Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Nípa Ọlọ́run Tòótọ́

Nípa Ọlọ́run Tòótọ́

Ohun Tá a Kọ́ Lọ́dọ̀ Jésù

Nípa Ọlọ́run Tòótọ́

Ǹjẹ́ Ọlọ́run ní orúkọ?

Jésù kọ́ wa pé Ọlọ́run ní orúkọ. Ó sọ pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.’” (Mátíù 6:9) Bíbélì sọ fún wa pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ pé: “Mo sì ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn.”—Jòhánù 17:26.

Ta ni Jèhófà?

Jésù pe Jèhófà ní “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà” nítorí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá. (Jòhánù 17:3) Jésù sọ pé: “Ẹ kò ha kà pé ẹni tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo?” (Mátíù 19:4) Jésù tún sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí.” (Jòhánù 4:24) Ìdí nìyẹn tí a ò fi lè rí Ọlọ́run.—Ẹ́kísódù 33:17-20.

Kí ni Ọlọ́run fẹ́ ká máa ṣe?

Nígbà tẹ́nì kan bi Jésù pé èwo ló ṣe pàtàkì jù lọ nínú òfin, Jésù dá a lóhùn pé: “Èkíní ni, ‘Gbọ́, Ìwọ Ísírẹ́lì, Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́ Jèhófà kan ṣoṣo, kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.’ Èkejì nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’”—Máàkù 12:28-31.

Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?

Jésù sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Baba.” Báwo ló ṣe fi ìfẹ́ tó ní sí Baba rẹ̀ hàn? Ó sọ pé: “Àní gẹ́gẹ́ bí Baba ti fi àṣẹ fún mi láti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni mo ń ṣe.” (Jòhánù 14:31) Ó tún sọ pé: “Nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wù ú.” (Jòhánù 8:29) A lè ṣe ohun tó wu Ọlọ́run bá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà nítorí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú.”—Jòhánù 17:3; 1 Tímótì 2:4.

Báwo la ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run?

Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run ni nípa kíkíyèsí àwọn ohun tó dá. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Ẹ fi tọkàntara ṣàkíyèsí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí wọn kì í fún irúgbìn tàbí ká irúgbìn tàbí kó jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́; síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí?” Kí ni Jésù fẹ́ ká kọ́ nípa kíkíyèsí àwọn ẹyẹ? Ohun tó fẹ́ ká kọ́ ni pé a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àníyàn ohun tá a nílò nígbèésí ayé dí wa lọ́wọ́ sísin Ọlọ́run.—Mátíù 6:26-33.

Ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gba mọ Jèhófà ni kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Jésù pe Ìwé Mímọ́ ní “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Lúùkù 8:21) Jésù sọ fún Ọlọ́run pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.”—Jòhánù 17:17; 2 Pétérù 1:20, 21.

Jésù ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ òtítọ́ nípa Jèhófà. Ọmọ ẹ̀yìn Jésù kan sọ nípa Jésù pé: “Ọkàn-àyà wa kò ha ń jó fòfò bí ó ti ń bá wa sọ̀rọ̀ ní ojú ọ̀nà, bí ó ti ń ṣí Ìwé Mímọ́ payá fún wa lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́?” (Lúùkù 24:32) Tá a bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, a ní láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ká múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́. Jésù sọ pé: “Láìjẹ́ pé ẹ yí padà, kí ẹ sì dà bí àwọn ọmọ kéékèèké, ẹ kì yóò wọ ìjọba ọ̀run lọ́nàkọnà.”—Mátíù 18:3.

Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìmọ̀ Ọlọ́run ń fúnni láyọ̀?

Ó pọn dandan fún wa láti mọ ìdí tá a fi wà láàyè, Ọlọ́run sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ìdí náà. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Jèhófà ń kọ́ wa bá a ṣe lè lò ìgbésí ayé wa lọ́nà tó dára jù lọ. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”—Lúùkù 11:28; Aísáyà 11:9.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo orí kìíní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

“Mo sì ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn.”—Jòhánù 17:26.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

A lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà látinú àwọn ohun tó dá àti látinú Bíbélì