Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbùkún Jèhófà Yóò Ha Dé Bá Ọ Bí?

Ìbùkún Jèhófà Yóò Ha Dé Bá Ọ Bí?

Ìbùkún Jèhófà Yóò Ha Dé Bá Ọ Bí?

“Gbogbo ìbùkún wọ̀nyí yóò sì wá sórí rẹ, yóò sì dé bá ọ, nítorí pé ìwọ ń bá a nìṣó láti máa fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ.”—DIUTARÓNÓMÌ 28:2.

1. Kí ni yóò pinnu bóyá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò gba ìbùkún tàbí ìfiré?

 ÀWỌN ọmọ Ísírẹ́lì pabùdó sí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù nígbà tí ogójì ọdún tí wọ́n fi rìn ní aginjù ń parí lọ. Ilẹ̀ Ìlérí rèé lọ́ọ̀ọ́kán wọn. Àkókò yìí ni Mósè kọ ìwé Diutarónómì, tó ní ọ̀pọ̀ ìbùkún àti ìfiré, ìyẹn ègún, nínú. Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá “ń bá a nìṣó láti máa fetí sí ohùn Jèhófà” nípa ṣíṣègbọràn sí i, ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò “dé bá” wọn. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí “àkànṣe dúkìá” rẹ̀, ó sì fẹ́ gbèjà wọn. Àmọ́ bí wọ́n bá dẹ́kun fífetí sí i, ó dájú pé ìfiré yóò dé bá wọn.—Diutarónómì 8:10-14; 26:18; 28:2, 15.

2. Kí ni ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù táa tú sí “bá a nìṣó láti máa fetí sí” àti “dé bá” nínú Diutarónómì 28:2?

2 Ọ̀rọ̀ Hébérù táa tú sí “bá a nìṣó láti máa fetí sí” nínú Diutarónómì 28:2 fi hàn pé ohun tí à ń ṣe nìṣó ni. Kì í ṣọ̀ràn kí àwọn èèyàn Jèhófà wulẹ̀ máa fetí sí i lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan; wọ́n gbọ́dọ̀ máa fetí sí i ní gbogbo ìgbà. Ìyẹn nìkan ni àwọn ìbùkún Ọlọ́run fi lè dé bá wọn. Ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù táa tú sí “dé bá” jẹ mọ́ ṣíṣọdẹ, ó sábà máa ń túmọ̀ sí “láti lé bá” tàbí “láti kàn lára.”

3. Báwo la ṣe lè dà bíi Jóṣúà, èé sì ti ṣe tí èyí fi ṣe pàtàkì gan-an?

3 Jóṣúà, aṣáájú Ísírẹ́lì, yàn láti fetí sí Jèhófà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà. Jóṣúà sọ pé: “Lónìí yìí, ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin yóò máa sìn fún ara yín . . . Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.” Látàrí ìyẹn, àwọn èèyàn náà fèsì pé: “Kò ṣeé ronú kàn fún àwa, láti fi Jèhófà sílẹ̀ láti lè sin àwọn ọlọ́run mìíràn.” (Jóṣúà 24:15, 16) Nítorí ìṣarasíhùwà rere tí Jóṣúà ní, ó wà lára àwọn díẹ̀ nínú ìran rẹ̀ tó láǹfààní àtiwọ Ilẹ̀ Ìlérí. Lónìí, a wà ní bèbè Ilẹ̀ Ìlérí kan tí kò láfiwé—èyíinì ni Párádísè ilẹ̀ ayé níbi tí àwọn ìbùkún jìngbìnnì tó pọ̀ ju èyí tó wà nígbà ayé Jóṣúà ti ń dúró de gbogbo àwọn tí Ọlọ́run ṣojú rere sí. Ǹjẹ́ ìbùkún wọ̀nyí yóò dé bá ọ? Bẹ́ẹ̀ ni, yóò dé bá ọ, bóo bá ń fetí sí Jèhófà. Kí ìpinnu rẹ láti fetí sí Jèhófà lè túbọ̀ lágbára, gbé ìtàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì àti àpẹẹrẹ àtàtà táwọn kan fi lélẹ̀ yẹ̀ wò.—Róòmù 15:4.

Ìbùkún Tàbí Ègún?

