Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Inú Ọkàn Èèyàn Ni Ìjọba Ọlọ́run wà?

Ṣé Inú Ọkàn Èèyàn Ni Ìjọba Ọlọ́run wà?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé

Ṣé Inú Ọkàn Èèyàn Ni Ìjọba Ọlọ́run wà?

Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló gbà pé ìdáhùn sí ìbéèrè yìí jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni. Bí àpẹẹrẹ, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ tó ń jẹ́ The Catholic Encyclopedia sọ pé: “Ohun tí ìjọba Ọlọ́run túmọ̀ sí ni . . . ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń ṣàkóso nínú ọkàn wa.” Irú ẹ̀kọ́ yìí ni àwọn àlùfáà fi máa ń kọ́ àwọn èèyàn. Ǹjẹ́ Bíbélì fi kọ́ni lóòótọ́ pé inú ọkàn èèyàn ni Ìjọba Ọlọ́run wà?

Àwọn kan sọ pé Jésù fúnra rẹ̀ lẹni tó kọ́kọ́ sọ pé inú ọkàn èèyàn ni Ìjọba Ọlọ́run wà. Ohun tí Jésù sọ rèé: “Wò ó! ìjọba Ọlọ́run wà ní àárín yín.” (Lúùkù 17:21) Ohun táwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan sọ níbí yìí ni pé: “Ìjọba Ọlọ́run wà nínú yín.” Ǹjẹ́ bó ṣe yẹ kí wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí ni wọ́n ṣe tú u? Ṣé ohun tí Jésù ní lọ́kàn ni pé inú ọkàn èèyàn ni Ìjọba Ọlọ́run wà?

Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun tí ọkàn èèyàn jẹ́. Tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa ọkàn, ohun tí Bíbélì ń sọ ni irú ẹni téèyàn kan jẹ́, ohun tó ń mú kó ronú bó ṣe máa ń ronú, ohun tó ń mú kó hu irú ìwà tó ń hù, àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀. Èrò náà pé Ìjọba Ọlọ́run tó ga lọ́lá ń gbé inú ọkàn èèyàn, ní ti bó ṣe lè yí èèyàn lọ́kàn padà tó sì lè sọ èèyàn dẹni iyì, lè dà bí ohun tó fani lọ́kàn mọ́ra, àmọ́ ṣé èrò yìí tọ̀nà?

Bíbélì sọ fún wa pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.” (Jeremáyà 17:9) Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Láti inú ọkàn-àyà àwọn ènìyàn, ni àwọn èrò tí ń ṣeni léṣe ti ń jáde wá: àgbèrè, olè jíjà, ìṣìkàpànìyàn, panṣágà, ojúkòkòrò, àwọn iṣẹ́ ìwà burúkú.” (Máàkù 7:20-22) Tiẹ̀ rò ó wò ná: Ǹjẹ́ kì í ṣe inú ọkàn èèyàn tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀ ni àwọn nǹkan tó ń fa ìpọ́njú lóde òní ti ń wá? Nígbà náà, báwo wá ni Ìjọba Ọlọ́run tó jẹ́ pípé ṣe lè wá láti irú ibẹ̀ yẹn? Ká sòótọ́, Ìjọba Ọlọ́run ò lè wá látinú ọkàn èèyàn, gẹ́gẹ́ bí a ò ṣe lè retí pé ká rí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára òṣùṣú.—Mátíù 7:16.

Ẹ jẹ́ ká tún ronú nípa àwọn tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ nígbà tó sọ̀rọ̀ tó wà nínú Lúùkù 17:21 yẹn. Ohun tí Lúùkù 17:20 tó ṣáájú ẹsẹ yẹn sọ ni pé: “Nígbà tí àwọn Farisí béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ìgbà tí ìjọba Ọlọ́run ń bọ̀, ó dá wọn lóhùn.” Ọ̀tá Jésù làwọn Farisí. Jésù sọ pé àwọn Farisí tí wọ́n jẹ́ alágàbàgebè yìí kò ní wọ Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 23:13) Bó bá jẹ́ pé àwọn Farisí ò ní wọ Ìjọba Ọlọ́run, báwo ni Ìjọba náà ṣe lè wá wà nínú ọkàn wọn? Ìyẹn ò ṣeé ṣe rárá! Kí wá ni Jésù ní lọ́kàn?

Nígbà táwọn Bíbélì kan tí wọ́n fara balẹ̀ túmọ̀ wọn ń sọ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí, wọ́n lo ọ̀rọ̀ tó jọ èyí tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun. Àwọn kan lára àwọn Bíbélì yẹn sọ pé, Ìjọba náà wà “láàárín yín.” Lọ́nà wo ni Ìjọba Ọlọ́run fi wà láàárín àwọn èèyàn yẹn, títí kan àwọn Farisí pàápàá? Jésù lẹni tí Jèhófà Ọlọ́run yàn láti jẹ́ Ọba Ìjọba náà. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó máa jẹ́ Ọba lọ́jọ́ iwájú, ó wà láàárín àwọn èèyàn náà nígbà yẹn. Ó kọ́ wọn nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó tún ṣe iṣẹ́ ìyanu, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí wọ́n rí ohun tí Ìjọba náà máa ṣe fáráyé lọ́jọ́ iwájú. Nígbà náà, ní ti gidi, Ìjọba Ọlọ́run wà láàárín wọn lóòótọ́.

Ó hàn gbangba pé kò síbì kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó sọ pé Ìjọba Ọlọ́run wà nínú ọkàn èèyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìjọba gidi kan tó máa mú àyípadà rere bá ayé ni, gẹ́gẹ́ bí àwọn wòlíì ṣe sọ tẹ́lẹ̀.—Aísáyà 9:6, 7; Dáníẹ́lì 2:44.