Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Níye Lórí Jù Lọ?

Kí Ló Níye Lórí Jù Lọ?

Kí Ló Níye Lórí Jù Lọ?

Níní ohun kan tó níye lórí gan-an lè múnú ẹni dùn. Àmọ́ kí nìyẹn lè jẹ́? Ṣé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ owó ni? Ṣé ohun ọ̀ṣọ́ tó lówó lórí tàbí tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ ni? Ṣé òkìkí àti agbára ni? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fojú ribiribi wo àwọn nǹkan wọ̀nyí. Níní àwọn nǹkan wọ̀nyí lè gbé ẹ̀mí wa ró, kó jẹ́ kí ìgbésí ayé wa túbọ̀ nítumọ̀, tàbí kó fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn èèyàn a mọyì wa, a ó sì ṣàṣeyọrí. Ǹjẹ́ a ń tiraka láti kó irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ jọ, pẹ̀lú ìrètí pé wọn óò jẹ́ ká lé góńgó wa àti àwọn ohun táa ń fojú sọ́nà fún lọ́jọ́ iwájú bá?

OHUN tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé, àwọn èèyàn máa ń mọrírì ohun tó bá yanjú àwọn àìní wọn tàbí ohun tó bá lè tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn. A máa ń mọyì àwọn ohun tó bá lè fi wá lọ́kàn balẹ̀, tó sì ń fún wa ní ìrètí ọjọ́ ọ̀la aláàbò. A ń fojú ribiribi wo àwọn nǹkan tó lè mú ìtura ojú ẹsẹ̀ wá, tó lè tù wá nínú tàbí tó lè gbé wa níyì. Síbẹ̀, gbígbé ohun táa gbà pé ó níye lórí karí ìfẹ́ ọkàn wa tó ń yí padà jẹ́ èrò kúkúrú tó ń fi àìro ti ọjọ́ ọ̀la hàn. Ní tòótọ́, ohun táa gbà pé a nílò jù lọ ló ń pinnu ohun tó níye lórí ní ti gidi.

Kí ni ohun táa nílò jù lọ? Kò sí ohunkóhun tó níye lórí láìsí ohun pàtàkì kan—ìyẹn ni ìwàláàyè. Láìsí ìwàláàyè, a óò jẹ́ aláìsí. Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì kọ̀wé pé: “Ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá . . . Kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù [sàréè gbogbo aráyé].” (Oníwàásù 9:5, 10) Bí ikú bá dé, ó di dandan ká fi gbogbo ohun táa ní sílẹ̀. Fún ìdí yìí, ohun táa nílò jù lọ ni pe ká ní ohun kan tó lè pa ìwàláàyè wa mọ́. Kí ló lè ṣèyẹn?

Kí Ló Lè Pa Ìwàláàyè Wa Mọ́?

Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Owó . . . jẹ́ fún ìdáàbòbò.” (Oníwàásù 7:12) Táa bá ní owó tó tówó lọ́wọ́, a lè ra oúnjẹ àti ilé tó dára. Owó lè jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti gbádùn rírin ìrìn àjò lọ sáwọn ibi jíjìnnà réré. Ó lè jẹ́ kí a ní àwọn ohun kòṣeémánìí nígbà tí ọjọ́ ogbó tàbí àìsàn kò bá jẹ́ kí a lè ṣiṣẹ́ mọ́. Ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú kéèyàn lówó lọ́wọ́. Síbẹ̀, owó ò lè pa ìwàláàyè wa mọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba Tímótì nímọ̀ràn pé: “Fún àwọn ọlọ́rọ̀ nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ní àṣẹ ìtọ́ni láti má ṣe jẹ́ ọlọ́kàn-gíga, kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run.” (1 Tímótì 6:17) Gbogbo owó tó wà láyé yìí kò lè ra ìwàláàyè fún wa.

Gbé ìrírí ọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hitoshi yẹ̀ wò. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú ìdílé tálákà ni wọ́n ti tọ́ Hitoshi dàgbà, ó fẹ́ fi torítọrùn sapá láti di ọlọ́rọ̀. Ó gbà pé owó lágbára gan-an débi pé ó gbà pé òun lè fowó ra ìfẹ́ àwọn ènìyàn pàápàá. Ọkùnrin kan wá wá sílé Hitoshi, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bí ó bá mọ̀ pé Jésù Kristi kú nítorí rẹ̀. Ìbéèrè yìí mú kí Hitoshi túbọ̀ fẹ́ mọ̀ sí i nítorí ó ronú pé kò sẹ́ni tó lè kú fún ènìyàn bíi tòun. Ó wá síbi àsọyé Bíbélì kan, ó sì ṣe é ní kàyéfì láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìṣílétí tó sọ pé ‘jẹ́ kí ojú rẹ mú ọ̀nà kan.’ Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé pé ojú tí ó “mú ọ̀nà kan” ni èyí tí ó ń wo ọjọ́ iwájú tó sì darí àfiyèsí sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí. (Lúùkù 11:34) Dípò tí Hitoshi ì bá fi máa wá owó lójú méjèèjì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sípò kìíní nínú ìgbésí ayé rẹ̀.