4. Kí ni Ọlọ́run fún Sólómọ́nì nígbà tó gbọ́ àdúrà rẹ̀, ojú wo ló sì yẹ ká fi wo irú àwọn ìbùkún bẹ́ẹ̀?

4 Ní èyí tó pọ̀ jù lọ nígbà àkóso Sólómọ́nì Ọba, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí ìbùkún yàbùgà-yabuga gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà. Wọ́n ní ààbò àtàwọn ohun rere lọ́pọ̀ yanturu. (1 Àwọn Ọba 4:25) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sólómọ́nì wá di olókìkí nítorí ọrọ̀ tó ní, kì í ṣe pé ó fẹnu ara rẹ̀ tọrọ ọrọ̀ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, tí kò tíì ní ìrírí, ohun tó béèrè fún ni àyà ìgbàṣe—Jèhófà gbọ́ àdúrà rẹ̀, ó sì fi ọgbọ́n àti òye jíǹkí rẹ̀. Èyí ló jẹ́ kí Sólómọ́nì mọ bó ṣe yẹ kóun ṣàkóso àwọn èèyàn náà, tó sì mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run tún fún un ní ọlá àti ọlà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, Sólómọ́nì fojú ribiribi wo ọrọ̀ tẹ̀mí. (1 Àwọn Ọba 3:9-13) Yálà olówó ni wá tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, a mà dúpẹ́ o, pé a ń gbádùn ìbùkún Jèhófà, táa sì jẹ́ ọlọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí!

5. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti Júdà kùnà láti fetí sí Jèhófà?

5 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò mọrírì ìbùkún Jèhófà. Àwọn ègún táa sọ tẹ́lẹ̀ sì dé bá wọn nítorí pé wọ́n dẹ́kun fífetí sí i. Ìyẹn ló jẹ́ káwọn ọ̀tá ṣẹ́gun wọn, tí ìjọba Ísírẹ́lì àti Júdà sì fi lọ sígbèkùn. (Diutarónómì 28:36; 2 Àwọn Ọba 17:22, 23; 2 Kíróníkà 36:17-20) Ǹjẹ́ ìyà yẹn kọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́gbọ́n, pé àwọn tó bá ń fetí sí Jèhófà nìkan ni àwọn ìbùkún àtọ̀runwá máa ń dé bá? Àṣẹ́kù àwọn Júù tó padà dé sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa ní àǹfààní láti fi hàn bóyá àwọn ti jèrè “ọkàn-àyà ọgbọ́n,” tí wọ́n sì ti rí ìjẹ́pàtàkì fífetí sí Ọlọ́run.—Sáàmù 90:12.

6. (a) Èé ṣe tí Jèhófà fi rán Hágáì àti Sekaráyà pé kí wọ́n lọ sọ àsọtẹ́lẹ̀ fáwọn èèyàn òun? (b) Ìlànà wo ni iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi rán Hágáì fìdí rẹ̀ múlẹ̀?

6 Àwọn Júù tó ti ìgbèkùn dé mọ pẹpẹ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. Ṣùgbọ́n nígbà tí àtakò gbígbóná janjan dé, wọ́n dẹwọ́, iṣẹ́ ìkọ́lé náà sì dáwọ́ dúró. (Ẹ́sírà 3:1-3, 10; 4:1-4, 23, 24) Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí lépa fàájì. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi rán wòlíì Hágáì àti wòlíì Sekaráyà pé kí wọ́n lọ ta àwọn èèyàn òun jí, kí wọ́n lè káràmáásìkí ìjọsìn tòótọ́. Jèhófà gbẹnu Hágáì sọ pé: “Àkókò ha nìyí fún ẹ̀yin láti máa gbé nínú àwọn ilé yín tí a fi igi pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí, nígbà tí ilé [ìjọsìn] yìí wà ní ipò ahoro? . . . Ẹ fi ọkàn-àyà yín sí àwọn ọ̀nà yín. Ẹ ti fún irúgbìn púpọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni ẹ ń mú wọlé. Ẹ ń jẹun, ṣùgbọ́n kì í ṣe ní àjẹyó. . . . Ẹni tí ó sì ń fi ara rẹ̀ háyà ń fi ara rẹ̀ háyà fún àpò tí ó ní àwọn ihò.” (Hágáì 1:4-6) Fífọwọ́ rọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí sẹ́yìn ká lè ráyè lépa àwọn nǹkan tara kì í yọrí sí ìbùkún Jèhófà.—Lúùkù 12:15-21.

