀ṣẹ̀ ń jáde kúrò nínú sànmánì ojú dúdú ṣọ́ọ̀ṣì; kò sì gbọ́dọ̀ yà wá lẹ́nu táa bá rí i pé a ṣì ń gba ‘àwọn ohun kan tí Bábílónì gbà gbọ́’ pé wọ́n jóòótọ́.” Fún àpẹẹrẹ, Grew mọyì ìràpadà tí Jésù pèsè, ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí” ni, ìyẹn ni ìwàláàyè ènìyàn pípé ti Jésù tí a fi ṣe pàṣípààrọ̀ fún ìwàláàyè ènìyàn pípé tí Ádámù sọ nù. (1 Tímótì 2:6) Henry Grew tún fi àṣìṣe gbà gbọ́ pé Jésù yóò padà wá ṣàkóso tí a ó fójúyòójú rí i lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́ ṣá o, Grew ní àníyàn fún sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, kókó kan tó jẹ́ pé ìwọ̀nba ènìyàn díẹ̀ ló nífẹ̀ẹ́ sí i láti ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa.

Bẹ́ẹ̀ náà ni George Storrs kò ní òye tí ó tọ̀nà nípa àwọn kókó pàtàkì kan. Ó ṣeé ṣe fún un láti rí ẹ̀kọ́ èké tí àwọn àlùfáà ń gbé lárugẹ, àmọ́ ohun tó yàtọ̀ pátápátá lòun náà máa ń sọ nígbà mìíràn. Fún àpẹẹrẹ, ó dájú pé ìgbà tí Storrs ti àṣejù bọ àtakò tó ṣe nípa èrò àwọn àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì nípa Sátánì ló bá kúkú kọ èrò pé Èṣù jẹ́ ẹni gidi sílẹ̀ pátápátá. Kò gba Mẹ́talọ́kan gbọ́: àmọ́, kò dá a lójú bóyá ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ẹnì kan tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ títí tó fi kù díẹ̀ kó kú. Nígbà tó jẹ́ pé George Storrs gbà pé ìpadàbọ̀ Kristi yóò kọ́kọ́ jẹ́ èyí tí kò ní ṣeé fojú rí, ó rò pé ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ìfarahàn tó ṣeé fojú rí yóò wà. Síbẹ̀síbẹ̀, ó dà bí ẹni pé aláìlábòsí-ọkàn àti olóòótọ́ ni àwọn ọkùnrin méjèèjì wọ̀nyí, wọ́n sì sún mọ́ òtítọ́ gan-an ju ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn.

“Pápá” tí Jésù ṣàpèjúwe nínú àkàwé àlìkámà àti èpò kò tíì ṣe tán fún kíkórè. (Mátíù 13:38) Grew, Storrs, àtàwọn mìíràn ń ṣiṣẹ́ nínú “pápá” ní ìmúrasílẹ̀ de ìkórè ni.

Charles Taze Russell, tó bẹ̀rẹ̀ sí tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde ní 1879, kọ̀wé nípa àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ pé: “Olúwa fún wa ní ọ̀pọ̀ ìrànwọ́ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ Rẹ̀, lára àwọn tó lókìkí jù lọ níbẹ̀ ni olólùfẹ́ àti arákùnrin wa arúgbó ọ̀wọ́n, George Storrs, ẹni tó jẹ́ pé ó ṣe ìrànwọ́ tó pọ̀ fún wa nípa ọ̀rọ̀ àti àwọn ohun tó kọ sílẹ̀; àmọ́, a gbìyànjú láti má ṣe jẹ́ ọmọlẹ́yìn ènìyàn láé, bó ti wù kí onítọ̀hún dára tó, bó sì ti wù kó gbọ́n tó, bí kò ṣe ‘Ọmọlẹ́yìn Ọlọ́run bí àwọn ọmọ ọ̀wọ́n.’” Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn olóòótọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè jàǹfààní látinú àwọn ìsapá tí àwọn ọkùnrin bíi Grew àti Storrs ṣe, ṣùgbọ́n ó tún ṣe pàtàkì láti ṣàyẹ̀wò Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ojúlówó orísun òtítọ́.—Jòhánù 17:17.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ohun Tí Henry Grew Gbà Gbọ́

Wọ́n ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà, ó sì yẹ kí a sọ ọ́ di mímọ́.

Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, àìleèkú ọkàn, àti iná ọ̀run àpáàdì jẹ́ ẹ̀tàn.

Ìjọ Kristẹni gbọ́dọ̀ ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé.

Àwọn Kristẹni kò gbọ́dọ̀ kópa nínú ogun àwọn orílẹ̀-èdè.

Àwọn Kristẹni kò sí lábẹ́ òfin Sábáàtì ti ọjọ́ Sátidé tàbí ti ọjọ́ Sunday.

Àwọn Kristẹni kò gbọ́dọ̀ wà nínú ẹgbẹ́ awo, bí ẹgbẹ́ Ògbóni.

Kò yẹ kí ẹgbẹ́ àlùfáà àti ẹgbẹ́ ọmọ ìjọ wà láàárín àwọn Kristẹni.

Ọ̀dọ̀ àwọn aṣòdì-sí-Kristi ni orúkọ oyè nínú ìsìn ti wá.

Gbogbo ìjọ gbọ́dọ̀ ní ẹgbẹ́ àwọn alàgbà.

Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ nínú gbogbo ìwà wọn, kí wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn.

Gbogbo Kristẹni gbọ́dọ̀ wàásù ìhìn rere.

Àwọn èèyàn tó máa wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé yóò wà.

Orin Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́ ìyìn sí Jèhófà àti Kristi.

[Credit Line]

Fọ́tò: Collection of The New-York Historical Society/69288

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Ohun Tí George Storrs Gbà Gbọ́

Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ san owó ìràpadà fún ìran ènìyàn.

A kò tíì ṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà (lọ́dún 1871).

Nítorí náà òpin kò tíì lè sún mọ́lé ní àkókò yẹn (lọ́dún 1871). Ọjọ́ iwájú kan ní láti wà nígbà tí iṣẹ́ ìwàásù náà yóò di ṣíṣe.

Àwọn èèyàn yóò wà tí wọn máa gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé.

A óò jí gbogbo àwọn tó kú láìmọ̀kan dìde. Àwọn tó bá tẹ́wọ́ gba ẹbọ ìràpadà Kristi yóò gba ìyè ayérayé lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn tó bá kọ̀ ọ́ yóò pa run.

Àìleèkú ọkàn àti iná ọ̀run àpáàdì jẹ́ ẹ̀kọ́ èké tí kò bọlá fún Ọlọ́run.

Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa jẹ́ ayẹyẹ ọdọọdún ní Nísàn 14.

[Credit Line]

Fọ́tò: SIX SERMONS, láti ọwọ́ George Storrs (1855)

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Lọ́dún 1909, C. T. Russell, olóòtú “Zion’s Watch Tower,” kó lọ sí Brooklyn, New York ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà