Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá A Ṣe Ń Kọ́ Ilé Tó Ń Fìyìn fún Jèhófà

Bá A Ṣe Ń Kọ́ Ilé Tó Ń Fìyìn fún Jèhófà

Bá A Ṣe Ń Kọ́ Ilé Tó Ń Fìyìn fún Jèhófà

“Ńṣe ló dà bí àlá lójú mi. Mi ò rò ó rí, pé a lè ní ibi ìjọsìn tó máa dára rèǹtèrente bí èyí, tá a ó ti máa pàdé láti máa yin Jèhófà. Áà, owó ò lè ra ayọ̀ tí mo ní yìí!”—MARIA, LÁTI ORÍLẸ̀-ÈDÈ MẸ́SÍKÒ.

ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ máa ń fẹ́ láti máa pé jọ kí wọ́n sì máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Sáàmù 27:4; Hébérù 10:23-25) Inú wọn máa ń dùn, àgàgà tó bá lọ jẹ́ pé inú ibi ìjọsìn tó bójú mu ni wọ́n ti ń pé jọ. Láti ọdún bíi mélòó kan báyìí, wọ́n ti kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi ìjọsìn ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè kárí ayé. Gbọ̀ngàn Ìjọba ni wọ́n máa ń pe ibi ìjọsìn wọn.

Kí nìdí tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí? Àwọn wo ló ń kọ́ ọ? Ipa wo ni iṣẹ́ ìkọ́lé náà máa ń ní lórí àwọn tó ń ṣe é? Ká lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ẹ jẹ́ ká gbé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò àti Belize yẹ̀ wò.

Wọ́n Nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba Tó Lé Ní Ẹgbẹ̀rún Mẹ́ta!

Nígbà kan rí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò máa ń pé jọ láti jọ́sìn níbikíbi tí wọ́n bá rí àyè sí, irú bí ẹ̀yìnkùlé àti inú ilé àwọn Ẹlẹ́rìí fúnra wọn, ibi ìkẹ́rùsí, ibi ìgbọ́kọ̀sí tàbí ní àwọn gbọ̀ngàn tí wọ́n rẹ́ǹtì. Lákòókò yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí adúróṣinṣin wọ̀nyí sábà máa ń rò ó pé ì bá dára gan-an ká ní àwọn lè kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàwọn.

Nígbà tó fi máa di ọdún 1994 iye àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Mẹ́síkò ti di ọ̀kẹ́ mọ́kàndínlógún ó lé ẹgbàárin [388,000]. Ìwádìí tá a ṣe lọ́dún yẹn fi hàn pé tí gbogbo wọn bá fẹ́ máa ṣèpàdé nínú ilé ìjọsìn táwọn fúnra wọn kọ́, wọ́n á nílò ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ọ̀ọ́dúnrún [3,300] Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ bàǹtàbanta ni wọ́n máa ṣe!

Lákòókò yẹn, àwọn ìjọ kan lára wọn ti ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn nítorí wọ́n lágbára àtikọ́ ọ. Àmọ́ nígbà tọ́dún márùn-ún máa fi pé, ó wá hàn kedere pé kí iye Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n nílò tó lè pé, a ní láti kọ́ iye tó pọ̀ sí i, a sì ní láti kọ́ wọn kíákíá. Ọgbọ́n wo là ń dá tá a fi ń kọ́ ọ?

Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni Tó Mọṣẹ́dunjú Ń Kọ́lé Káàkiri

Lọ́dún 1999 a bẹ̀rẹ̀ ètò tuntun kan tó wà fún iṣẹ́ ìkọ́lé. A bẹ̀rẹ̀ sí í kó Ẹgbẹ́ Àwọn Tí Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba jọ jákèjádò orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ibi gbogbo ní orílẹ̀-èdè náà ló yọ̀ǹda ara wọn láti kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń wúni lórí yìí, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì mọ ilé kọ́. Ní báyìí, orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ní ẹgbẹ́ márùndínlógójì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ilé kíkọ́, wọ́n sì ti dá ẹgbẹ́ kan sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Belize.