7. Èé ṣe tí Jèhófà fi sọ fáwọn Júù pé: “Ẹ fi ọkàn-àyà yín sí àwọn ọ̀nà yín”?

7 Àníyàn ojoojúmọ́ tó gba àwọn Júù lọ́kàn kò jẹ́ kí wọ́n rántí mọ́ pé, àyàfi bí wọ́n bá ń bá a nìṣó ní ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run, láìfi àtakò pè, ni Ọlọ́run yóò fi fún wọn ní òjò, tí irè oko wọn yóò sì so àsokún. (Hágáì 1:9-11) Nítorí náà, ẹ ò rí i pé wẹ́kú ni ọ̀rọ̀ ìyànjú náà ṣe, pé: “Ẹ fi ọkàn-àyà yín sí àwọn ọ̀nà yín”! (Hágáì 1:7) Lọ́rọ̀ mìíràn, ohun tí Jèhófà ń sọ fún wọn ni pé: ‘Ẹ ronú! Ó yẹ kẹ́ẹ mọ̀ pé ilé ìjọsìn mi tó dahoro ni kò jẹ́ kẹ́ẹ kórè oko délé.’ Níkẹyìn, ọ̀rọ̀ ìmísí táwọn wòlíì Jèhófà sọ wọ àwọn olùgbọ́ wọn lọ́kàn, wọ́n padà sẹ́nu iṣẹ́ tẹ́ńpìlì náà, wọ́n sì kọ́ ọ tán lọ́dún 515 ṣááju Sànmánì Tiwa.

8. Ọ̀rọ̀ ìyànjú wo ni Jèhófà fún àwọn Júù nígbà ayé Málákì, èé sì ti ṣe?

8 Nígbà tó tún ṣe, nígbà ayé wòlíì Málákì, ni àwọn Júù bá tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ẹsẹ̀ kan ilé, ẹsẹ̀ kan òde, nípa tẹ̀mí, àní wọ́n tiẹ̀ ń mú ọrẹ gbà-má-pa-mí-jẹ wá fún Ọlọ́run pàápàá. (Málákì 1:6-8) Ìyẹn ló jẹ́ kí Jèhófà gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n mú ìdámẹ́wàá wọn wá sínú ilé òun, kí wọ́n sì dán òun wò, bóyá òun kò ní ṣí ibodè ọ̀run sílẹ̀ fún wọn, kí òun sì rọ̀jò ìbùkún sórí wọn títí kò fi ní sí àìní mọ́. (Málákì 3:10) Àwọn Júù wọ̀nyẹn mà gọ̀ o, wọ́n lọ ń ṣe làálàá àṣekúdórógbó nítorí àwọn ohun náà gan-an tí Ọlọ́run ti sọ pé òun máa pèsè fún wọn lọ́pọ̀ yanturu, bí wọ́n bá sáà ń bá a nìṣó ní fífetí sí ohùn òun!—2 Kíróníkà 31:10.

9. Ìtàn àwọn mẹ́ta wo la fẹ́ gbé yẹ̀ wò nínú Bíbélì?

9 Ní àfikún sí ìtàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó wà nínú Bíbélì, ìtàn ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó gba ìbùkún tàbí ègún látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ń bẹ níbẹ̀ pẹ̀lú, gbogbo rẹ̀ sinmi lórí bóyá wọ́n ń bá a nìṣó ní fífetí sí Jèhófà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ẹ jẹ́ ká wo ẹ̀kọ́ táa lè rí kọ́ nínú ìtàn èèyàn mẹ́ta lára wọn—ìyẹn Bóásì, Nábálì, àti Hánà. Láti mọ̀ sí i nípa àwọn aráabí yìí, á dáa kóo ka ìwé Rúùtù àti 1 Sámúẹ́lì 1:1–2:21 àti 1 Sámúẹ́lì 25:2-42.

