Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìjọsìn Tòótọ́ Ń So Àwọn Èèyàn Pọ̀ Ṣọ̀kan

Ìjọsìn Tòótọ́ Ń So Àwọn Èèyàn Pọ̀ Ṣọ̀kan

Ìjọsìn Tòótọ́ Ń So Àwọn Èèyàn Pọ̀ Ṣọ̀kan

BÓ TILẸ̀ jẹ́ pé ìsìn lápapọ̀ máa ń pín aráyé níyà ni, ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà ní agbára láti so àwọn èèyàn pọ̀ ṣọ̀kan. Nígbà tí Ọlọ́run fi Ísírẹ́lì ṣe àyànfẹ́ orílẹ̀-èdè, ọ̀pọ̀ àwọn Kèfèrí tó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn ló fìfẹ́ hàn sí ìjọsìn tòótọ́. Fún àpẹẹrẹ, Rúùtù fi àwọn ọlọ́run tí wọ́n ń sìn ní Móábù ìlú rẹ̀ sílẹ̀, ó sì sọ fún Náómì pé: “Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.” (Rúùtù 1:16) Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, àwọn tó pọ̀ gan-an lára àwọn Kèfèrí ti di olùjọsìn Ọlọ́run tòótọ́. (Ìṣe 13:48; 17:4) Lẹ́yìn náà, nígbà tí àwọn àpọ́sítélì Jésù bẹ̀rẹ̀ sí mú ìhìn rere náà lọ sí àwọn ibi jíjìnnà réré, àwọn mìíràn tó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ náà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ [ti] yí padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run kúrò nínú òrìṣà yín láti sìnrú fún Ọlọ́run tòótọ́ àti alààyè.” (1 Tẹsalóníkà 1:9) Ǹjẹ́ ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ náà ní irú agbára tí ń soni pọ̀ ṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ lónìí?

Àwọn oníyèméjì kọ̀ jálẹ̀ pé ó lòdì láti máa sọ̀rọ̀ nípa “ìjọsìn tòótọ́” tàbí “Ọlọ́run tòótọ́.” Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ní irú èrò yẹn nítorí pé wọn ò mọ orísun èyíkéyìí tí wọ́n ti lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ṣùgbọ́n àwọn olùwá òtítọ́ kiri, tí wọ́n ti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wá ti wá mọ̀ pé ìjọsìn kì í ṣe ọ̀ràn èyí wù-mí-ò-wù-ọ́. Ẹnì kan ṣoṣo tó yẹ ká máa jọ́sìn ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo—Jèhófà Ọlọ́run. (Ìṣípayá 4:11) Òun ni Ọlọ́run tòótọ́, òun ló sì lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ bó ṣe yẹ ká máa jọ́sìn òun.

Jèhófà ti tipasẹ̀ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá wa sọ̀rọ̀, kí a lè mọ ohun tó ń béèrè lọ́wọ́ wa. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ẹni tó wà láyé lónìí ló láǹfààní àtika odindi Bíbélì tàbí apá kan rẹ̀. Láfikún sí i, Ọmọ Ọlọ́run sọ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, . . . ẹ ó . . . mọ òtítọ́.” (Jòhánù 8:31, 32) Nítorí náà, òtítọ́ ṣeé mọ̀. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olóòótọ́ ọkàn, tí wọ́n ti inú onírúurú ẹ̀sìn tó yàtọ̀ síra jáde, ló ń fìgboyà tẹ́wọ́ gba òtítọ́ yìí, a sì ń so wọ́n pọ̀ ṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́.—Mátíù 28:19, 20; Ìṣípayá 7:9, 10.

Ìṣọ̀kan Jákèjádò Ayé ní Àkókò Tiwa!

Àsọtẹ́lẹ̀ mánigbàgbé kan tó wà nínú ìwé Sefanáyà inú Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ènìyàn láti àwọn ibi tó yàtọ̀ síra yóò ṣe kóra jọ pọ̀. Ó sọ pé: “Nígbà náà ni èmi [Jèhófà Ọlọ́run] yóò fún àwọn ènìyàn ní ìyípadà sí èdè mímọ́ gaara, kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ Jèhófà, kí wọ́n lè máa sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” (Sefanáyà 3:9) Ẹ ò rí i bó ṣe wúni lórí tó, láti rí àwọn èèyàn tó ti yí padà bí wọ́n ṣe ń sin Ọlọ́run ní ìṣọ̀kan!