Èèyàn mẹ́jọ, lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn ló sábà máa ń wà nínú Ẹgbẹ́ Àwọn Tí Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọn ò sì níṣẹ́ míì jùyẹn lọ, wọn kì í sì í gbowó iṣẹ́. Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí wọ́n jẹ́ aláyọ̀ yìí máa ń lọ láti àgbègbè kan sí òmíràn láàárín orílẹ̀-èdè náà láti darí iṣẹ́ ìkọ́lé. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn máa ń ṣiṣẹ́ wákàtí mẹ́jọ lóòjọ́ láti ọjọ́ Monday sí ọjọ́ Friday, wọ́n sì máa ń ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ Saturday méjì tàbí mẹ́ta lóṣù. Ìjíròrò ẹsẹ Bíbélì kan ni wọ́n máa fi ń bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ní aago méje òwúrọ̀, lẹ́yìn èyí ni wọ́n á wá jẹun àárọ̀. Gbogbo wọn ṣe tán láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá ní kí wọ́n ṣe. Bí àpẹẹrẹ, àwọn obìnrin máa ń ṣiṣẹ́ ọkùnrin, irú bíi rírẹ́lé, lílẹ àwo ìkọ́lé mọ́ ara ògiri àti kíkun ilé.

Àwọn ará ìjọ tí wọ́n ń kọ́ Gbọ̀ngàn fún máa ń gba àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí wọ́n wá kọ́ gbọ̀ngàn náà sílé, wọ́n máa ń fọ aṣọ wọn, wọ́n sì máa ń se oúnjẹ fún wọn. Yàtọ̀ sí pé àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni náà jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará ìjọ tí wọ́n ń kọ́lé fún, wọ́n tún jọ máa ń gbádùn ìpàdé ìjọ tí wọ́n sì jọ máa ń wàásù láti ilé dé ilé.

Àǹfààní Táwọn Tó Yọ̀ǹda Ara Wọn Ń Jẹ

Kí lèrò àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ náà? Daniel tó ti fohun tó lé ní ọdún mẹ́ta ṣiṣẹ́ ìkọ́lé sọ pé: “Òótọ́ ni pé a ń ṣiṣẹ́ kára lójò lẹ́ẹ̀rùn, tá à ń jẹ oúnjẹ tí kò mọ́ wa lára, tá à ń fìgbà gbogbo ṣí kiri, tá a filé fọ̀nà wa sílẹ̀ fáwọn ìgbà kan, tá a kì í sì í ráwọn ohun amáyédẹrùn lò lọ́pọ̀ ìgbà.” Ó wá fi kún un pé: “Àmọ́ àwọn àìbáradé wọ̀nyí kò jẹ́ nǹkan kan tá a bá fi wé ìbùkún tá à ń rí gbà.”

Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìbùkún náà? Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ ìkọ́lé yìí máa ń kọ́ iṣẹ́ tuntun lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Àmọ́, olùyọ̀ǹda ara ẹni kan tó ń jẹ́ Carlos, tó ń bójú tó ọ̀kan lára àwùjọ ńlá sọ ohun tó jẹ́ àǹfààní tó ṣe pàtàkì jù. Ó ní: “Ńṣe ni gbogbo wa tá a jẹ́ ogún dà bí ìdílé kan. À ń jẹun pa pọ̀, à ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀, à ń kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀, a sì ń gbàdúrà pa pọ̀. A ti wá di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.”

Àwọn àwùjọ tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé tún di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ará ìjọ tí wọ́n ń bá kọ́lé. José tó ti kópa nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó lé ní ọgọ́rùn-ún sọ pé: “Omijé ayọ̀ àti ẹ̀rín tó máa ń wà lójú wọn nígbà tí wọ́n bá rí Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn tí wọ́n ti ń wọ̀nà fún máa ń fi bí ìmọrírì wọn ṣe pọ̀ tó hàn, èyí sì kọjá àfẹnusọ.” Ó fi kún un pé: “Bá a bá ṣe ń parí Gbọ̀ngàn Ìjọba kọ̀ọ̀kan, inú wa máa ń dùn pé ìwọ̀nba ohun tá à ń ṣe nínú kíkọ́ ilé fún ìjọsìn mímọ́ ń mú kí ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn lágbára sí i.”

