Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Owó Ẹ àbí Ẹ̀mí Ẹ?

Owó Ẹ àbí Ẹ̀mí Ẹ?

Owó Ẹ àbí Ẹ̀mí Ẹ?

Ó ṣeé ṣe kóo ti gbọ́ nípa àwọn adigunjalè tí wọ́n ń kọjú ìbọn sáwọn tí wọ́n bá dá lọ́nà, tí wọ́n á sì sọ pé: “Owó ẹ àbí ẹ̀mí ẹ!” Lónìí, ọ̀rọ̀ tí kò ṣàjèjì yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí dún jáde nítorí ìṣòro lílekoko tó dojú kọ gbogbo wa—àgàgà àwa tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù. Àmọ́ ṣá, ọ̀rọ̀ àwọn adigunjalè kọ́ là ń sọ lọ́wọ́ táa wà yìí. Bí kò ṣe bí àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn ṣe túbọ̀ ń ka owó àti ọrọ̀ àlùmọ́nì sí nǹkan bàbàrà.

IRÚ nǹkan bẹ́ẹ̀ sì ti gbé àwọn ìṣòro àti àníyàn tuntun dìde. Báwo ló ṣe yẹ ká lépa owó àti àwọn ohun ìní ti ara tó? Ǹjẹ́ ohun díẹ̀ lè tẹ́ wa lọ́rùn? Ṣé lóòótọ́ làwọn èèyàn ń fi “ìyè tòótọ́” du ara wọn nítorí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì? Ṣé owó ni lájorí ohun tó ń fúnni ní ìgbésí ayé aláyọ̀?

Wíwá Owó Lójú Méjèèjì

Nínú gbogbo ohun táwọn èèyàn fọkàn fẹ́, tí wọ́n sì ń hára gàgà fún—yálà èyí tó bófin mu ni o, tàbí èyí tí kò bófin mu—ìfẹ́ owó ló gbapò kìíní. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀ àti oúnjẹ, ìlépa owó kì í dópin. Ọjọ́ ogbó kì í fòpin sí i. Nínú ọ̀pọ̀ ọ̀ràn, ńṣe ni ọjọ́ ogbó pàápàá tún máa ń fi kún ìfẹ́ téèyàn ní fún owó tàbí bó ṣe ń ṣàníyàn nípa rẹ̀ àti nípa ohun tówó lè rà.

Ìwọra túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ẹni tó jẹ́ òṣèré tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú sinimá kan tó lókìkí sọ pé: “Ìwọra ń múni kẹ́sẹ járí. Ìwọra ṣàǹfààní.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń pe àwọn ọdún 1980 ní Ọdún Ìwọra, ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú àti lẹ́yìn àkókò yẹn fi hàn pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ nínú ìṣarasíhùwà àwọn èèyàn sí owó bí ọdún ti ń gorí ọdún.

Ohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ tuntun ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ti rí àǹfààní tó pọ̀ láti tẹ́ ìfẹ́ tí wọ́n ní fún ọrọ̀ àlùmọ́nì lọ́rùn lójú ẹsẹ̀. Ó dà bí ẹni pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn tó wà láyé ló ń fi àkókò tó pọ̀ jù lọ lo èyí tó pọ̀ jù lọ nínú agbára wọn láti wá ọ̀rọ̀ àlùmọ́nì, kí wọ́n sì kó o jọ pelemọ. O lè gbà pé kíkó ọrọ̀ jọ àti nínáwó ti di ìgbòkègbodò táwọn èèyàn ń fìtara ṣe—tó sì sábà ń jẹ́ èyí tí wọ́n ń ronú lé lórí jù lọ—nínú ìgbésí ayé òde òní.

Àmọ́, ǹjẹ́ ìyẹn ń mú kí ayọ̀ àwọn èèyàn pọ̀ sí i? Ní ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn, ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì, tó lọ́rọ̀ rẹpẹtẹ kọ̀wé ní ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta sẹ́yìn pé: “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá. Asán ni èyí pẹ̀lú.” (Oníwàásù 5:10) Ẹ̀kọ́ nípa àjọṣe ẹ̀dá fi hàn pé bẹ́ẹ̀ náà lọ̀ràn rí lóde òní.

Owó àti Ayọ̀

Ọ̀kan nínú àwọn àwárí tó yani lẹ́nu jù lọ nínú ìṣe ẹ̀dá ènìyàn ni pé kíkó owó àti ọrọ̀ àlùmọ́nì jọ pelemọ kì í fi bẹ́ẹ̀ fúnni ní ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ púpọ̀ sí i. Ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn olùṣèwádìí wá mọ̀ báyìí ni pé gbàrà téèyàn bá ti lówó débì kan, ọ̀rọ̀ nípa ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ rẹ̀ kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ọ̀pọ̀ nǹkan ìní tó ń kó jọ mọ́.

Ìdí nìyẹn tí wíwá ọrọ̀ àlùmọ́nì àti owó lójú méjèèjì fi mú kí àwọn kan máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ó dà bíi pé gbogbo nǹkan tuntun táa bá rà la máa ń gbádùn; síbẹ̀, èé ṣe tó fi jẹ́ pé nígbà tá bá tún gbé gbogbo rẹ̀ yẹ̀ wò, a óò rí i pé gbogbo ìgbádùn wọ̀nyí kò fún wa ní ìtẹ́lọ́rùn púpọ̀ sí i?’