Ìgbà wo ni èyí yóò ṣẹlẹ̀? Sefanáyà 3:8 sọ pé: “‘Ẹ máa wà ní ìfojúsọ́nà fún mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘títí di ọjọ́ tí èmi yóò dìde sí ẹrù àkótogunbọ̀, nítorí ìpinnu ìdájọ́ mi ni láti kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ, kí n kó àwọn ìjọba jọpọ̀, kí n lè da ìdálẹ́bi tí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá jáde sórí wọn, gbogbo ìbínú jíjófòfò mi; nítorí nípa iná ìtara mi, gbogbo ilẹ̀ ayé ni a ó jẹ run.’” Bẹ́ẹ̀ ni o, láàárín àkókò tí Jèhófà fi ń kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ, ṣùgbọ́n kí ó tó tú ìbínú jíjófòfò rẹ̀ dà sórí wọn, ó fún àwọn ọlọ́kàn tútù ayé ní èdè mímọ́ gaara tí wọn óò máa sọ. Àkókò yẹn gan-an la wà yìí, nítorí pé kíkó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè ní Amágẹ́dọ́nì ti ń lọ lọ́wọ́.—Ìṣípayá 16:14, 16.

Jèhófà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní èdè mímọ́ gaara, kí ó lè so wọ́n pọ̀ ṣọ̀kan. Èdè tuntun yìí kan lílóye òtítọ́ Bíbélì nípa Ọlọ́run àtàwọn ète rẹ̀ lọ́nà tó gún régé. Sísọ èdè mímọ́ gaara náà wé mọ́ gbígba òtítọ́ gbọ́, fífi í kọ́ àwọn ẹlòmíràn, àti gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run. Ó ń béèrè pé kéèyàn yàgò fún ọ̀ràn ìṣèlú tó ń fa ìpínyà, kó sì fa ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan bíi kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tó jẹ́ ẹ̀mí ayé yìí tu kúrò lọ́kàn rẹ̀. (Jòhánù 17:14; Ìṣe 10:34, 35) Gbogbo àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ ló lè kọ́ èdè yìí. Ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn márààrún táa mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ ìṣáájú—àwọn tí ẹ̀sìn yà nípa tẹ́lẹ̀—ṣe wá di ẹni tó wà níṣọ̀kan nínú jíjọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà báyìí.

Ìjọsìn Tòótọ́ So Wọ́n Pọ̀ Ṣọ̀kan

Nígbà tí Fidelia, tó jẹ́ Roman Kátólíìkì olùfọkànsìn, ra Bíbélì tí ọmọ rẹ̀ máa lò nílé ìwé, ó ní kí àlùfáà òun fi Bíbélì náà ṣàlàyé ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ òun márààrún tó kú. Ó ní: “Ó mà já mi kulẹ̀ o!” Nítorí ìdí èyí, nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bi wọ́n ní ìbéèrè kan náà. Nígbà tó ka ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa ipò tí àwọn òkú wà nínú Bíbélì tiẹ̀ fúnra rẹ̀, ó wá mọ̀ pé ṣọ́ọ̀ṣì òun ti tan òun jẹ jìnnà. Ó wá mọ̀ pé àwọn òkú kò mọ ohunkóhun, nítorí náà kò sí ọ̀rọ̀ pé wọ́n ń jìyà ní Limbo tàbí níbikíbi. (Sáàmù 146:4; Oníwàásù 9:5) Bí Fidelia ṣe kó gbogbo ère rẹ̀ sọnù nìyẹn, tó fi ṣọ́ọ̀ṣì ọ̀hún sílẹ̀, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (1 Jòhánù 5:21) Ọdún kẹwàá rèé tó ti ń gbádùn fífi òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ kọ́ àwọn ẹlòmíràn.

Tara tó wá láti Kathmandu kó lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, níbi tí tẹ́ńpìlì àwọn Híńdù kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí. Ìyẹn ló jẹ́ kó lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì kan pẹ̀lú ìrètí láti tẹ́ àìní rẹ̀ nípa tẹ̀mí lọ́rùn. Àmọ́ kò rí ìdáhùn sí ìbéèrè rẹ̀ nípa ìyà tó ń jẹ ìran ènìyàn. Ẹ̀yìn ìyẹn ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn sí i, tí wọ́n sọ pé àwọn óò bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tara sọ pé: “Mo wá mọ̀ pé kò lè jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ ló ń ṣokùnfà gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé . . . Inú mi dùn gan-an pé a lè fojú sọ́nà fún ayé tuntun tí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan máa wà.” (Ìṣípayá 21:3, 4) Tara kó gbogbo ère Híńdù rẹ̀ sọnù, ó jáwọ́ nínú títẹ̀lé àwọn àṣà ìsìn ilẹ̀ ìbílẹ̀ rẹ̀, ó sì rí ojúlówó ayọ̀ nínú ṣíṣèrànwọ́ láti tẹ́ àìní àwọn ẹlòmíràn nípa tẹ̀mí lọ́rùn gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Aláfọ̀ṣẹ ni Panya tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Búdà nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́kọ́ kàn sí i ní Bangkok. Ìdí nìyẹn tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì fi fà á lọ́kàn mọ́ra. Panya sọ pé: “Nígbà tí mo gbọ́ ìdí tí ipò nǹkan òde òní fi yàtọ̀ sí bí Ẹlẹ́dàá ṣe pète rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àti bó ti ṣe ṣètò láti ṣàtúnṣe ohun tí àwọn tó kọ òun àti ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ sílẹ̀ ti bà jẹ́, ńṣe ló dà bí ẹni pé a ṣí agọ̀ kan kúrò lójú mi. Gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì ló fohùn ṣọ̀kan látòkèdélẹ̀. Mo wá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan; èyí ló wá sún mi láti ṣe ohun tí mo mọ̀ pé ó tọ́. Mo wá ń hára gàgà láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọgbọ́n ènìyàn àti ọgbọ́n Ọlọ́run. Ọgbọ́n tòótọ́ ti yí ìgbésí ayé mi padà pátápátá.”