Àwọn nǹkan ìní ti ara tún lè fi wá lọ́kàn balẹ̀, kí ó sì dáàbò bò wá dé àyè kan. Níní ànító lè dín ṣíṣe àníyàn nípa àwọn ohun táa nílò lójoojúmọ́ kù. Ilé rèǹtèrente kan táa kọ́ sí àdúgbò tó fani mọ́ra lè jẹ́ kínú wa máa dùn pé a ṣàṣeyọrí. Àwọn aṣọ tó bóde mu àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ bọ̀gìnnì lè mú káwọn ẹlòmíràn máa kan sáárá sí wa.

Ìbùkún ló jẹ́ láti ‘rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára wa.’ (Oníwàásù 3:13) Níní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ sì lè mú kó ṣeé ṣe fáwọn olólùfẹ́ wa láti ‘fara balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, kí wọ́n máa jẹ, kí wọ́n máa mu, kí wọ́n sì máa gbádùn ara wọn.’ Àmọ́, ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ráńpẹ́ ni àwọn ohun ìní ti ara níye lórí mọ. Nígbà tí Jésù Kristi ń kìlọ̀ nípa ojúkòkòrò, ó sọ pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” (Lúùkù 12:15-21) Bó ti wù kí ohun ìní pọ̀ tó, kí ó sì níye lórí tó, kò lè fún wa ní ìyè.

Fún àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni Liz fẹ́. Ó ròyìn pé: “A ní ilé tó rẹwà àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ méjì, báa sì ṣe lówó tó fún wa láǹfààní àtigbádùn ohunkóhun téèyàn lè fowó rà nínú ayé yìí. . . . Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu pé, síbẹ̀síbẹ̀ mo tún máa ń ṣàníyàn nípa owó.” Ó wá ṣàlàyé pé: “A ti pàdánù ohun púpọ̀. Ó dà bíi pé bóo bá ṣe ní nǹkan tó ni wàá máa rí i pé ààbò tóo ní kò tó.”

Òkìkí àti agbára tún jẹ́ ohun tó níye lórí gan-an lójú ọ̀pọ̀ ènìyàn nítorí pé wọ́n lè mú ìyìn àti ọlá wá. Nínú ayé òde oní, iṣẹ́ tó gbéni dépò ọlá jẹ́ àṣeyọrí kan táwọn èèyàn lè jowú. Níní àwọn ẹ̀bùn tàbí òye iṣẹ́ tó tayọ lọ́lá lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe orúkọ fún ara wa. Àwọn mìíràn lè yìn wá, wọ́n lè ka èrò wa sí èyí tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn, kí wọ́n sì máa wá ọ̀nà láti rí ojú rere wa. Gbogbo èyí ló lè fún wa ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. Àmọ́, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, kò ní sí mọ́. Gbogbo ògo àti agbára tó yẹ kí ọba ní ni Sólómọ́nì ní, síbẹ̀ ó kédàárò pé: “A kì í rántí ọlọ́gbọ́n ju arìndìn . . . Olúkúlùkù ni a ti gbàgbé dájúdájú.” (Oníwàásù 2:16) Òkìkí àti agbára kọ́ ló ń fúnni ní ìwàláàyè.

Gbẹ́nàgbẹ́nà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Celo wá mọyì ohun kan tó níye lórí gan-an ju òkìkí lọ. Nítorí ẹ̀bùn tó ní, ó láǹfààní àtilọ sílé ìwé tó jẹ́ kí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Láìpẹ́ àwọn oníwèé ìròyìn àtàwọn tó máa ń yẹ iṣẹ́ ọ̀nà wò bẹ̀rẹ̀ sí gbé iṣẹ́ rẹ̀ lárugẹ. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ère tó gbẹ́ ni wọ́n gbé síbi táwọn èèyàn ti lè rí wọn láwọn ìlú ńláńlá Yúróòpù. Celo ròyìn pé: “Mo gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ pé ní àkókò kan, iṣẹ́ ọnà ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé mi. Àmọ́, mo wá rí i pé bí mo bá ní kí n máa bá iṣẹ́ ọwọ́ mi yìí lọ, ńṣe ni yóò dà bí ẹni pé mo ń sin ọ̀gá méjì. (Mátíù 6:24) Mo wá rí i kedere pé ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tí mo lè ṣe ni pé kí n máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Nípa bẹ́ẹ̀ mo pinnu láti fi iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà tí mò ń ṣe sílẹ̀.”

Kí Ló Níye Lórí Jù Lọ?