Nínú ìwé Happy People, òǹkọ̀wé náà, Jonathan Freedman sọ pé: “Gbàrà tí owó tó ń wọlé fún ọ bá ti pọ̀ débì kan, kò sí bí owó tóo bá ní lẹ́yìn náà ṣe lè pọ̀ tó táa wá fi kún ayọ̀ rẹ. Tí owó tó ń wọlé bá ti gbé pẹ́ẹ́lí kọjá ti ẹni táa lè pè ní òtòṣì, owó tó ń wọlé kò fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan í ṣe pẹ̀lú ayọ̀ mọ́.” Ọ̀pọ̀ ló ti wá mọ̀ báyìí pé olórí ohun tó ń fúnni láyọ̀ ni pé kéèyàn ní dúkìá nípa tẹ̀mí, kó ní àwọn góńgó tó ní láárí nínú ìgbésí ayé, kó tún wá níwà rere pẹ̀lú. Ohun tó tún ṣe pàtàkì ni kéèyàn ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, kó máà sí ìforígbárí tàbí ìkálọ́wọ́kò èyíkéyìí tó lè dí wa lọ́wọ́ àtigbádùn ohun táa ní.

Ọ̀pọ̀ ti rí i pé ohun tó ń fa èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìṣòro ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà òde òní ni kéèyàn máa lérò pé òun lè gbìyànjú láti fi aásìkí ti ara yanjú ìdààmú ọkàn. Àwọn kan tó máa ń sọ̀rọ̀ nípa àjọṣe ẹ̀dá sọ pé èrò pé nǹkan ò ní dáa àti àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn wọ́pọ̀ gan-an báyìí. Wọ́n tún kíyè sí bí àwọn èèyàn tó ń gbé ní àwọn àwùjọ tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù ṣe túbọ̀ ń tọ àwọn tí ń ṣètọ́jú lọ tàbí kí wọ́n máa wá bí ayé wọn ṣe lè nítumọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn olùkọ́ ẹ̀sìn Híńdù, ẹgbẹ́ awo, àti àwọn ẹgbẹ́ tó sọ pé àwọn lè ṣètọ́jú. Èyí fi hàn pé ọrọ̀ àlùmọ́nì kò lè mú kí ìgbésí ayé ẹni nítumọ̀ gidi.

Owó Lágbára, Kò sì Tún Lágbára

Ká sọ tòótọ́, owó lágbára. Ó lè ra ilé mèremère, ó lè ra àwọn aṣọ tó lẹ́wà, ó sì lè ra àwọn àga olówó iyebíye sínú ilé. Ó sì lè jẹ́ kí wọ́n máa pọ́n èèyàn lé láwùjọ, yálà àpọ́nlé náà jóòótọ́ tàbí ti ẹ̀tàn, ó tiẹ̀ lè jẹ́ kéèyàn ní àwọn aríre-báni-jẹ ọ̀rẹ́ pàápàá. Àmọ́ gbogbo ibi tágbára owó mọ náà kò jù bẹ́ẹ̀ lọ. Owó kò lè ra ohun táa nílò jù lọ—ìyẹn ni ìfẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́ kan, ìbàlẹ̀ ọkàn, ìtùnú tó tọkàn wá nígbà téèyàn bá wà ní bèbè ikú. Owó kò sì lè ra ojú rere Ọlọ́run, fáwọn tó mọyì àjọṣe wọn pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá.

Sólómọ́nì Ọba, tó ní gbogbo nǹkan dáadáa tí owó lè rà nígbà ayé rẹ̀, rí i pé gbígbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ àlùmọ́nì kò lè fúnni ní ayọ̀ pípẹ́ títí. (Oníwàásù 5:12-15) A lè pàdánù owó tí báńkì bá forí ṣánpọ́n tàbí tí ọ̀wọ́n gógó ọjà bá dé. Ìjì líle lè pa dúkìá ilé àti ilẹ̀ run. Bí àwọn abánigbófò bá tiẹ̀ dá díẹ̀ padà lára ohun ìní táa pàdánù, wọn ò lè mú ẹ̀dùn ọkàn ẹni kúrò. Owó ìdókòwò lè wọmi ní ọ̀sán-kan-òru-kan bí ọjà bá kùtà lójijì. Kódà èèyàn lè ní iṣẹ́ tó ń mówó tó jọjú wọlé lónìí, kó sì bọ́ lọ́wọ́ ẹni lọ́la.

Báwo la ṣe lè wá fi owó sí àyè rẹ̀? Ipa wo ló yẹ kí owó àti ohun ìní kó nínú ìgbésí ayé wa? Jọ̀wọ́ túbọ̀ gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò, kí o lè rí i bí o ṣe lè ní ohun kan tó níyè lórí ní ti gidi—ìyẹn ni “ìyè tòótọ́.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Àwọn nǹkan ìní ti ara kì í mú ayọ̀ pípẹ́ títí wá