Fífi Ìtọ́ni Àsìkò Ran Àwọn Ọ̀dọ́ Lọ́wọ́
Ẹ Dúró Lọ́nà Pípé Pẹ̀lú Ìgbàgbọ́ Tó Fìdí Múlẹ̀
Fífi Ìtọ́ni Àsìkò Ran Àwọn Ọ̀dọ́ Lọ́wọ́
EPAFÍRÁSÌ jẹ́ Kristẹni kan tó rìnrìn àjò lọ sí Róòmù ní ọ̀rúndún kìíní. Síbẹ̀ fún ìdí pàtàkì kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí ronú ṣáá nípa Kólósè, ìlú kan ní Éṣíà Kékeré. Ó ti wàásù ìhìn rere níbẹ̀, ó sì dájú pé ó ti ran àwọn kan tó jẹ́ ará Kólósè lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi. (Kólósè 1:7) Epafírásì ṣàníyàn gan-an nípa àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó wà ní Kólósè, nítorí pé láti Róòmù ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti kọ̀wé sí wọn pé: “Epafírásì kí yín, nígbà gbogbo ni ó ń tiraka nítorí yín nínú àwọn àdúrà rẹ̀, pé kí ẹ lè dúró lọ́nà tí ó pé níkẹyìn àti pẹ̀lú ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run.”—Kólósè 4:12.
Bákan náà ni àwọn baba àti ìyá tó jẹ́ Kristẹni lóde òní máa ń fi tìtaratìtara gbàdúrà fún ire tẹ̀mí àwọn ọmọ wọn. Àwọn òbí wọ̀nyí ń tiraka láti gbin ìfẹ́ Ọlọ́run sọ́kàn àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni ló ti béèrè ìrànlọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tí wọ́n ń dojú kọ nílé ìwé àti láwọn ibòmíràn. Ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sọ pé: “Àwọn ìṣòro wa túbọ̀ ń le sí i ni. Ìgbésí ayé ń dẹ́rù bani. A nílò ìrànlọ́wọ́!” Ṣé a ti dáhùn ìbéèrè irú àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí àti àdúrà tí àwọn òbí olùbẹ̀rù Ọlọ́run ń gbà? Bẹ́ẹ̀ ni o! “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti pèsè àwọn ìtọ́ni táa gbé ka Bíbélì. (Mátíù 24:45) Àpilẹ̀kọ yìí mẹ́nu kan àwọn kan lára àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ti ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti “dúró lọ́nà pípé pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó fìdí múlẹ̀.” Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ lára àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí yẹ̀ wò.
“Ẹ Wo . . . Ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ Ẹlẹ́rìí Tuntun!”
Ní August 1941, àwùjọ tó jẹ́ ọ̀kẹ́ márùn-ún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [115,000] kóra jọ sí St. Louis, Missouri, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, fún àpéjọpọ̀ tí ó tóbi jù lọ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tíì ṣe títí di àkókò yẹn. Ní ọjọ́ tó kẹ́yìn—táa pè ní “Ọjọ́ Àwọn Ọmọdé”—nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [15,000] àwọn ọmọdé ló jókòó sítòsí pèpéle, tí wọ́n tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ bí Joseph F. Rutherford ṣe ń sọ̀rọ̀ lórí kókó náà, “Àwọn Ọmọ Ọba.” Nígbà tó kù díẹ̀ kí Rutherford, tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànléláàádọ́rin, parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó fi ohùn tó dún bíi ti baba sọ pé:
“Gbogbo yín . . . ẹ̀yin ọmọdé tẹ́ẹ ti gbà . . . láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run àti Ọba rẹ̀, ẹ jọ̀wọ́, ẹ dìde dúró.” Bí gbogbo àwọn ọmọdé ṣe dìde lẹ́ẹ̀kan náà nìyẹn. Arákùnrin Rutherford, wá sọ ní ohùn rara pé, “Ẹ wò ó, àwọn tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [15,000] ẹlẹ́rìí tuntun fún Ìjọba náà!” Àtẹ́wọ́ wàá-wàá-wàá sì dún. Alásọyé náà wá fi kún un pé: “Gbogbo ẹ̀yin tẹ́ẹ máa ṣe gbogbo ohun tẹ́ẹ bá lè ṣe láti sọ fáwọn ẹlòmíràn nípa ìjọba Ọlọ́run . . . , ẹ jọ̀wọ́, ẹ sọ pé Bẹ́ẹ̀ ni.” Àwọn ọmọdé náà sì fi ohùn rara dáhùn pé “Bẹ́ẹ̀ ni!” Bó ṣe mú ìwé tuntun náà, Children, jáde nìyẹn o, ni àtẹ́wọ́ bá tún sọ wàá-wàá-wàá fúngbà pípẹ́.
Lẹ́yìn àsọyé tó wúni lórí yìí ni àwọn ọmọdé tò lọ bí ilẹ̀ bí ẹní, tí wọ́n ń rìn lọ sórí pèpéle níbi tí Arákùnrin Rutherford ti ń fún wọn ní ẹ̀bùn ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ìwé tuntun náà. Ìran náà mú kí omi jáde lójú àwọn tó wà láwùjọ. Ẹnì kan tí ọ̀ràn náà ṣojú rẹ̀ sọ pé: “Kìkì ẹni tó bá lọ́kàn òkúta nìkan ni orí rẹ̀ kò ní wú bó ṣe ń wo àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n [ń fi] ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jèhófà, Ọlọ́run [hàn].”