Bóásì Fetí sí Ọlọ́run

10. Kí ló bára mu nínú ìgbésí ayé Bóásì àti ti Nábálì?

10 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ìgbà kan náà ni Bóásì àti Nábálì jọ gbáyé, ìgbésí ayé wọ́n bára mu láwọn ọ̀nà kan. Fún àpẹẹrẹ, ilẹ̀ Júdà làwọn méjèèjì gbé. Wọ́n lówó, wọ́n sì tún ní ilẹ̀ rẹpẹtẹ. Àwọn méjèèjì sì ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti ṣojú àánú sí aláìní. Ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n fi bára wọn mu kò jùyẹn lọ.

11. Báwo ni Bóásì ṣe fi hàn pé òun ń fetí sí Jèhófà?

11 Bóásì gbé ayé nígbà táwọn onídàájọ́ ń ṣàkóso Ísírẹ́lì. Ó máa ń fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n, ó sì níyì gan-an lójú àwọn tó ń bá a kórè. (Rúùtù 2:4) Bóásì ṣègbọràn sí Òfin, ó rí i dájú pé èéṣẹ́ wà lóko òun fáwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àtàwọn òtòṣì. (Léfítíkù 19:9, 10) Kí ni Bóásì ṣe nígbà tó gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Rúùtù àti Náómì, tó sì rí akitiyan Rúùtù láti tọ́jú ìyá ọkọ rẹ̀ tó ti darúgbó? Àánú Rúùtù ṣe é gan-an, ó sì pàṣẹ fáwọn ọkùnrin tó ń bá a ṣiṣẹ́ pé kí wọ́n jẹ́ kó máa pèéṣẹ́ lóko òun. Nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe onífẹ̀ẹ́, Bóásì fi hàn pé ẹni tẹ̀mí tó ń fetí sí Jèhófà lòun. Nítorí náà, ó rí ojú rere àti ìbùkún Ọlọ́run.—Léfítíkù 19:18; Rúùtù 2:5-16.

12, 13. (a) Báwo ni Bóásì ṣe fi hàn pé òun fọwọ́ pàtàkì mú òfin Jèhófà nípa ìtúnnirà? (b) Àwọn ìbùkún àtọ̀runwá wo ló dé bá Bóásì?

12 Ẹ̀rí títayọ tó fi hàn pé Bóásì ń fetí sí Jèhófà ni bó ṣe fi àìmọtara-ẹni-nìkan tẹ̀ lé òfin tí Ọlọ́run ṣe nípa ìtúnnirà. Bóásì sa gbogbo ipá rẹ̀ láti rí i dájú pé ogún ìbátan òun—Elimélékì ọkọ Náómì tó ti dolóògbé—kò ní kúrò nínú ìdílé Elimélékì. Nípasẹ̀ ètò ‘opó ṣíṣú,’ opó kan yóò fẹ́ ẹbí ọkọ rẹ̀ olóògbé, kí ogún ìdílé náà lè di ti ọmọkùnrin tí wọ́n bá bí. (Diutarónómì 25:5-10; Léfítíkù 25:47-49) Rúùtù yọ̀ǹda kí wọ́n fẹ́ òun ṣaya ní ipò Náómì tó ti darúgbó, tí kò sì lè bímọ mọ́. Lẹ́yìn tí ìbátan tó sún mọ́ Elimélékì jù kọ̀ láti ran Náómì lọ́wọ́, Bóásì gbà láti fi Rúùtù ṣaya. Ọmọkùnrin wọn Óbédì ni wọ́n kà sí ọmọ Náómì, ó sì lẹ́tọ̀ọ́ sí ogún Elimélékì.—Rúùtù 2:19, 20; 4:1, 6, 9, 13-16.

13 Ìbùkún jìngbìnnì dé bá Bóásì nítorí pé ó fi àìmọtara-ẹni-nìkan tẹ̀ lé òfin Ọlọ́run. Nípasẹ̀ Óbédì ọmọkùnrin wọn, Bóásì àti Rúùtù láǹfààní dídi bàbá àti ìyá ńlá Jésù Kristi. (Rúùtù 2:12; 4:13, 21, 22; Mátíù 1:1, 5, 6) Ìwà àìmọtara-ẹni-nìkan Bóásì fi hàn pé ọ̀pọ̀ ìbùkún máa ń dé bá àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ ẹlòmíràn, tí wọ́n sì ṣe ohun tí Ọlọ́run béèrè.