Níwọ̀n bó ṣe jẹ́ pé kò sóhun tó nítumọ̀ tàbí tó níye lórí láìsí ìwàláàyè, kí la wá lè ní táa jẹ́ ká máa wà láàyè títí lọ? Jèhófà Ọlọ́run ni orísun gbogbo ìwàláàyè. (Sáàmù 36:9) Ní tòótọ́, “nípasẹ̀ rẹ̀ ni àwa ní ìwàláàyè, tí a ń rìn, tí a sì wà.” (Ìṣe 17:28) Yóò fi ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun jíǹkí àwọn tó nífẹ̀ẹ́. (Róòmù 6:23) Kí la lè ṣe láti rí ẹ̀bùn yìí gbà?

A gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà táa bá fẹ́ rí ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun gbà. Nítorí náà, rírí ojú rere rẹ̀ níye lórí gan-an ju ohunkóhun táa lè ní. Nígbà táa bá rí ojú rere rẹ̀, a lè máa fojú sọ́nà fún ojúlówó ayọ̀ tí yóò wà títí láé. Àmọ́, bí a kò bá rí ojú rere Ọlọ́run, ìparun ayérayé ló ń dúró dè wá yẹn. Ó ṣe kedere nígbà náà pé ohunkóhun tó bá lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà ló níye lórí jù lọ.

Ohun Táa Gbọ́dọ̀ Ṣe

Àṣeyọrí wa sinmi lórí jíjèrè ìmọ̀. Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Jèhófà ni orísun ìmọ̀ pípéye. Ìwé yìí nìkan ṣoṣo ló sọ ohun táa lè ṣe láti múnú Ọlọ́run dùn fún wa. Nítorí náà, ó yẹ ká fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́. Fífi taápọntaápọn sapá láti kọ́ gbogbo ohun táa bá lè kọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi yóò yọrí sí ‘ìmọ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.’ (Jòhánù 17:3) Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìṣúra táa gbọ́dọ̀ mọyì!—Òwe 2:1-5.

Ìmọ̀ táa ń jèrè láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń mú wa gbára dì láti gbé ìgbésẹ̀ tó tẹ̀ lé e—ìyẹn ni lílo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi. Jèhófà ti pa á láṣẹ pé gbogbo ẹni tó bá fẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ òun gbọ́dọ̀ wá nípasẹ̀ Jésù. (Jòhánù 14:6) Ní ti tòótọ́, “kò sí ìgbàlà kankan nínú ẹnikẹ́ni mìíràn.” (Ìṣe 4:12) Lílà á já wa níkẹyìn kò sinmi lórí ‘fàdákà tàbí wúrà . . . , bí kò ṣe lórí ẹ̀jẹ̀ iyebíye ti Kristi.’ (1 Pétérù 1:18, 19) A gbọ́dọ̀ fi ẹ̀rí ìgbàgbọ́ wa hàn nípa gbígba ẹ̀kọ́ Jésù gbọ́ àti títẹ̀lé àpẹẹrẹ rẹ̀. (Hébérù 12:1-3; 1 Pétérù 2:21) Ẹbọ rẹ̀ níye lórí gan-an o! Àwọn àǹfààní ẹbọ rẹ̀ ló ń pinnu ọjọ́ iwájú àìnípẹ̀kun gbogbo aráyé. Ìgbà táa bá sì lo àǹfààní ẹbọ náà fún wa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ la óò fún wa ní ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun tó níye lórí jù lọ.—Jòhánù 3:16.

Jésù sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:37) Nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà túmọ̀ sí pé “kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (1 Jòhánù 5:3) Àwọn àṣẹ rẹ̀ wé mọ́ yíya ara wa sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé, ká níwà rere, ká sì fi ìdúróṣinṣin kọ́wọ́ ti Ìjọba rẹ̀ lẹ́yìn. Ọ̀nà táa lè gbà “yan ìyè” dípò ikú nìyẹn. (Diutarónómì 30:19) Bí a bá ‘sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sún mọ́ àwa náà.’—Jákọ́bù 4:8.

Níní ìdánilójú pé a ti rí ojú rere Ọlọ́run níye lórí ju gbogbo àwọn ìṣúra tó wà nínú ayé lọ. Àwọn tó rí i ló láyọ̀ jù lọ ní gbogbo ayé! Ǹjẹ́ kí a sapá nígbà náà, láti ní ìṣúra tó níye lórí jù lọ—ìyẹn ni ojú rere Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé a fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ́kàn pé: “Máa lépa òdodo, fífọkànsin Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ìfaradà, inú tútù. Ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú gírígírí.”—1 Tímótì 6:11, 12.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Kí lo kà sí ohun tó níye lórí jù lọ? Ṣé owó ni, tàbí nǹkan ìní ti ara, tàbí òkìkí, tàbí nǹkan mìíràn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ó yẹ ká máa fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́