Níbi àpéjọpọ̀ mánigbàgbé yẹn, ọgọ́rùn-ún dín légbèje [1,300] àwọn ọ̀dọ́ ló ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí àmì ìyàsímímọ́ wọn sí Jèhófà. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló dúró gbọ́n-in nínú ìgbàgbọ́ títí di báa ti ń wí yìí. Wọ́n ń ṣe ìtìlẹ́yìn fún ìjọ tí wọ́n wà, wọ́n ń yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì, tàbí kí wọ́n máa sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì nílẹ̀ òkèèrè. Láìṣe àní-àní, “Ọjọ́ Àwọn Ọmọdé” àti ìwé Children wọ ọ̀pọ̀ ọmọdé lọ́kàn ṣinṣin!
“Ó Dà Bíi Pé Wọ́n Ń Dé Lásìkò Tó Yẹ Gan-an”
Láwọn ọdún 1970, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún tẹ ìwé mẹ́ta mìíràn jáde, èyí tó fa ẹgbàágbèje àwọn ọ̀dọ́ mọ́ra. Àwọn ìwé wọ̀nyí ni Fifetisilẹ si Olukọ Nla Na, Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, àti Iwe Itan
Bibeli Mi. Ní 1982, ọ̀wọ́ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” bẹ̀rẹ̀ sí jáde nínú ìwé ìròyìn Jí! Àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí ru ìfẹ́ tọmọdé tàgbà sókè. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan sọ pé: “Alaalẹ́ ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé a tẹ̀ wọ́n jáde.” Ọmọ ọdún mẹ́tàlá kan sọ pé: “Mo fẹ́ràn àwọn àpilẹ̀kọ náà, ó dà bíi pé wọ́n ń dé lásìkò tó yẹ gan-an.” Àwọn òbí àtàwọn Kristẹni alàgbà táa yàn sípò gbà pé àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí bọ́ sásìkò, wọ́n sì ṣàǹfààní.Nígbà tó fi máa di ọdún 1989, nǹkan bí igba [200] àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ló ti jáde nínú Jí! A sì mú ìwé náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, jáde ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìfọkànsìn Oníwà-bí-Ọlọ́run” táa ṣe ní ọdún yẹn. Ǹjẹ́ ó ti ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́? Àwọn ọ̀dọ́ mẹ́ta kọ̀wé pé: “Ìwé yìí ti jẹ́ àgbàyanu dúkìá fún wa láti lóye àwọn ìṣòro wa, ká sì mọ báa ṣe ń kojú wọn. Ẹ ṣeun fún gbogbo ìsapá tí ẹ̀ ń ṣe fún ire wa.” Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó kà á jákèjádò ayé ló gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.
“Ó Ti Lé Ebi Tó Ń Pa Wá Lọ”
Nígbà tó tún di ọdún 1999, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pèsè ìtọ́ni mìíràn tó bọ́ sásìkò fún àwọn ọ̀dọ́—ìyẹn ni fídíò Young People Ask—How Can I Make Real Friends? Inú àwọn èèyàn dùn sí i gan-an, wọ́n sì fi tìtaratìtara dáhùn. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan sọ pé: “Fídíò yìí ní ipa tó ga lórí mi.” Ìyá kan tó ń dá tọ́mọ sọ pé: “Yóò jẹ́ ara oúnjẹ tẹ̀mí táa óò máa jẹ déédéé.” Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan sọ pé: “Ó mọ́kàn mi yọ̀ láti mọ̀ pé Jèhófà, tó jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ jù lọ, dìídì nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀dọ́, ó sì ń bìkítà fún wọn nínú ètò àjọ rẹ̀ jákèjádò ayé.”
Kí ni fídíò náà ti ṣe láṣeyọrí? Àwọn ọ̀dọ́ sọ pé: “Ó ti ràn mí lọ́wọ́ láti mọ irú àwọn tí màá máa bá kẹ́gbẹ́, láti wá ọ̀rẹ́ kún ọ̀rẹ́ nínú ìjọ, àti láti fi Jèhófà ṣe ọ̀rẹ́ mi.” “Ó ti ràn mí lọ́wọ́ láti borí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe.” “Ó ti jẹ́ kí n dúró gbọ́n-in sórí ìpinnu mi láti fi gbogbo agbára mi sin Jèhófà.” Tọkọtaya kan tún kọ̀wé pé: “A fi tọkàntọkàn dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún pípèsè ‘oúnjẹ’ yìí fún wa. Ó ti lé ebi tó ń pa wá lọ.”
Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wọn, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” táa fòróró yàn ti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí lásìkò fún gbogbo àwọn tó bá ṣe tán láti tẹ́wọ́ gbà á. Ẹ ò rí i bó ṣe múnú wa dùn tó láti rí i bí irú ìtọ́ni bẹ́ẹ̀ látinú Ìwé Mímọ́ ṣe ń ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ lónìí láti ‘dúró lọ́nà pípé pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run’!