Nábálì Kò Fetí Sílẹ̀

14. Irú èèyàn wo ni Nábálì?

14 Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí Bóásì, Nábálì kọ̀ láti fetí sí Jèhófà. Ó rú òfin Ọlọ́run tó sọ pé: “Kí ìwọ . . . nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Léfítíkù 19:18) Nǹkan tẹ̀mí kò jẹ Nábálì lógún; ó sì “burú ní àwọn ìṣe rẹ̀.” Àní “ọkùnrin tí kò dára fún ohunkóhun” làwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kà á sí. Orúkọ ló ń rò ó, nítorí pé orúkọ rẹ̀ Nábálì túmọ̀ sí “òpònú,” tàbí “arìndìn.” (1 Sámúẹ́lì 25:3, 17, 25) Báwo wá ni Nábálì ṣe hùwà nígbà tó láǹfààní láti ṣojú àánú sí ẹnì kan tó nílò ìrànlọ́wọ́—ìyẹn Dáfídì, ẹni àmì òróró Jèhófà?—1 Sámúẹ́lì 16:13.

15. Irú ìwà wo ni Nábálì hù sí Dáfídì, báwo sì ni Ábígẹ́lì ṣe yàtọ̀ sí ọkọ rẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí?

15 Nígbà tí Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀ pabùdó sí sàkáání ibi tí agbo ẹran Nábálì wà, wọ́n dáàbò bo agbo náà lọ́wọ́ àwọn onísùnmọ̀mí, láìgba ohunkóhun. Ọ̀kan lára darandaran Nábálì tiẹ̀ sọ pé: “Ògiri ni wọ́n jẹ́ yí wa ká ní òru àti ní ọ̀sán.” Àmọ́ o, nígbà tí àwọn ońṣẹ́ Dáfídì wá béèrè fún oúnjẹ, ńṣe ni Nábálì “fi ìkanra sọ̀rọ̀ sí wọn,” ó sì dá wọn padà lọ́wọ́ òfo. (1 Sámúẹ́lì 25:2-16) Ábígẹ́lì, aya Nábálì, kò fọ̀ràn falẹ̀ rárá, ojú ẹsẹ̀ ló kó oúnjẹ lọ fún Dáfídì. Inú bí Dáfídì gan-an, ó sì ṣe tán láti run Nábálì tilétilé. Ìgbésẹ̀ tí Ábígẹ́lì gbé ló gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn là, tí kò sì jẹ́ kí Dáfídì jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Ṣùgbọ́n ojúkòkòrò àti ìwà òṣónú Nábálì ti pọ̀ jù. Nǹkan bí ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn náà ni “Jèhófà . . . kọlu Nábálì, tí ó fi kú.”—1 Sámúẹ́lì 25:18-38.

16. Báwo la ṣe lè fara wé Bóásì, ká sì yàgò fún ìwà Nábálì?

16 Ìyàtọ̀ àárín Bóásì àti Nábálì mà pọ̀ o! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ ká yẹra fún ìwà òṣónú àti ìmọtara-ẹni-nìkan Nábálì, ẹ jẹ́ ka fara wé inú rere àti ìwà àìmọtara-ẹni-nìkan Bóásì. (Hébérù 13:16) A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa fífi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sílò, pé: “Níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Lónìí, “àwọn àgùntàn mìíràn” Jésù, ìyẹn àwọn Kristẹni tó ní ìrètí láti wà lórí ilẹ̀ ayé, ní àǹfààní láti ṣe rere sí àwọn ẹni àmì òróró Jèhófà, ìyẹn àṣẹ́kù àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, tí a óò fún ní àìleèkú ní ọ̀run. (Jòhánù 10:16; 1 Kọ́ríńtì 15:50-53; Ìṣípayá 14:1, 4) Jésù kà á sí pé òun alára ni wọ́n ń ṣe irú iṣẹ́ rere bẹ́ẹ̀ fún, ṣíṣe nǹkan rere wọ̀nyí sì máa ń yọrí sí ìbùkún jìngbìnnì látọ̀dọ̀ Jèhófà.—Mátíù 25:34-40; 1 Jòhánù 3:18.

Àwọn Àdánwò àti Ìbùkún Hánà

17. Àwọn àdánwò wo ni Hánà dojú kọ, ẹ̀mí wo ló sì fi gbà á?