Bí àkókò ti ń lọ, Virgil bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì nípa àwọn ohun tí ẹ̀sìn rẹ̀ gbà gbọ́. Dípò tí ì bá fi máa gbàdúrà sí Ọlọ́run láti ran àwọn adúláwọ̀ lọ́wọ́, kí ó tún máa gbàdúrà fún ètò àjọ tó kà sí ti ẹlẹ́yàmẹ̀yà tó dà bíi pé bí wọ́n ṣe máa kórìíra àwọn aláwọ̀ funfun ni olórí ète wọn, ńṣe ló gbàdúrà pé kí òun rí òtítọ́, ohun yòówù kó jẹ́, àti ibi yòówù kó wà. Virgil sọ pé: “Nígbà tí mo jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, lẹ́yìn àdúrà tí mo fi taratara gbà sí Ọlọ́run, mo rí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ kan nínú ilé. . . . Ó ní láti jẹ́ pé abẹ́ ilẹ̀kùn ni wọ́n gbà kì í sínú ilé.” Láìpẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Fún ìgbà àkọ́kọ́ láyé mi, ọkàn mi balẹ̀. . . . Ìmọ́lẹ̀ ìrètí bẹ̀rẹ̀ sí tàn nínú mi.” Kò pẹ́ tí Virgil fi bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń fún àwọn ènìyàn ní ìrètí tòótọ́ kan ṣoṣo náà gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Inú Charo tó wá láti Látìn Amẹ́ríkà dùn gan-an nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gladys rí i pé ó níṣòro pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ kéékèèké, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ràn án lọ́wọ́, tó ń mú un lọ sí ọjà. Bí àkókò ti ń lọ, Charo tẹ́wọ́ gba ohun tí Gladys fi lọ̀ ọ́—ìyẹn ni kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé lọ́fẹ̀ẹ́. Ó ya Charo lẹ́nu gan-an nígbà tó rí i nínú Bíbélì tiẹ̀ fúnra rẹ̀ pé kì í ṣe gbogbo ẹni rere ló ń lọ sí ọ̀run, àmọ́ pé Jèhófà yóò tún fi ìyè àìnípẹ̀kun jíǹkí àwọn ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:11, 29) Charo alára ti ń sọ ìrètí yìí fún àwọn ẹlòmíràn láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn.

Fojú inú wò ó ná, kí gbogbo ayé kún fún àwọn olóòótọ́ ènìyàn, tí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan nínú jíjọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà! Èyí kì í ṣe àlá lásán. Ohun tí Jèhófà ti ṣèlérí ni. Ọlọ́run tipasẹ̀ Sefanáyà, wòlíì rẹ̀ kéde pé: “Dájúdájú, èmi yóò sì jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni rírẹlẹ̀ ṣẹ́ kù sí àárín rẹ, wọn yóò sì sá di orúkọ Jèhófà ní ti tòótọ́. . . . Wọn kì yóò ṣe àìṣòdodo, tàbí kí wọ́n pa irọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò rí ahọ́n àgálámàṣà ní ẹnu wọn; . . . kò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.” (Sefanáyà 3:12, 13) Bí ìlérí yìí bá fà ọ́ lọ́kàn mọ́ra, fi ọ̀rọ̀ ìyànjú inú Bíbélì náà sọ́kàn pé: “Ẹ wá Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé, tí ń fi ìpinnu ìdájọ́ Tirẹ̀ ṣe ìwà hù. Ẹ wá òdodo, ẹ wá ọkàn-tútù. Bóyá a lè pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.”—Sefanáyà 2:3.