Wọ́n Ti Ṣe Bẹbẹ!

Àwọn ilé ìjọsìn wọ̀nyí kì í ṣe ilé ràgàjì ràgàjì tàbí ilé aláruru. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba náà rọrùn, èyí mú kí wọ́n tètè ṣeé kọ́ tí wọn ò sì náni lówó rẹpẹtẹ. Níbi tó bá ti ṣeé ṣe, ohun èlò ìkọ́lé tó wà ládùúgbò àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà kọ́lé ládùúgbò ni wọ́n máa ń lò láti fi kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n lè kọ́ gbọ̀ngàn tuntun kan ní ọ̀sẹ̀ mẹ́fà péré!

Nígbà tó fi máa di ọdún 2007, gbogbo ìjọ tó wà ní orílẹ̀-èdè Belize ti ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun mẹ́tàdínlógún. Ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, lẹnu ọdún 1999 sígbà tá a wà yìí, wọ́n ti kọ́ àwọn gbọ̀ngàn tí iye wọn ju egbèje [1,400] lọ!

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àṣeyọrí ni a ti ṣe, iṣẹ́ ṣì pọ̀ láti ṣe. (Mátíù 9:37) Iye àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílẹ̀ Mẹ́síkò ti ju ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ [600,000] lọ nísinsìnyí, gbogbo wọn ló sì ń pàdé pọ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́sẹ̀ láti gba ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èyí fi hàn pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá [2,000] gbọ̀ngàn tuntun tí wọ́n ṣì nílò. Bó bá jẹ́ pé agbára èèyàn la fi ń ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé yìí ni, apá wa ò ní ká irú iṣẹ́ bàǹtàbanta tó wà níwájú yìí. Àmọ́ bí ọ̀pọ̀ gbọ̀ngàn tí wọ́n ti kọ́ parí yìí ṣe fi hàn, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, “ohun gbogbo ṣeé ṣe.”—Mátíù 19:26.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

“Wọ́n Máa Ń Tẹ̀ Lé Ọ̀rọ̀ Wọn”

Kì í ṣe ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn máa ń ṣe láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan lórílẹ̀-èdè Belize, ọkùnrin kan tí ìyàwó rẹ̀ jẹ́ ará ṣọ́ọ̀ṣì Pentecostal sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá kọ́ “ṣọ́ọ̀ṣì” wọn tán, òun á máa lọ síbẹ̀. Kí nìdí tó fi fẹ́ láti máa wá sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba? Ó ní: “Mo rí i pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn. Wọn kì í bá ara wọn jà bí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́. Wọ́n máa ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ wọn.”

[Àwòrán]

Gbọ̀ngàn Ìjọba ní àdúgbò Orange Walk, lórílẹ̀-èdè Belize

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Iṣẹ́ Ìkọ́lé Tó Kárí Ayé

A ti dá Ẹgbẹ́ Àwọn Tí Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sílẹ̀ ní ọgọ́fà [120] orílẹ̀-èdè. Díẹ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè táwọn olùyọ̀ǹda ti ń fayọ̀ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé náà rèé:

Àǹgólà, Bòlífíà, Croatia, Dominican Republic, Etiópíà, Fẹnẹsúélà, Fíjì, Gánà, Hong Kong, Íńdíà, Jàmáíkà, Kazakhstan, Làìbéríà, Moldova, Nàìjíríà, Papua New Guinea, Rùwáńdà, Sáńbíà, Túfálù, Ukraine.

[Àwọn àwòrán]

Gbọ̀ngàn Ìjọba ní Acapulco, nílẹ̀ Mẹ́síkò

Ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Àwọn Tí Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba nílẹ̀ Mẹ́síkò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Gbọ̀ngàn Ìjọba nílùú Tlaxcala, nílẹ̀ Mẹ́síkò