17 Ìbùkún Jèhófà náà tún dé bá Hánà olùfọkànsin Ọlọ́run. Àgbègbè olókè ńláńlá Éfúráímù lobìnrin yìí àti Ẹlikénà ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ Léfì ń gbé. Ẹlikénà ní ìyàwó mìíràn tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pẹ̀nínà, nítorí pé Òfin Mósè gba ìyẹn láyè. Hánà yàgàn, nǹkan ẹ̀gàn sì nìyí fún obìnrin èyíkéyìí ní Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n Pẹ̀nínà ní tirẹ̀ ní àwọn ọmọ. (1 Sámúẹ́lì 1:1-3; 1 Kíróníkà 6:16, 33, 34) Àmọ́ dípò kí Pẹ̀nínà máa tu Hánà nínú, ńṣe ló ń fòòró ẹ̀mí rẹ̀, débi pé Hánà á bẹ̀rẹ̀ sì sunkún, kò sì ní lè jẹun. Ó tún wá lọ jẹ́ pé bó ṣe ń ṣẹlẹ̀ nìyẹn “lọ́dọọdún,” ní gbogbo ìgbà tí ìdílé náà bá lọ sílé Jèhófà ní Ṣílò. (1 Sámúẹ́lì 1:4-8) Pẹ̀nínà yìí ò mà lójú àánú o! Àdánwò ńlá mà sì lèyí jẹ́ fún Hánà o! Síbẹ̀, Hánà ò dá Jèhófà lẹ́bi rí; bẹ́ẹ̀ ni kò wá tìtorí ìyẹn jókòó sílé nígbà tí ọkọ rẹ̀ bá ń lọ sí Ṣílò. Nítorí náà, ó dájú pé ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ ìbùkún máa dé bá Hánà.

18. Àpẹẹrẹ wo ni Hánà fi lélẹ̀?

18 Hánà fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn èèyàn Jèhófà lóde òní, àgàgà fáwọn tí ọ̀rọ̀ kòbákùngbé táwọn kan sọ sí wọn ti mú wọn lọ́kàn gbọgbẹ́. Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, yíya ara ẹni sọ́tọ̀ kọ́ ló máa yanjú ìṣòro náà. (Òwe 18:1) Hánà kò jẹ́ kí àwọn àdánwò rẹ̀ paná ìfẹ́ tó ní láti wà níbi táa ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, níbi táwọn èèyàn Ọlọ́run pé jọ sí fún ìjọsìn. Ìyẹn ló jẹ́ kó dúró dáadáa nípa tẹ̀mí. Àdúrà rẹ̀ àtọkànwá, tó wà nínú 1 Sámúẹ́lì 2:1-10, fi hàn pé ó dúró sán-ún nípa tẹ̀mí. a

19. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì àwọn nǹkan tẹ̀mí?

19 Àwa táa jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní kì í jọ́sìn nínú àgọ́ ìjọsìn. Síbẹ̀ a lè fi hàn pé a mọrírì àwọn nǹkan tẹ̀mí, gẹ́gẹ́ bí Hánà ti ṣe. Fún àpẹẹrẹ, a lè fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ hàn fún àwọn ọrọ̀ tẹ̀mí nípa wíwá sáwọn ìpàdé, àwọn àpéjọ, àtàwọn àpéjọpọ̀ Kristẹni déédéé. Ẹ jẹ́ ká máa lo àǹfààní wọ̀nyí láti fún ara wa lẹ́nì kìíní kejì níṣìírí nínú ìjọsìn tòótọ́ Jèhófà, ẹni tó fún wa ní “àǹfààní ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un láìbẹ̀rù pẹ̀lú ìdúróṣinṣin àti òdodo.”—Lúùkù 1:74, 75; Hébérù 10:24, 25.

20, 21. Báwo la ṣe san ẹ̀san fún Hánà nítorí ìfọkànsìn rẹ̀?

