Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Pétérù Sẹ́ Jésù

Pétérù Sẹ́ Jésù

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Pétérù Sẹ́ Jésù

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sáriwo ni kó o ti ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ yìí. Bó o ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyẹn, fojú inú wò ó pé o wà níbi tí ohun tó ò ń kà náà ti ṣẹlẹ̀. Máa fojú inú wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, bíi pé ò ń gbọ́ báwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Kó o sì fojú inú wo bí nǹkan ṣe rí lárá àwọn tó kópa pàtàkì nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA MÁTÍÙ 26:31-35, 69-75 .

Àwọn mélòó lo rò pé ó wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà?

․․․․․

Kí lèrò rẹ nípa àwọn tó ko Pétérù lójú? Ṣé ohùn jẹ́jẹ́ ni wọ́n fi bá a sọ̀rọ̀ ni? Àbí wọ́n kàn fẹ́ gbọ́ nǹkan kan lẹ́nu ẹ̀ ni? Ṣé inú ń bí wọn ni? Àbí nǹkan míì ló wà lọ́kàn wọn?

․․․․․

Báwo lo ṣe rò pé ó rí lára Pétérù nígbà tí wọ́n ń kò ó lójú?

․․․․․

Kí ló fà á tí Pétérù fi sẹ́ Jésù? Ṣé kò nífẹ̀ẹ́ Jésù ni, àbí nǹkan míì ló fà á?

․․․․․

ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.—KA LÚÙKÙ 22:31-34; MÁTÍÙ 26:55-58; JÒHÁNÙ 21:9-17.

Kí nìdí tó fi lè jẹ́ pé dídá tí Pétérù dá ara rẹ̀ lójú jù ló mú kó ṣe àṣìṣe yìí?

․․․․․

Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun fọkàn tán Pétérù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ tó máa kọsẹ̀?

․․․․․

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pétérù sẹ́ Jésù, ọ̀nà wo ló gbà fi hàn pé òun nígboyà ju àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù lọ?

․․․․․

Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun dárí ji Pétérù?

․․․․․

Kí lo rò pé ó mú kí Jésù béèrè lọ́wọ́ Pétérù lẹ́ẹ̀mẹta pé: “Ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi bí?”

․․․․․

Lẹ́yìn tí Jésù jíròrò ọ̀rọ̀ yìí pẹ̀lú Pétérù, báwo lo ṣe rò pé ọ̀rọ̀ náà rí lára Pétérù, kí sì nìdí?

․․․․․

MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀHÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ OHUN TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Ìbẹ̀rù èèyàn.

․․․․․

Bí Jésù ṣe fàánú hàn sáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àní nígbà tí wọ́n ṣohun tí kò tọ́ pàápàá.

․․․․․

Apá wo ló gbàfiyèsí rẹ jù lọ nínú ìtàn yìí, kí sì nìdí?

․․․․․

․․․․․