20 Jèhófà kíyè sí ìfọkànsìn Hánà, ó sì san án lérè jìngbìnnì. Nígbà kan tí ìdílé wọn lọ sí Ṣílò bí wọ́n ti ń ṣe lọ́dọọdún, Hánà bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà tọkàntọkàn sí Ọlọ́run pẹ̀lú omijé lójú, ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, láìkùnà, bí ìwọ yóò bá wo ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ ẹrúbìnrin rẹ níṣẹ̀ẹ́, tí o sì rántí mi ní ti tòótọ́, tí ìwọ kì yóò sì gbàgbé ẹrúbìnrin rẹ, tí o sì fún ẹrúbìnrin rẹ ní ọmọ tí ó jẹ́ ọkùnrin ní ti tòótọ́, èmi yóò fi í fún Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.” (1 Sámúẹ́lì 1:9-11) Ọlọ́run gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Hánà, ó fi ọmọkùnrin kan jíǹkí rẹ̀, Hánà sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sámúẹ́lì. Nígbà tó já a lẹ́nu ọmú, ó mú un lọ sí Ṣílò, kí ó lè máa sìn nínú àgọ́ ìjọsìn.—1 Sámúẹ́lì 1:20, 24-28.

21 Hánà fi hàn pé òun fẹ́ràn Ọlọ́run, ó sì mú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ fún Ọlọ́run nípa Sámúẹ́lì ṣẹ. Ẹ sì wo ìbùkún jìngbìnnì tí Hánà àti Ẹlikénà gbádùn nítorí pé ọmọ wọn ọ̀wọ́n ń sìn nínú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà! Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni òbí ló ní irú ayọ̀ àti ìbùkún yìí nítorí pé ọmọ wọn ń sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún, tàbí mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì, tàbí ní àwọn ọ̀nà mìíràn tí ń bọlá fún Jèhófà.

Máa Bá A Nìṣó Ní Fífetí sí Jèhófà!

22, 23. (a) Ìdánilójú wo la óò ní báa bá ń fetí sí ohùn Jèhófà? (b) Kí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

22 Ìdánilójú wo la óò ní báa bá ń bá a nìṣó ní fífetí sí Jèhófà? A óò jẹ́ ọlọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí báa bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn, tí ọ̀nà táa gbà ń gbé ìgbésí ayé wa bá sì fi hàn pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún un. Kódà nígbà tó bá pọndandan fún wa láti fara da àwọn àdánwò mímúná ká tó lè tọ ipa ọ̀nà yẹn, ìbùkún Jèhófà yóò dé bá wa ṣáá ni—ó sì sábà máa ń pọ̀ ju ohun táa ń retí lọ.—Sáàmù 37:4; Hébérù 6:10.

23 Òjò ìbùkún ṣì máa rọ̀ sórí àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́jọ́ iwájú. Nítorí wọ́n fetí sí Jèhófà, a óò dá “ogunlọ́gọ̀ ńlá” sí nígbà “ìpọ́njú ńlá,” wọn yóò sì máa gbádùn ayọ̀ gbígbé nínú ayé tuntun Ọlọ́run. (Ìṣípayá 7:9-14; 2 Pétérù 3:13) Ibẹ̀ ni Jèhófà yóò ti tẹ́ ìfẹ́ òdodo tó wà lọ́kàn gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́rùn. (Sáàmù 145:16) Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó kàn yóò ti fi hàn, kódà lọ́wọ́ táa wà yìí, àwọn tó ń fetí sí ohùn Jèhófà ń gba ‘àwọn ẹ̀bùn rere àti ọrẹ pípé láti òkè.’—Jákọ́bù 1:17.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ọ̀rọ̀ tí Hánà sọ jọ ọ̀rọ̀ tí Màríà ọ̀dọ́bìnrin wúńdíá náà sọ kété lẹ́yìn tó gbọ́ pé òun ló máa bí Mèsáyà náà.—Lúùkù 1:46-55.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Ẹ̀kọ́ wo ni ìtàn Ísírẹ́lì kọ́ wa nípa àwọn ìbùkún àtọ̀runwá?

• Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín Bóásì àti Nábálì?

• Báwo la ṣe lè fara wé Hánà?

• Èé ṣe tó fi yẹ ká máa bá a nìṣó ní fífetí sí ohùn Jèhófà?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Sólómọ́nì Ọba gbàdúrà fún àyà ìgbàṣe, Jèhófà sì fi ọgbọ́n jíǹkí rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Bóásì fọ̀wọ̀ wọ àwọn ẹlòmíràn, ó sì ṣàánú wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

A bù kún Hánà jìngbìnnì nítorí pé ó gbára lé Jèhófà